-
“Kí Ìjọba Rẹ Dé”Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
-
-
15, 16. Àwọn wo ni Jésù pè ní “ìran yìí”?
15 Ìgbà wo gan-an wá ni Ìjọba Ọlọ́run máa dé ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́? Jésù kò sọ ìgbà pàtó tó máa dé. (Mát. 24:36) Àmọ́, ó sọ ohun kan tó yẹ kó mú un dá wa lójú pé ó ti sún mọ́lé. Jésù fi hàn pé Ìjọba náà yóò dé lẹ́yìn tí àwọn tó pè ní “ìran yìí” bá ti rí ìmúṣẹ àmì tó sọ tẹ́lẹ̀ náà. (Ka Mátíù 24:32-34.) Àwọn wo ni Jésù pè ní “ìran yìí”? Jẹ́ ká fara balẹ̀ gbé ọ̀rọ̀ yìí yẹ̀ wò.
16 “Ìran yìí.” Ṣé àwọn aláìgbàgbọ́ ni Jésù pè ní “ìran yìí”? Rárá o. Tá a bá wò ó, a ó rí i pé àwọn àpọ́sítélì mélòó kan tó “tọ̀ ọ́ wá ní ìdákọ́ńkọ́” ló ń bá sọ̀rọ̀. Àwọn ni Jésù sọ àsọtẹ́lẹ̀ náà fún. (Mát. 24:3) Ọlọ́run sì máa tó fi ẹ̀mí mímọ́ yan àwọn àpọ́sítélì yẹn. Tún wo nǹkan tí Jésù ń sọ bọ̀ kó tó mẹ́nu kan “ìran yìí.” Ó ti kọ́kọ́ sọ pé: “Wàyí o, ẹ kẹ́kọ̀ọ́ kókó yìí lára igi ọ̀pọ̀tọ́ gẹ́gẹ́ bí àpèjúwe kan pé: Gbàrà tí ẹ̀ka rẹ̀ tuntun bá yọ ọ̀jẹ̀lẹ́, tí ó sì mú ewé jáde, ẹ mọ̀ pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn sún mọ́lé. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹ̀yin pẹ̀lú, nígbà tí ẹ bá rí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, kí ẹ mọ̀ pé ó ti sún mọ́ tòsí lẹ́nu ilẹ̀kùn.” Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tó jẹ́ ẹni àmì òróró ni yóò rí àwọn nǹkan tó sọ tẹ́lẹ̀, tí wọ́n á sì fòye mọ̀ pé Jésù ti “sún mọ́ tòsí lẹ́nu ilẹ̀kùn,” kì í ṣe àwọn aláìgbàgbọ́. Torí náà, nígbà tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa “ìran yìí,” àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tó jẹ́ ẹni àmì òróró ló ní lọ́kàn.
17. Kí ni ọ̀rọ̀ náà “ìran” tí Bíbélì sọ níhìn-ín túmọ̀ sí? Kí ni gbólóhùn ọ̀rọ̀ náà “gbogbo nǹkan wọ̀nyí” túmọ̀ sí?
17 “Kì yóò kọjá lọ lọ́nàkọnà títí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹlẹ̀.” Báwo lọ̀rọ̀ yìí ṣe máa ṣẹ? Ká lè rí ìdáhùn ìbéèrè yìí, ó yẹ ká mọ ohun méjì kan, ìyẹn ni: ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà “ìran” àti gbólóhùn náà “gbogbo nǹkan wọ̀nyí.” Ọ̀rọ̀ náà “ìran” sábà máa ń tọ́ka sí àwọn èèyàn kan tí ọjọ́ orí wọn yàtọ̀ síra, àmọ́ tí wọ́n bá ara wọn láyé tí wọ́n sì jọ gbé ayé pa pọ̀ láàárín àkókò kan. Ìran kan kì í gùn jàn-ànràn jan-anran, ó sì máa ń ní òpin. (Ẹ́kís. 1:6) Gbólóhùn náà “gbogbo nǹkan wọ̀nyí” kan gbogbo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa wáyé nígbà wíwàníhìn-ín rẹ̀, látìgbà tó ti bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914 títí tó fi máa dé ìparí rẹ̀ nígbà “ìpọ́njú ńlá.”—Mát. 24:21.
18, 19. Kí ni òye wa lórí ọ̀rọ̀ Jésù nípa “ìran yìí”? Ibo la wá lè parí ọ̀rọ̀ náà sí?
18 Kí wá ni òye wa lórí ọ̀rọ̀ Jésù nípa “ìran yìí”? Ìran yẹn jẹ́ àwùjọ ẹni àmì òróró méjì tí ọ̀kan bá èkejì láyé tí wọ́n sì jọ gbé ayé láàárín àkókò kan. Àwùjọ àkọ́kọ́ ni àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n rí ìgbà tí àmì náà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ lọ́dún 1914. Àwùjọ kejì ni àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n bá àwùjọ àkọ́kọ́ láyé, tí àwọn méjèèjì sì jọ gbé láyé láàárín ìgbà kan. Ó kéré tán, àwọn kan lára àwùjọ kejì yóò ṣì wà láyé nígbà tí ìpọ́njú ńlá tó ń bọ̀ máa bẹ̀rẹ̀. Àwùjọ méjèèjì yìí jẹ́ ìran kan torí pé wọ́n jọ jẹ́ ẹni àmì òróró pa pọ̀ láàárín àkókò kan.c
19 Ibo la wá lè parí ọ̀rọ̀ yìí sí? Ohun kan ni pé a mọ̀ dájú pé àmì tó fi hàn pé Jésù ti wà níhìn-ín gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run hàn kedere kárí ayé. A sì tún rí i pé àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ “ìran yìí” ti ń darúgbó lọ; bẹ́ẹ̀ sì rèé wọn kò ní kú tán kí ìpọ́njú ńlá tó bẹ̀rẹ̀. Èyí jẹ́ ká mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run ti dé tán báyìí láti wá máa ṣàkóso ilẹ̀ ayé! Ẹ wo bí inú wa ṣe máa dùn tó tí àdúrà tí Jésù kọ́ wa ká máa gbà pé “Kí ìjọba rẹ dé,” bá ń ṣẹ níṣojú wa!
-