-
Máa Fi Ìdúróṣinṣin Ti Àwọn Arákùnrin Kristi Lẹ́yìnIlé Ìṣọ́—2015 | March 15
-
-
4 Lọ́dún 1881, ìwé ìròyìn Zion’s Watch Tower ṣàlàyé pé Jésù ni “Ọmọ ènìyàn,” tá a tún pè ní “Ọba náà.” Nígbà àtijọ́, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gbà pé ọ̀rọ̀ náà “arakọnrin mi” tó wà nínú Bibeli Mimọ ń tọ́ka sí àwọn tó máa ṣàkóso pẹ̀lú Kristi, ó sì tún ń tọ́ka sí gbogbo aráyé lẹ́yìn tí wọ́n bá ti di pípé lórí ilẹ̀ ayé. Èrò wọn ni pé ìgbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi ni yíya àgùntàn sọ́tọ̀ kúrò lára ewúrẹ́ máa wáyé. Wọ́n sì tún gbà pé ìdí tí Jésù fi máa ka àwọn kan sí àgùntàn ni pé wọ́n pa òfin Ọlọ́run nípa ìfẹ́ mọ́.
5. Báwo ni òye wa ṣe túbọ̀ ṣe kedere lọ́dún 1923?
5 Lọ́dún 1923, Jèhófà mú kí àwọn èèyàn rẹ̀ túbọ̀ lóye àpèjúwe yìí. Ilé Ìṣọ́ October 15, 1923, ṣàlàyé pé Jésù ni “Ọmọ ènìyàn” náà. Àmọ́, ó ṣe àlàyé tó bọ́gbọ́n mu tá a gbé karí Ìwé Mímọ́ to fi hàn pé kìkì àwọn tó máa ṣàkóso pẹ̀lú Kristi lọ́run, ìyẹn àwọn arákùnrin Kristi ni àwọn tá à ń sọ̀rọ̀ nípa wọn, ó sì ṣàlàyé pé àwọn àgùntàn ni àwọn tó nírètí láti máa gbé lórí ilẹ̀ ayé lábẹ́ Ìjọba Kristi. Àkókò wo ni Kristi máa ya àwọn àgùntàn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ewúrẹ́? Àpilẹ̀kọ yẹn sọ pé tó bá fi máa di ìgbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, àwọn arákùnrin Kristi á ti máa ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀ ní ọ̀run, torí náà kò ní sí pé ẹnikẹ́ni ń ràn wọ́n lọ́wọ́ tàbí pa wọ́n tì. Fún ìdí yìí, ṣáájú ìgbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi ni yíya àgùntàn sọ́tọ̀ kúrò lára ewúrẹ́ máa wáyé. Nípa ìdí tá a fi máa ka àwọn kan sí àgùntàn, àpilẹ̀kọ yẹn sọ pé ohun tó máa mú kí á ka àwọn kan sí àgùntàn ni pé wọ́n gba Jésù gẹ́gẹ́ bí Olúwa wọn, wọ́n sì gbà pé Ìjọba rẹ̀ nìkan ló lè yanjú ìṣòro aráyé.
-
-
Máa Fi Ìdúróṣinṣin Ti Àwọn Arákùnrin Kristi Lẹ́yìnIlé Ìṣọ́—2015 | March 15
-
-
7. Òye tó ṣe kedere wo la ti wá ní báyìí?
