ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • O Lè Jèrè Arákùnrin Rẹ
    Ilé Ìṣọ́—1999 | October 15
    • 5, 6. Táa bá gbé àyíká ọ̀rọ̀ yẹ̀ wò, irú ẹ̀ṣẹ̀ wo ni Mátíù 18:15 ń tọ́ka sí, kí ló sì fi èyí hàn?

      5 Ní ti gidi, ìmọ̀ràn Jésù dá lórí àwọn ọ̀ràn tó túbọ̀ nípọn. Jésù wí pé: “Bí arákùnrin rẹ bá dá ẹ̀ṣẹ̀.” Ní ìtumọ̀ tó gbòòrò, “ẹ̀ṣẹ̀” lè jẹ́ àṣìṣe tàbí ìkùdíẹ̀káàtó. (Jóòbù 2:10; Òwe 21:4; Jákọ́bù 4:17) Ṣùgbọ́n, àyíká ọ̀rọ̀ náà fi hàn pé ẹ̀ṣẹ̀ tí Jésù ní lọ́kàn níhìn-ín, ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ni. Ẹ̀ṣẹ̀ náà wúwo débi tó ti lè yọrí sí kíka oníwà àìtọ́ náà sí “ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè àti gẹ́gẹ́ bí agbowó orí.” Kí ni gbólóhùn yẹn túmọ̀ sí?

      6 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ yẹn mọ̀ pé àwọn ọmọọ̀lú àwọn kò jẹ́ bá àwọn Kèfèrí ṣe wọléwọ̀de. (Jòhánù 4:9; 18:28; Ìṣe 10:28) Dájúdájú, wọ́n máa ń yẹra fáwọn agbowó orí, àwọn tó jẹ́ pé lóòótọ́ Júù ni wọ́n o, àmọ́ wọ́n ti di oníjìbìtì. Nítorí náà, ká kúkú sọjú abẹ níkòó, ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ni Mátíù 18:15-17 ń tọ́ka sí, kì í ṣe aáwọ̀ lásán láàárín ẹnì kan sẹ́nì kan tàbí ìwà àfojúdi tẹ́nì kan hù sí ọ́, tàbí ohun tẹ́nì kan ṣe tó mú ọkàn rẹ gbọgbẹ́, tóo lè dárí jì í, tàbí tóo lè gbàgbé ẹ̀.—Mátíù 18:21, 22.a

  • O Lè Jèrè Arákùnrin Rẹ
    Ilé Ìṣọ́—1999 | October 15
    • a Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, McClintock and Strong’s Cyclopedia, sọ pé: “Ọ̀dalẹ̀ àti apẹ̀yìndà ni wọ́n ka àwọn agbowó òde [àwọn agbowó orí] sí nínú Májẹ̀mú Tuntun, àwọn èèyàn gbà pé wọ́n ti di aláìmọ́ nípa ṣíṣe wọléwọ̀de pẹ̀lú àwọn abọgibọ̀pẹ̀, àwọn tí àwọn aninilára ń lò. Wọ́n kà wọ́n kún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ . . . Nítorí tí wọ́n ti di ẹni ìtanù, àwọn ọmọlúwàbí èèyàn kò jẹ́ bá wọn rìn, àwọn tó dà bíi tiwọn, àwọn ẹni àpatì bí aṣọ tó gbó nìkan lọ̀rẹ́ àti alábàákẹ́gbẹ́ wọn.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́