-
Ṣé Wàá “Máa Bá A Nìṣó Ní Ṣíṣọ́nà”?Ilé Ìṣọ́—2015 | March 15
-
-
9. (a) Ìkìlọ̀ wo ni Jésù ṣe nípa bí ẹnì kan ṣe lè di ẹni tó ń tòògbé? (b) Kí làwọn ẹni àmì òróró ti ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ igbe to ta pé: “Ọkọ ìyàwó ti dé”? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
9 Ànímọ́ kejì tó mú káwọn wúńdíá náà lè múra sílẹ̀ dáadáa ni bí wọn ṣe wà lójúfò. Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí oorun gbé ẹnikẹ́ni lọ lára àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró láàárín àkókò gígùn tá a retí pé kí wọ́n fi ṣọ́nà lóru? Bẹ́ẹ̀ ni. Kíyè sí ohun tí Jésù sọ nípa àwọn wúńdíá mẹ́wàá náà, ó ní: Nígbà tí ọkọ ìyàwó kò tètè dé “gbogbo wọn tòògbé, wọ́n sì sùn lọ.” Jésù mọ̀ pé bẹ́nì kan tiẹ̀ fẹ́ ṣe ohun tí ó tọ́ tó sì wù ú gan-an, àìpé ṣì lè ṣàkóbá fún un. Àwọn olóòótọ́ ẹni àmì òróró ti fetí sí ìkìlọ̀ yìí, wọ́n sì ti ṣiṣẹ́ kára láti rí i dájú pé àwọn wà lójúfò, àwọn sì ń ṣọ́nà. Nínú àkàwé yìí, gbogbo àwọn wúńdíá náà ló ta jí, tí wọ́n sì dáhùn nígbà tí igbe ta lóru pé: “Ọkọ ìyàwó ti dé!” Àmọ́ ìwọ̀nba àwọn tó wà lójúfò ló fara dà á títí dé òpin. (Mát. 25:5, 6; 26:41) Àwọn olóòótọ́ ẹni àmì òróró òde òní ńkọ́? Jálẹ̀ àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, wọ́n ń ṣiṣẹ́ lórí àwọn ẹ̀rí tó dájú tí wọ́n rí tó dà bí igbe tó ta pé, “Ọkọ ìyàwó ti dé,” ìyẹn àwọn àmì tó ń fi hàn pé ó ti fẹ́rẹ̀ dé. Wọ́n tún lo ìfaradà ní ti pé gbogbo ìgbà ni wọ́n múra sílẹ̀ de Ọkọ ìyàwó tó ń bọ̀ náà.a Àmọ́ o, àárín àkókò míì tó ṣe pàtó ni lájorí ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé nínú àkàwé náà máa ní ìmúṣẹ. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀?
-
-
Ṣé Wàá “Máa Bá A Nìṣó Ní Ṣíṣọ́nà”?Ilé Ìṣọ́—2015 | March 15
-
-
a Nínú àkàwé náà, àlàfo tó ṣe kedere wà láàárín ìgbà tí igbe ta pé, “Ọkọ ìyàwó ti dé!” (ẹsẹ 6) àti ìgbà tí ó tó wọlé dé gan-an tàbí tí ó tó fara hàn (ẹsẹ 10). Ní gbogbo ọjọ́ ìkẹyìn yìí, àwọn ẹni àmì òróró tó wà lójúfò ti róye àmì wíwà níhìn-ín Jésù. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n mọ̀ pé ó ti “dé,” Ìjọba rẹ̀ sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso. Ohun tó wá kù báyìí ni pé wọ́n gbọ́dọ̀ fara dà á títí tó fi máa wọlé dé tàbí tó fi máa fara hàn.
-