-
Kí Ní Ń Sún Ọ Láti Ṣiṣẹ́sin Ọlọrun?Ilé-Ìṣọ́nà—1995 | June 15
-
-
17. Ní ọ̀rọ̀ tìrẹ, ṣàlàyé òwe àkàwé tálẹ́ńtì ní kúkúrú.
17 Gbé òwe àkàwé Jesu nípa tálẹ́ńtì yẹ̀wò, gẹ́gẹ́ bí a ṣe kọ ọ́ ní Matteu 25:14-30. Ọkùnrin kan tí ó máa tó rín ìrìn-àjò lọ sí ìdálẹ̀ fi ọlá-àṣẹ pé àwọn ẹrú rẹ̀ ó sì fi àwọn nǹkan ìní rẹ̀ lé wọn lọ́wọ́. “Ó sì fi talẹnti márùn-ún fún ọ̀kan, méjì fún òmíràn, ati ẹyọkan fún òmíràn síbẹ̀, fún olúkúlùkù ní ìbámu pẹlu agbára ìlèṣe nǹkan tirẹ̀.” Nígbà tí ọ̀gá náà padà dé láti yanjú ìṣirò owó pẹ̀lú àwọn ẹrú rẹ̀, kí ni ó rí? Ẹrú tí a ti fún ní tálẹ́ńtì márùn-ún jèrè márùn-ún síi. Bákan náà, ẹrú tí a ti fún ní tálẹ́ńtì méjì jèrè méjì síi. Ẹrú tí a ti fún ní tálẹ́ńtì kan bò ó mọ́ inú ilẹ̀ kò sì ṣe ohunkóhun láti sọ ọrọ̀ ọ̀gá rẹ̀ di púpọ̀. Báwo ni ọ̀gá náà ṣe gbé ipò náà yẹ̀wò?
-
-
Kí Ní Ń Sún Ọ Láti Ṣiṣẹ́sin Ọlọrun?Ilé-Ìṣọ́nà—1995 | June 15
-
-
19 Àmọ́ ṣáá o, a kò gbóríyìn fún ẹrú kẹta. Níti tòótọ́, a jù ú sínú òkùnkùn lóde. Níwọ̀n bí òun ti gbà tálẹ́ńtì kan, a kò lè retí pé kí ó pèsè ohun púpọ̀ gẹ́gẹ́ bí ti ẹrú náà tí ó ní tálẹ́ńtì márùn-ún. Ṣùgbọ́n, òun kò tilẹ̀ gbìyànjú! Ìdájọ́ aláìbáradé rẹ̀ ga dé ìpẹ̀kun nítorí ìwà ‘burúkú ati ìlọ́ra’ tí ó wà ní ọkàn-àyà rẹ̀, èyí tí ó fi àìnífẹ̀ẹ́ fún ọ̀gá náà hàn.
-