ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ọba Náà Yọ́ Àwọn Èèyàn Rẹ̀ Mọ́ Nípa Tẹ̀mí
    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
    • 1-3. Kí ni Jésù ṣe nígbà tó rí i pé wọ́n ti sọ tẹ́ńpìlì di ẹlẹ́gbin?

      ỌWỌ́ pàtàkì ni Jésù fi mú tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù, torí pé ó mọ ohun tí tẹ́ńpìlì náà dúró fún. Ọjọ́ pẹ́ tí tẹ́ńpìlì náà ti jẹ́ ojúkò ìjọsìn tòótọ́ lórí ilẹ̀ ayé. Àmọ́, torí pé ìjọsìn Ọlọ́run mímọ́ náà, Jèhófà, ni tẹ́ńpìlì náà wà fún, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́ àti aláìlábàwọ́n. Wá wo bó ṣe rí lára Jésù nígbà tó wọ tẹ́ńpìlì náà ní Nísàn 10, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, tí ó sì rí i pé wọ́n ti sọ tẹ́ńpìlì náà di ẹlẹ́gbin. Kí ló fà á?—Ka Mátíù 21:12, 13.

      2 Ó ṣẹlẹ̀ pé, nínú Àgbàlá àwọn Kèfèrí, àwọn olówò tí wọ́n jẹ́ oníwọra àtàwọn tó ń pààrọ̀ owó ń rẹ́ àwọn tó wá rúbọ sí Jèhófà nínú tẹ́ńpìlì jẹ.a Jésù “lé gbogbo àwọn tí ń tà, tí wọ́n sì ń rà nínú tẹ́ńpìlì síta, ó sì sojú tábìlì àwọn olùpààrọ̀ owó dé.” (Fi wé Nehemáyà 13:7-9.) Ó bá àwọn onímọtara-ẹni-nìkan yẹn wí, torí pé wọ́n sọ ilé Baba rẹ̀ di “hòrò àwọn ọlọ́ṣà.” Jésù tipa báyìí fi hàn pé ọwọ́ pàtàkì ni òun fi mú tẹ́ńpìlì náà àti ohun tó dúró fún. Ìjọsìn Baba rẹ̀ gbọ́dọ̀ wà ní mímọ́!

  • Ọba Náà Yọ́ Àwọn Èèyàn Rẹ̀ Mọ́ Nípa Tẹ̀mí
    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
    • a Ó ní irú ẹyọ owó tí àwọn Júù tó wá láti ìlú míì gbọ́dọ̀ fi san owó orí ọdọọdún ní tẹ́ńpìlì. Torí náà, àwọn tó ń pààrọ̀ owó ní tẹ́ńpìlì máa ń gba owó lọ́wọ́ wọn kí wọ́n tó lè bá wọn ṣẹ́ ẹyọ owó tí wọ́n ní lọ́wọ́ sí irú owó tí wọ́n lé lò ní tẹ́ńpìlì. Yàtọ̀ síyẹn, ó lè pọn dandan pé káwọn àlejò ra àwọn ẹran tí wọ́n máa fi rúbọ. Ó lè jẹ́ owó gọbọi tí àwọn oníṣòwò náà máa ń fi lé ọjà tàbí iye tí wọ́n ń gbà lọ́wọ́ àwọn èèyàn ló mú kí Jésù pè wọ́n ní “ọlọ́ṣà.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́