ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • O Lè Jèrè Arákùnrin Rẹ
    Ilé Ìṣọ́—1999 | October 15
    • Wá Ìrànlọ́wọ́ Àwọn Tó Dàgbà Dénú

      12, 13. (a) Kí ni ìgbésẹ̀ kejì tí Jésù sọ pé a lè gbé láti yanjú aáwọ̀? (b) Àwọn ìmọ̀ràn yíyẹ wo ló tọ́ láti fiyè sí nígbà táa bá ń gbé ìgbésẹ̀ yìí?

      12 Ká lóo hùwà kan tó burú jáì, ǹjẹ́ wàá fẹ́ káwọn èèyàn pa ẹ́ tì torí pé oò tètè yí padà? Kò dájú pé wàá fẹ́ bẹ́ẹ̀. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Jésù fi hàn pé lẹ́yìn tóo ti gbé ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́, o kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kó rẹ̀ ọ́ láti jèrè arákùnrin rẹ, kí ìwọ àtòun àtàwọn yòókù lè jọ wà ní ìrẹ́pọ̀, kẹ́ sì lè jọ máa jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tó fẹ́. Jésù sọ ìgbésẹ̀ kejì, ó ní: “Bí kò bá fetí sílẹ̀, mú ẹnì kan tàbí méjì sí i dání pẹ̀lú rẹ, kí a lè fi ìdí ọ̀ràn gbogbo múlẹ̀ ní ẹnu ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta.”

      13 Ó ní kóo mú “ẹnì kan tàbí méjì” dání. Kò sọ pé lẹ́yìn tóo bá ti gbégbèésẹ̀ àkọ́kọ́, o ti lómìnira láti bẹ̀rẹ̀ sí í rojọ́ fáwọn ẹlòmí-ìn, kóo wá bẹ̀rẹ̀ sí í wá alábòójútó arìnrìn-àjò kiri láti fi tó o létí, tàbí kóo bẹ̀rẹ̀ sí kọ lẹ́tà sáwọn ará nípa ìṣòro náà. Bó ti wù kó dá ẹ lójú tó pé lóòótọ́ ló ṣẹ̀ ọ́, ẹ̀yin méjèèjì ò tíì fìdí ọ̀ràn náà múlẹ̀. Ó sì dájú pé o kò ní fẹ́ tan ọ̀rọ̀ èké, tó lè wá sọ ẹ́ di abanijẹ́, kálẹ̀. (Òwe 16:28; 18:8) Ṣùgbọ́n, ohun tí Jésù wí ni pé, mú ẹnì kan tàbí méjì dání. Èé ṣe tó fi sọ bẹ́ẹ̀? Àwọn wo la sì lè mú dání?

      14. Ta la lè mú lọ́wọ́ táa bá fẹ́ gbé ìgbésẹ̀ kejì?

      14 Ò ń gbìyànjú láti jèrè arákùnrin rẹ̀ nípa jíjẹ́ kó mọ̀ pé ó ti ṣẹ̀ ọ́ àti pé o fẹ́ sún un láti ronú pìwà dá, kí ó bàa lè wà ní àlàáfíà pẹ̀lú rẹ àti pẹ̀lú Ọlọ́run. Kí èyí lè ṣeé ṣe, ohun tí yóò dára jù ni pé kí “ẹnì kan tàbí méjì” náà jẹ́ àwọn tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́rìí sí ohun tí ẹni yẹn ṣe. Ó lè jẹ́ pé wọ́n wà níbẹ̀ nígbà tọ́ràn náà wáyé, tàbí wọ́n ní ìsọfúnni tó ṣeé gbára lé lọ́wọ́ nípa ohun tó wáyé (tàbí tí kò wáyé) nínú ọ̀ràn ìṣòwò náà. Bí kò bá sí irú àwọn ẹlẹ́rìí bẹ́ẹ̀, àwọn tóo pè lè jẹ́ àwọn tí wọ́n ti ní ìrírí nípa irú ohun tó fa awuyewuye náà, tí wọn yóò sì lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé lóòótọ́ ni ohun tí onítọ̀hún ṣe ò dáa. Láfikún sí i, nítorí à ò mọ ẹ̀yìn ọ̀ràn, àwọn pẹ̀lú lè jẹ́ ẹlẹ́rìí sí ohun tẹ́ẹ sọ, tàbí kí wọ́n jẹ́rìí sí àwọn kókó tẹ́ẹ gbé kalẹ̀ àti ìsapá tẹ́ẹ ṣe. (Númérì 35:30; Diutarónómì 17:6) Nítorí náà, wọn kì í ṣe ẹni tí kò mọ nǹkan kan rárá nípa ọ̀ràn náà, ẹni tó jẹ́ pé ó kàn wá gbẹ́jọ́ lásán ni; síbẹ̀, wíwà tí wọ́n wà níbẹ̀ jẹ́ láti ṣèrànwọ́ láti jèrè arákùnrin rẹ àti arákùnrin wọn.

      15. Èé ṣe tí àwọn Kristẹni àlàgbà lè ṣèrànwọ́ báa bá fẹ́ gbé ìgbésẹ̀ kejì?

      15 Kò pọndandan pé àwọn alàgbà ìjọ lo gbọ́dọ̀ pè. Àmọ́ ṣá o, àwọn ọkùnrin tó dàgbà dénú, tí wọ́n jẹ́ alàgbà lè ṣèrànwọ́, nítorí àwọn ànímọ́ tẹ̀mí tí wọ́n ní. Irú àwọn alàgbà bẹ́ẹ̀ jẹ́ “ibi ìfarapamọ́sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù àti ibi ìlùmọ́ kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò, bí àwọn ìṣàn omi ní ilẹ̀ aláìlómi, bí òjìji àpáta gàǹgà ní ilẹ̀ gbígbẹ táútáú.” (Aísáyà 32:1, 2) Tó bá dọ̀ràn ká fèròwérò pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin, ká sì mú wọn padà bọ̀ sípò, onírìírí làwọn alàgbà jẹ́. Ẹni tó hùwà àìtọ́ náà yóò sì lè gbára lé irú “àwọn ẹ̀bùn [tí ó jẹ́] ènìyàn” bẹ́ẹ̀.c (Éfésù 4:8, 11, 12) Sísọ bí ọ̀ràn náà ṣe rí gan-an níwájú irú àwọn tó dàgbà dénú bẹ́ẹ̀ àti dídara pọ̀ mọ́ wọn nínú àdúrà lè yí nǹkan padà, kí ohun táa rò pé ó ti di ìṣòro ńlá wá di ìtì ọ̀gẹ̀dẹ̀, tí kò tó nǹkan tí à ń lọ àdá sí.—Fi wé Jákọ́bù 5:14, 15.

  • O Lè Jèrè Arákùnrin Rẹ
    Ilé Ìṣọ́—1999 | October 15
    • c Ọ̀mọ̀wé kan tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ ṣàlàyé pé: “Ó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ pé ẹni tó hùwà àìtọ́ yóò tẹ́tí sí ẹni méjì tàbí mẹ́ta ju ẹnì kan ṣoṣo lọ (pàápàá jù lọ bí wọ́n bá jẹ̀ àwọn tó yẹ kó bọ̀wọ̀ fún), yóò ṣòro fún un láti tẹ́tí sí ẹnì kan, pàápàá jù lọ bí onítọ̀hún bá lọ jẹ́ ẹni tí èrò wọn kò bára mu.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́