ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Àpèjúwe Nípa Àwọn Tálẹ́ńtì Náà
    Ilé Ìṣọ́—2015 | March 15
    • ẸRÚ BURÚKÚ ÀTI ONÍLỌ̀Ọ́RA

      14, 15. Ǹjẹ́ ohun tí Jésù ń sọ ni pé èyí tó pọ̀ nínú àwọn ọmọlẹ́yìn òun tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn máa di ẹrú burúkú àti onílọ̀ọ́ra? Ṣàlàyé.

      14 Nínú àkàwé náà, ẹrú kẹta lọ ri tálẹ́ńtì rẹ̀ mọ́lẹ̀, dípò kó fi ṣòwò tàbí kó lọ fi sí báńkì. Ẹrú náà fi hàn pé èèyàn burúkú ni òun, torí ṣe ló mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tó lòdì sí ohun tí ọ̀gá rẹ̀ fẹ́. Abájọ tí ọ̀gá náà fi pè é ní ẹrú “burúkú àti onílọ̀ọ́ra.” Ọ̀gá náà gba tálẹ́ńtì náà lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì fún ẹrú tó ní mẹ́wàá. Wọ́n sì ju ẹrú burúkú náà “síta nínú òkùnkùn lóde.” “Níbẹ̀ ni ẹkún rẹ̀ àti ìpayínkeke rẹ̀ yóò wà.”—Mát. 25:24-30; Lúùkù 19:22, 23.

      15 Jésù sọ pé ọ̀kan nínú àwọn ẹrú mẹ́ta náà fi tálẹ́ńtì rẹ̀ pa mọ́. Ṣé ohun tó wá ń sọ ni pé ìdá kan nínú mẹ́ta lára àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn yóò jẹ́ ẹrú burúkú àti onílọ̀ọ́ra? Rárá o. Jẹ́ ká wo àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ kó tó sọ àkàwé yìí. Nínú àpèjúwe ẹrú olóòótọ́ àti olóye náà, Jésù sọ nípa ẹrú burúkú kan tó na àwọn míì tí wọ́n jọ jẹ́ ẹrú. Jésù ò fìyẹn sọ tẹ́lẹ̀ pé ẹgbẹ́ ẹrú búburú kan máa jẹ yọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ń kìlọ̀ fún ẹrú olóòótọ́ náà pé kó má ṣe hùwà bí ẹrú burúkú náà. Bákan náà, nínú àpèjúwe àwọn wúńdíá mẹ́wàá náà, Jésù ò sọ pé ìdajì nínú àwọn ọmọlẹ́yìn òun tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn ló máa dà bí àwọn òmùgọ̀ wúńdíá márùn-ún náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ń kìlọ̀ fún wọn nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ tí wọn ò bá wà lójúfò tí wọn ò sì múra sílẹ̀.f Látinú ohun tá a gbé yẹ̀ wò yìí, ó dà bíi pé ó bọ́gbọ́n mu tá a bá gbà pé Jésù ò fi àpèjúwe nípa tálẹ́ńtì sọ pé èyí tó pọ̀ nínú àwọn tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn yóò di ẹni burúkú àti onílọ̀ọ́ra láwọn ọjọ́ ìkẹyìn. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jésù ń kìlọ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn pé kí wọ́n jẹ́ aláápọn bí wọ́n ṣe ń ‘fi tálẹ́ńtì wọn ṣòwò,’ kí wọ́n má sì fìwà àti ìṣe jọ ẹrú burúkú náà.—Mát. 25:16.

  • Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Àpèjúwe Nípa Àwọn Tálẹ́ńtì Náà
    Ilé Ìṣọ́—2015 | March 15
    • Ẹrú Burúkú àti Onílọ̀ọ́ra.

      Ọ̀gá náà pàṣẹ pé kí wọ́n ju ẹrú burúkú náà sóde

      Òye wa tẹ́lẹ̀: Ẹrú burúkú àti onílọ̀ọ́ra náà ń tọ́ka sí àwọn ẹni àmì òróró tó kọ̀ láti lọ́wọ́ sí iṣẹ́ ìwàásù ní ọdún 1914.

      Òye wa tuntun: Jésù kò sọ tẹ́lẹ̀ pé ẹgbẹ́ ẹrú búburú kan máa jẹ yọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ń kìlọ̀ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ tí wọ́n bá lọ hùwà tó máa jẹ́ kí wọ́n dà bí ẹrú burúkú àti onílọ̀ọ́ra náà.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́