ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Kí Ìjọ Wà ní Mímọ́ Kí Àlàáfíà sì Jọba
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
    • 14 Jésù sọ ohun pàtó tó yẹ ká ṣe láti yanjú ìṣòro tó bá wáyé láàárín àwa àtàwọn ará wa. Kíyè sí ohun tó ní ká ṣe, ó ní: “Tí arákùnrin rẹ bá ṣẹ̀, [1] lọ sọ ẹ̀bi rẹ̀ fún un láàárín ìwọ àti òun nìkan. Tó bá fetí sí ọ, o ti jèrè arákùnrin rẹ. Àmọ́ tí kò bá fetí sí ọ, [2] mú ẹnì kan tàbí méjì dání, kó lè jẹ́ pé nípa ẹ̀rí ẹni méjì tàbí mẹ́ta, a ó fìdí gbogbo ọ̀rọ̀ múlẹ̀. Tí kò bá fetí sí wọn, [3] sọ fún ìjọ. Tí kò bá fetí sí ìjọ pàápàá, bí èèyàn àwọn orílẹ̀-èdè àti agbowó orí ni kó rí sí ọ gẹ́lẹ́.”​—Mát. 18:15-17.

  • Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Kí Ìjọ Wà ní Mímọ́ Kí Àlàáfíà sì Jọba
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
    • 18 Tí kò bá ṣeé ṣe fún ẹ láti jèrè arákùnrin rẹ pa dà lẹ́yìn tó o ti sọ ẹ̀bi rẹ̀ fún un “láàárín ìwọ àti òun nìkan,” o wá lè ṣe ohun tí Jésù tún sọ, pé kó o “mú ẹnì kan tàbí méjì dání,” kó o sì bá arákùnrin rẹ sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. Àwọn tó máa fẹ́ kó o jèrè arákùnrin rẹ pa dà ni kó o mú dání o. Á dáa kí wọ́n jẹ́ ẹni tí ọ̀rọ̀ náà ṣojú ẹ̀, ṣùgbọ́n tí kò bá sí ẹni tí ọ̀rọ̀ náà ṣojú ẹ̀, o lè ní kí arákùnrin kan tàbí méjì tẹ̀ lé ẹ, kí wọ́n lè mọ̀ sí ọ̀rọ̀ náà. Wọ́n lè ti ní ìrírí nínú irú ọ̀rọ̀ tẹ́ ẹ fẹ́ yanjú náà, tí wọ́n á sì lè mọ̀ bóyá ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn burú lóòótọ́. Tó bá jẹ́ pé àwọn alàgbà ló bá ẹ lọ, kì í ṣe ìjọ ni wọ́n ṣojú fún o, torí pé kì í ṣe ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà ló dìídì yàn wọ́n láti dá sí ọ̀rọ̀ náà.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́