ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Kí ni Jèhófà Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa Lónìí?
    Ilé Ìṣọ́—1999 | September 15
    • 3, 4. (a) Kí ni ohun náà gan-an tí Jèhófà béèrè lọ́wọ́ wa lónìí? (b) Èé ṣe tí a fi ní láti tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Jésù pẹ́kípẹ́kí?

      3 Ní ọdún tó kẹ́yìn iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù, àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ Pétérù, Jákọ́bù, àti Jòhánù tẹ̀ lé e lọ sí òkè ńlá gíga kan, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ apá kan tó yọ gọnbu lórí Òkè Hámónì. Ibẹ̀ ni wọ́n ti rí ìran alásọtẹ́lẹ̀ nípa Jésù nínú ògo ọlọ́lá ńlá, tí wọ́n sì gbọ́ ohùn Ọlọ́run fúnra rẹ̀ tó polongo pé: “Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà; ẹ fetí sí i.” (Mátíù 17:1-5) Láìsí àní-àní, ohun tí Jèhófà ń béèrè lọ́wọ́ wa nìyẹn—ká fetí sí Ọmọ rẹ̀, ká sì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àti ẹ̀kọ́ rẹ̀. (Mátíù 16:24) Ìdí nìyẹn tí àpọ́sítélì Pétérù fi kọ̀wé pé: “Kristi pàápàá jìyà fún yín, ó fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún yín kí ẹ lè tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.”—1 Pétérù 2:21.

  • Kí ni Jèhófà Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa Lónìí?
    Ilé Ìṣọ́—1999 | September 15
    • 5. Abẹ́ òfin wo làwọn Kristẹni wà, ìgbà wo sì ni òfin yẹn bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́?

      5 Kí ló wé mọ́ fífetí sí Jésù àti fífara wé e? Ṣé wíwà lábẹ́ Òfin ló túmọ̀ sí ni? Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Èmi fúnra mi kò sí lábẹ́ òfin.” Ohun tó ń tọ́ka sí níhìn-ín ni “májẹ̀mú láéláé,” ìyẹn ni májẹ̀mú Òfin táa bá Ísírẹ́lì dá. Pọ́ọ̀lù jẹ́wọ́ ní ti tòótọ́ pé òun wà “lábẹ́ òfin sí Kristi.” (1 Kọ́ríńtì 9:20, 21; 2 Kọ́ríńtì 3:14) Bí májẹ̀mú Òfin ògbólógbòó ṣe ń lọ sí òpin ni “májẹ̀mú tuntun” bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ pẹ̀lú “Òfin Kristi” rẹ̀ tó pọndandan fún gbogbo ìránṣẹ́ Jèhófà lónìí láti ṣègbọ́ràn sí.—Lúùkù 22:20; Gálátíà 6:2; Hébérù 8:7-13.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́