ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • A Gbà Wọ́n Là Láti Inú “Ìran Burúkú”
    Ilé-Ìṣọ́nà—1995 | November 1
    • 11. (a) Ní pàtàkì, ọlá àṣẹ wo ni ó yẹ kí ó ṣamọ̀nà wa láti pinnu bí a ṣe ní láti lo he ge·ne·aʹ hauʹte? (b) Báwo ni ọlá àṣẹ yìí ṣe lo ọ̀rọ̀ náà?

      11 Àmọ́ ṣáá o, bí àwọn òǹkọ̀wé Ìròyìn Rere tí a mí sí ṣe lo gbólóhùn Griki náà he ge·ne·aʹ hauʹte, tàbí “ìran yìí,” ní ríròyìn àwọn ọ̀rọ̀ Jesu ni àwọn Kristian tí ń kẹ́kọ̀ọ́ kókó yìí ní pàtàkì ní láti darí ìrònú wọn sí. Ó lò gbólóhùn náà déédéé lọ́nà tí kò bára dé. Nípa bẹ́ẹ̀, Jesu pe àwọn aṣáájú ìsìn Júù ní “ejò, àmújáde-ọmọ paramọ́lẹ̀,” ó sì ń bá a lọ láti sọ pé, a óò múdàájọ́ Gẹ̀hẹ́nà ṣẹ sórí “ìran yìí.” (Matteu 23:33, 36) Bí ó ti wù kí ó rí, a ha fi ìdájọ́ yìí mọ sórí àwùjọ àlùfáà alágàbàgebè bí? Bẹ́ẹ̀ kọ́ rárá. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jesu gbọ́ tí ń sọ̀rọ̀ nípa “ìran yìí,” ní lílo ọ̀rọ̀ náà lọ́nà kan náà, lọ́nà gbígbòòrò sí i. Kí nìyẹn?

  • A Gbà Wọ́n Là Láti Inú “Ìran Burúkú”
    Ilé-Ìṣọ́nà—1995 | November 1
    • 13. Níṣojú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ta ni Jesu pè ní “ìran burúkú yii” tí ó sì dẹ́bi fún?

      13 Lẹ́yìn náà ní 31 C.E., bí Jesu àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò ìwàásù wọn kejì yíká Galili, “awọn kan lára awọn akọ̀wé òfin ati awọn Farisi” béèrè àmì lọ́wọ́ Jesu. Ó sọ fún àwọn àti “ogunlọ́gọ̀ naa” tí ó pésẹ̀ pé: “Ìran burúkú ati panṣágà tẹramọ́ wíwá àmì, ṣugbọn a kì yoo fi àmì kankan fún un àyàfi àmì Jona wòlíì. Nitori gan-an gẹ́gẹ́ bí Jona ti wà ninu ikùn ẹja mùmùrara naa fún ọ̀sán mẹ́ta ati òru mẹ́ta, bẹ́ẹ̀ naa ni Ọmọkùnrin ènìyàn yoo wà ninu ọkàn-àyà ilẹ̀-ayé fún ọ̀sán mẹ́ta ati òru mẹ́ta. . . . Bẹ́ẹ̀ ni yoo rí pẹlu fún ìran burúkú yii.” (Matteu 12:38-46) Ó ṣe kedere pé, “ìran burúkú yìí” ní àwọn aṣáájú ìsìn àti “ogunlọ́gọ̀ naa,” tí kò lóye àmì náà tí ó ní ìmúṣẹ nínú ikú àti àjíǹde Jesu nínú.d

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́