ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìgbàgbọ́ Nínú Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì Máa Ń Gbani Là
    Ilé Ìṣọ́—2007 | April 1
    • Láàárín oṣù mẹ́ta péré, Cestius Gallus, Gómìnà ilẹ̀ Róòmù tó ń ṣàkóso lórí ilẹ̀ Síríà, kó àwọn ọmọ ogun tó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n [30,000] gba ọ̀nà gúúsù láti lọ paná ọ̀tẹ̀ àwọn Júù. Àkókò Àjọyọ̀ Àtíbàbà làwọn ọmọ ogun rẹ̀ dé àgbègbè Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì ya wọ àwọn ìgbèríko rẹ̀ kíákíá. Àwọn Júù Ọlọ̀tẹ̀, tí wọn ò tó nǹkan lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ ogun náà, sá lọ sínú tẹ́ńpìlì tí odi yí ká. Kò pẹ́ táwọn ọmọ ogun Róòmù fi bẹ̀rẹ̀ sí í gbẹ́ ògiri tẹ́ńpìlì náà nídìí. Ẹ̀rù ba àwọn Júù. Èèmọ̀, àwọn sójà tó jẹ́ abọ̀rìṣà ń sọ ibi táwọn ẹlẹ́sìn Júù kà sí ibi mímọ́ jù lọ di aláìmọ́! Àmọ́ o, àwọn Kristẹni tó wà nílùú yẹn rántí ọ̀rọ̀ Jésù pé: ‘Nígbà tí ẹ bá tajú kán rí ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro, tí ó dúró ní ibi mímọ́, nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí àwọn òkè ńlá.’ (Mátíù 24:15, 16) Ǹjẹ́ wọ́n á gba àsọtẹ́lẹ̀ Jésù gbọ́ kí wọ́n sì ṣe ohun tó tọ́? Bí nǹkan ṣe wá yọrí sí, èyí gba ẹ̀mí wọn là. Àmọ́ báwo ni wọ́n ṣe rọ́nà sá lọ?

      Lójijì, láìsí ìdí kan gúnmọ́, gómìnà Cestius Gallus kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kúrò wọ́n sì forí lé ọ̀nà etíkun. Báwọn Júù Ọlọ̀tẹ̀ ṣe gbá tọ̀ wọ́n lẹ́yìn nìyẹn. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ pé ìpọ́njú tó bá ìlú yẹn wá sópin lọ́gán báyẹn! Àwọn Kristẹni náà fi hàn pé àwọn nígbàgbọ́ nínú àsọtẹ́lẹ̀ Jésù, wọ́n sá jáde ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì lọ sílùú Pẹ́là tó wà lórí àwọn òkè lódìkejì Odò Jọ́dánì, níbi tí kò sí wàhálà kankan. Àkókò tó dára jù ni wọ́n sá lọ yẹn. Kò pẹ́ táwọn Júù Ọlọ̀tẹ̀ yẹn fi padà sí Jerúsálẹ́mù tí wọ́n sì ń fipá mú àwọn èèyàn tó ṣẹ́ kù sí ìlú náà láti dara pọ̀ mọ́ wọn.a Àmọ́ àwọn Kristẹni ti wà ní Pẹ́là ní tiwọn, wọ́n sì ti bọ́ lọ́wọ́ ewu, wọ́n wá ń retí àwọn nǹkan tó máa tún ṣẹlẹ̀.

  • Ìgbàgbọ́ Nínú Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì Máa Ń Gbani Là
    Ilé Ìṣọ́—2007 | April 1
    • a Òpìtàn tó jẹ́ Júù tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Josephus sọ pé ọjọ́ méje làwọn Júù Ọlọ̀tẹ̀ náà fi lépa àwọn ará Róòmù yẹn kí wọ́n tó padà sí Jerúsálẹ́mù.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́