-
Àwọn Oníwàásù—Àwọn Òjíṣẹ́ Ọlọ́run Yọ̀ǹda Ara Wọn TinútinúÌjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
-
-
Bíi ti ọkùnrin tí inú rẹ̀ dùn gan-an nígbà tó rí ìṣúra kan tí a pa mọ́, inú àwọn Kristẹni máa ń dùn pé àwọn rí òtítọ́ Ìjọba náà (Wo ìpínrọ̀ 20)
20. Báwo ni àkàwé Jésù nípa ìṣúra tí a fi pa mọ́ ṣe jẹ́ ká mọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ yóò kọbi ara sí ìtọ́ni rẹ̀ pé kí wọ́n máa bá a nìṣó ní wíwá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́?
20 Jésù mọ̀ pé àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ yóò kọbi ara sí ìtọ́ni rẹ̀ pé kí wọ́n máa bá a nìṣó ní wíwá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́. Bí àpẹẹrẹ, wo àkàwé kan tí Jésù sọ nípa ìṣúra kan tí a fi pa mọ́. (Ka Mátíù 13:44.) Nígbà tí ọkùnrin alágbàṣe inú àkàwé náà ń ṣiṣẹ́ òòjọ́ rẹ̀ nínú pápá, ó rí ìṣúra kan tí a fi pa mọ́, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló sì mọ bó ti ṣeyebíye tó. Kí ló wá ṣe? “Nítorí ìdùnnú tí ó ní, ó lọ, ó sì ta àwọn ohun tí ó ní, ó sì ra pápá yẹn.” Ẹ̀kọ́ wo nìyẹn kọ́ wa? Nígbà tá a bá rí òtítọ́ Ìjọba náà, tá a sì mọ bó ti ṣeyebíye tó, tìdùnnú-tìdùnnú la fi máa ṣe gbogbo ohun tó bá gbà ká lè fi ire Ìjọba náà sípò kìíní tó yẹ ká fi í sí nígbèésí ayé wa.d
-
-
Àwọn Oníwàásù—Àwọn Òjíṣẹ́ Ọlọ́run Yọ̀ǹda Ara Wọn TinútinúÌjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
-
-
d Jésù tún sọ irú kókó kan náà nínú àkàwé olówò arìnrìn-àjò kan tó lọ wá àwọn péálì tó níye lórí gan-an. Nígbà tí olówò yìí rí péálì náà, ó ta gbogbo ohun tó ní, ó sì rà á. (Mát. 13:45, 46) Àkàwé méjèèjì náà sì tún kọ́ wa pé ó lè jẹ́ ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la máa gbà kẹ́kọ̀ọ́ nípa òtítọ́ Ìjọba náà. A lè sọ pé ńṣe ni àwọn kan kàn bá òtítọ́ pàdé; ṣe làwọn míì sì wá a kàn. Ṣùgbọ́n ọ̀nà yòówù ká gbà rí òtítọ́, ńṣe la fi tinútinú ṣe gbogbo ohun tó gbà ká lè fi Ìjọba náà sí ipò àkọ́kọ́ ní ìgbésí ayé wa.
-