-
Fetí sí Ohùn JèhófàIlé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019 | March
-
-
“Ẹ FETÍ SÍ I”
7. Bó ṣe wà nínú Mátíù 17:1-5, ìgbà míì wo ni Jèhófà sọ̀rọ̀ látọ̀run, kí sì lohun tó sọ?
7 Ka Mátíù 17:1-5. Ìgbà tí Jésù ‘yí pa dà di ológo’ ni ìgbà kejì tí Jèhófà sọ̀rọ̀ látọ̀run. Jésù mú Pétérù, Jémíìsì àti Jòhánù pẹ̀lú rẹ̀ nígbà tó lọ sórí òkè ńlá kan. Ibẹ̀ ni wọ́n wà nígbà tí wọ́n rí ìran kan tó kàmàmà. Wọ́n rí i tí ojú Jésù ń tàn yanran, tí aṣọ rẹ̀ sì ń kọ mànà. Wọ́n tún kíyè sí àwọn méjì kan tó ṣàpẹẹrẹ Mósè àti Èlíjà tí wọ́n ń bá Jésù sọ̀rọ̀ nípa ikú àti àjíǹde rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé “oorun ń kun” àwọn àpọ́sítélì mẹ́ta náà gidigidi, nígbà tí oorun dá lójú wọn, wọ́n rí ìran àgbàyanu náà. (Lúùkù 9:29-32) Lẹ́yìn ìyẹn, ìkùukùu tó mọ́lẹ̀ yòò ṣíji bò wọ́n, wọ́n sì gbọ́ ohùn Ọlọ́run fúnra rẹ̀! Nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi, Jèhófà sọ pé òun tẹ́wọ́ gba Ọmọ òun àti pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ó sọ pé: “Èyí ni Ọmọ mi, àyànfẹ́, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.” Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, Jèhófà fi kún un pé: “Ẹ fetí sí i.”
-
-
Fetí sí Ohùn JèhófàIlé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019 | March
-
-
9. Àwọn ìmọ̀ràn wo ni Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀?
9 “Ẹ fetí sí i.” Ó ṣe kedere pé Jèhófà fẹ́ ká máa fetí sí Ọmọ òun, ká sì máa ṣègbọràn sí i. Àwọn nǹkan wo ni Jésù sọ nígbà tó wà láyé? Ọ̀pọ̀ nǹkan ló sọ tó yẹ ká fetí sí. Bí àpẹẹrẹ, ó kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bí wọ́n ṣe lè máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, léraléra ló sì sọ fún wọn pé kí wọ́n wà lójúfò. (Mát. 24:42; 28:19, 20) Ó tún gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n máa sa gbogbo ipá wọn, kí wọ́n má sì jẹ́ kó sú wọn. (Lúùkù 13:24) Jésù tẹnu mọ́ ọn fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn, kí wọ́n ṣera wọn lọ́kan, kí wọ́n sì máa pa àṣẹ òun mọ́. (Jòh. 15:10, 12, 13) Ẹ ò rí i pé ìmọ̀ràn tí Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wúlò gan-an! Bó ṣe wúlò nígbà yẹn náà ló ṣe wúlò títí dòní.
-