ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Olùṣọ́ Àgùntàn Tó Bìkítà Nípa Rẹ
    Ilé Ìṣọ́—2008 | February 1
    • Jésù fi ọ̀nà tí olùṣọ́ àgùntàn gbà ń bójú tó agbo ẹran rẹ̀ ṣàkàwé bí ọ̀rọ̀ wa ṣe jẹ Jèhófà lógún. Ó ní: “Bí ọkùnrin kan bá wá ní ọgọ́rùn-ún àgùntàn, tí ọ̀kan nínú wọn sì ṣáko lọ, kì yóò ha fi mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún náà sílẹ̀ lórí àwọn òkè ńlá, kí ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n láti wá ọ̀kan tí ó ṣáko lọ? Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé ó rí i, mo sọ fún yín dájúdájú, yóò yọ̀ púpọ̀ lórí rẹ̀ ju lórí mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún tí kò tíì ṣáko lọ. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, kì í ṣe ohun tí Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run ní ìfẹ́-ọkàn sí, pé kí ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré wọ̀nyí ṣègbé.” (Mátíù 18:12-14) Ẹ jẹ́ ká wo bí Jésù ṣe fi èyí ṣàlàyé bọ́rọ̀ olúkúlùkù ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe jẹ Jèhófà lógún tó.

  • Olùṣọ́ Àgùntàn Tó Bìkítà Nípa Rẹ
    Ilé Ìṣọ́—2008 | February 1
    • Nígbà tí Jésù ń ṣàlàyé àpèjúwe yìí, ó ní, Ọlọ́run kò fẹ́ kí “ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré wọ̀nyí ṣègbé.” Jésù ti kọ́kọ́ kìlọ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣáájú pé kí wọ́n má ṣe “mú ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré wọ̀nyí tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú [òun] kọsẹ̀.” (Mátíù 18:6) Kí ni àpèjúwe tí Jésù ṣe yìí wá kọ́ wa nípa Jèhófà? Ó kọ́ wa pé Jèhófà jẹ́ Olùṣọ́ Àgùntàn tọ́rọ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àgùntàn rẹ̀ jẹ lógún gan-an, títí kan “àwọn ẹni kékeré,” ìyẹn àwọn táráyé kà sí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan. Bẹ́ẹ̀ ni o, Ọlọ́run mọ olúkúlùkù ìránṣẹ́ rẹ̀ dunjú, wọ́n sì ṣe pàtàkì lójú rẹ̀.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́