7 Lóde òní, a ti wá ní òye tó ṣe kedere nípa àpèjúwe àwọn àgùntàn àtàwọn ewúrẹ́. Nípa ti àwọn tá a sọ̀rọ̀ nípa wọn nínú àpèjúwe yìí, Jésù ni “Ọmọ ènìyàn,” ìyẹn Ọba náà. Àwọn tó pè ní “arákùnrin mi” ni àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn, tí wọ́n máa ṣàkóso pẹ̀lú Kristi ní ọ̀run. (Róòmù 8:16, 17) “Àwọn àgùntàn” àti “àwọn ewúrẹ́,” túmọ̀ sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn èèyàn ní gbogbo orílẹ̀-èdè. Àwọn yìí ò sí lára àwọn tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí yan. Àkókò wo ni ìdájọ́ náà máa wáyé? Ìdájọ́ yìí máa wáyé ní apá ìparí ìpọ́njú ńlá tó máa bẹ̀rẹ̀ láìpẹ́. Kí wá ni ìdí tí Jésù máa fi ṣèdájọ́ àwọn èèyàn gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tàbí ewúrẹ́? Èyí sinmi lé bí wọ́n bá ṣe hùwà sí àwọn tó ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé lára àwọn arákùnrin Kristi tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí yàn. Bí òpin ètò nǹkan yìí ṣe túbọ̀ ń sún mọ́lé, a dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ Jèhófà pé ó ń tan ìmọ́lẹ̀ sí àpèjúwe yìí àtàwọn àpèjúwe tó tan mọ́ ọn tó wà ní Mátíù orí 24 àti 25!
-
-
Máa Fi Ìdúróṣinṣin Ti Àwọn Arákùnrin Kristi Lẹ́yìnIlé Ìṣọ́—2015 | March 15
-
-
9 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó yẹ ká mọ̀ pé ńṣe ni Jésù ń fi àpèjúwe yẹn kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Ó ṣe kedere pé, kì í ṣe yíya àwọn àgùntàn àtàwọn ewúrẹ́ gidi sọ́tọ̀ ló ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Bákan náà, kò sọ pé ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tí òun máa ṣèdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí àgùntàn gbọ́dọ̀ bọ́ àwọn arákùnrin òun, kí wọ́n da aṣọ bò wọ́n, kí wọ́n ṣètọ́jú wọn tàbí kí wọ́n lọ wò wọ́n lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ń ṣàpèjúwe bí àwọn àgùntàn ìṣàpẹẹrẹ náà ṣe máa hùwà sí àwọn arákùnrin rẹ̀. Ìdí tó fi pe àwọn àgùntàn náà ní “olódodo” ni pé wọ́n gbà pé Kristi ní àwùjọ àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ arákùnrin rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, àwọn àgùntàn náà sì ń fi ìdúróṣinṣin ti àwọn ẹni àmì òróró lẹ́yìn ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn lílekoko yìí.—Mát. 10:40-42; 25:40, 46; 2 Tím. 3:1-5.
10. Báwo ni àwọn àgùntàn ṣe lè fi inú rere hàn sí àwọn arákùnrin Kristi?
10 Ohun kejì ni pé ó yẹ ká ṣàyẹ̀wò ohun tí Jésù ń sọ bọ̀ kó tó sọ àpèjúwe yìí. Ó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn àmì wíwàníhìn-ín rẹ̀ àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan. (Mát. 24:3) Kò pẹ́ tí Jésù bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó fi sọ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn àmì náà, ìyẹn ni pé, a ó “wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.” (Mát. 24:14) Kó tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn àgùntàn àtàwọn ewúrẹ́, ó ti sọ àpèjúwe tálẹ́ńtì. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, Jésù sọ àpèjúwe yẹn láti fi tẹnu mọ́ ọn pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn, ìyẹn àwọn “arákùnrin” rẹ̀ gbọ́dọ̀ máa fìtara ṣe iṣẹ́ ìwàásù. Àmọ́, ìwọ̀nba kéréje àwọn ẹni àmì òróró tó ṣì wà láyé nígbà wíwàníhìn-ín Jésù ní ìpèníjà ńlá kan, ìyẹn bí wọ́n ṣe máa wàásù lọ sí “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè” kí òpin tó dé. Àpèjúwe àwọn àgùntàn àtàwọn ewúrẹ́ jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ẹni àmì òróró máa ní olùrànlọ́wọ́. Torí náà, ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ọ̀nà tí àwọn tá a máa ṣèdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí àgùntàn lè gbà fi inú rere hàn sí àwọn arákùnrin Kristi ni pé kí wọ́n máa tì wọ́n lẹ́yìn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ni irú ìtìlẹ́yìn yẹn ní nínú? Ṣé kí wọ́n kàn ṣáà máa fi owó àtàwọn ohun ìní wọn ṣètìlẹ́yìn fún wọn, kí wọ́n sì máa tù wọ́n nínú ni?
-