ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Máa Fiyè Sí Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́—2000 | April 1
    • 6. (a) Èé ṣe tí Jésù fi pe ìyípadà ológo náà ní ìran? (b) Kí ni ìyípadà ológo náà ṣàpẹẹrẹ rẹ̀?

      6 Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé orí ọ̀kan lára ọ̀wọ́ àwọn Òkè Ńlá Hámónì ni ìṣẹ̀lẹ̀ àràmàǹdà yìí ti ṣẹlẹ̀, níbi tí Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mẹ́ta náà wà mọ́jú. Ó dájú pé òru ni ìyípadà ológo náà wáyé, ìyẹn ló tún jẹ́ kó hàn kedere. Ọ̀kan lára ìdí tí Jésù fi pè é ní ìran ni pé, Mósè àti Èlíjà, tí wọ́n ti kú tipẹ́tipẹ́, kò sí níbẹ̀ ní ti gidi. Kristi nìkan ló wà níbẹ̀ táa lè rí. (Mátíù 17:8, 9) Irú ìmọ́lẹ̀ mọ̀nà-ǹ-kọ-yẹ̀rì bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí Pétérù, Jákọ́bù, àti Jòhánù rí ìran àwòyanu tó ṣàpẹẹrẹ wíwàníhìn-ín ológo Jésù nínú agbára Ìjọba náà. Mósè àti Èlíjà dúró fún àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ àjùmọ̀jogún pẹ̀lú Jésù, ìran náà sì ṣe ìtìlẹyìn tó lágbára fún ẹ̀rí tí Jésù jẹ́ nípa Ìjọba náà àti ipò ọba rẹ̀ ọjọ́ iwájú.

  • Máa Fiyè Sí Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́—2000 | April 1
    • 8. (a) Kí ni ìkéde tí Ọlọ́run ṣe nípa Ọmọ rẹ̀ pe àfiyèsí sí? (b) Kí ni àwọsánmà táa rí nígbà ìyípadà ológo náà fi hàn?

      8 Apá tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìyípadà ológo yìí ni kíkéde tí Ọlọ́run kéde pé: “Èyí ni ọmọ mi, olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n, ẹni tí èmi tìkára mi tẹ́wọ́ gbà.” Gbólóhùn yìí darí àfiyèsí sọ́dọ̀ Jésù gẹ́gẹ́ bí Ọba tí Ọlọ́run ti gbé gorí ìtẹ́, ẹni tí gbogbo ẹ̀dá gbọ́dọ̀ máa ṣègbọràn sí. Ìkùukùu tó ṣíji bò wọ́n ló fi hàn pé ìmúṣẹ ìran yìí yóò jẹ́ èyí tí a kò lè fojú rí. Kìkì nípa lílo ìfòyemọ̀ ni àwọn tó bá mọ “àmì” wíwàníhìn-ín Jésù nínú agbára Ìjọba náà, èyí tí a kò lè fojú rí, yóò fi mọ̀ ọ́n. (Mátíù 24:3) Ní tòótọ́, ìkìlọ̀ tí Jésù ṣe fún wọn pé kí wọ́n má sọ̀rọ̀ nípa ìran náà fún ẹnikẹ́ni kí òun tó jíǹde fi hàn pé ẹ̀yìn àjíǹde rẹ̀ ni ìgbéga àti ìṣelógo rẹ̀ yóò tó wáyé.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́