-
Ọjọ́ Ọ̀la Wo Ni Ó Wà Fún Àwọn Àgùntàn àti Ewúrẹ́?Ilé-Ìṣọ́nà—1995 | October 15
-
-
Ọjọ́ Ọ̀la Wo Ni Ó Wà fún Ẹgbẹ́ Kọ̀ọ̀kan?
16, 17. Ọjọ́ ọ̀la wo ni àwọn àgùntàn ní?
16 Jesu sọ ìdájọ́ rẹ̀ nípa àwọn àgùntàn náà pè: “Ẹ wá, ẹ̀yin tí Baba mi ti bùkún, ẹ jogún ìjọba tí a ti pèsè sílẹ̀ fún yín lati ìgbà pípilẹ̀ ayé.” Ẹ wo irú ìkésíni ọlọ́yàyà tí èyí jẹ́—“Ẹ wá”! Sínú kí ni? Sínú ìyè àìnípẹ̀kun, gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ọ́ ní ṣókí pé: “Awọn olódodo [yóò bọ́] sínú ìyè àìnípẹ̀kun.”—Matteu 25:34, 46.
17 Nínú òwe àkàwé àwọn tálẹ́ńtì, Jesu fi ohun tí a ń béèrè lọ́wọ́ àwọn tí yóò ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀ ní ọ̀run hàn, ṣùgbọ́n nínú òwe àkàwé yìí, ó fi ohun tí a ń retí lọ́wọ́ àwọn ọmọ abẹ́ Ìjọba náà hàn. (Matteu 25:14-23) Ní pàtó, nítorí ìtìlẹ́yìn tí wọ́n fi tọkàntọkàn ṣe sí àwọn arákùnrin Jesu, àwọn àgùntàn náà jogún ayè kan nínú pápá àkóso ilẹ̀ ayé ti Ìjọba rẹ̀. Wọn yóò gbádùn ìwàláàyè nínú Paradise lórí ilẹ̀ ayé—ìfojúsọ́nà tí Ọlọrun múra sílẹ̀ fún wọn “lati ìgbà pípilẹ̀ ayé” àwọn ẹ̀dá ènìyàn tí wọ́n ṣeé rà padà.—Luku 11:50, 51.
-
-
Ọjọ́ Ọ̀la Wo Ni Ó Wà Fún Àwọn Àgùntàn àti Ewúrẹ́?Ilé-Ìṣọ́nà—1995 | October 15
-
-
19 Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli mọ̀ pé èyí kò lè túmọ̀ sí pé, ọkàn àìleèkú ti àwọn ẹni bí ewúrẹ́ yóò jìyà nínú iná ayérayé. Ó tì o, nítorí àwọn ẹ̀dá ènìyàn ni ọkàn; wọn kò ní ọkàn àìleèkú. (Genesisi 2:7; Oniwasu 9:5, 10; Esekieli 18:4) Nípa ṣíṣèdájọ́ “iná àìnípẹ̀kun” fún àwọn ewúrẹ́ náà, Onídàájọ́ náà ní ìparun tí kò ní ìrètí ọjọ ọ̀la lọ́kàn, èyí tí yóò jẹ́ òpin pátápátá fún Èṣù àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ pẹ̀lú. (Ìṣípayá 20:10, 14) Nípa báyìí, Onídàájọ́ ti Jehofa gbé àwọn ìdájọ́ yíyàtọ̀ síra kalẹ̀. Ó sọ fún àwọn àgùntàn pé, “Ẹ wá”; ó sì wí fún àwọn ewúrẹ́ pé, “Ẹ mú ọ̀nà yín pọ̀n kúrò lọ́dọ̀ mi.” Àwọn àgùntàn yóò jogún “ìyè àìnípẹ̀kun.” Àwọn ewúrẹ́ yóò sì gbà “ìkékúrò àìnípẹ̀kun.”—Matteu 25:46.b
-
-
Ọjọ́ Ọ̀la Wo Ni Ó Wà Fún Àwọn Àgùntàn àti Ewúrẹ́?Ilé-Ìṣọ́nà—1995 | October 15
-
-
21 Ṣùgbọ́n, kí ni òye tuntun yìí nípa òwe àkàwé ti àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́ túmọ̀ sí fún wa? Tóò, àwọn ènìyàn ti ń yan ìhà tí wọn yóò wà. Àwọn kan wà ní ‘ojú ọ̀nà gbígbòòrò tí ó lọ sí ìparun,’ nígbà tí àwọn mìíràn gbìyànjú láti dúró ní ‘ojú ọ̀nà tóóró tí ó lọ sí ìyè.’ (Matteu 7:13, 14) Ṣùgbọ́n, àkókò náà tí Jesu yóò kéde ìdájọ́ ìkẹyìn lórí àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́ tí a ṣàpèjúwe nínú òwe àkàwé náà ṣì wà níwájú. Nígbà tí Ọmọkùnrin ènìyàn bá wá nínú ipa iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́, òun yóò pinnu pé ọ̀pọ̀ àwọn Kristian tòótọ́—ní ti gidi, “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti àwọn àgùntàn tí wọ́n ti ṣe ìyàsímímọ́—yóò tóótun láti la apá ìkẹyìn “ìpọ́njú ńlá naa” já sínú ayé tuntun. Ìfojúsọ́nà náà ní láti jẹ́ orísun ìdùnnú nísinsìnyí. (Ìṣípayá 7:9, 14) Ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ láti inú “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè” yóò ti fi ẹ̀rí hàn pé àwọn jẹ́ olórí kunkun bí ewúrẹ́. Wọn “yoo kọjá sínú ìkékúrò àìnípẹ̀kun.” Ẹ wo irú ìtura tí èyí yóò jẹ́ fún ilẹ̀ ayé!
-
-
Ọjọ́ Ọ̀la Wo Ni Ó Wà Fún Àwọn Àgùntàn àti Ewúrẹ́?Ilé-Ìṣọ́nà—1995 | October 15
-
-
b Ìwé náà El Evangelio de Mateo sọ pé: “Ìyè ayérayé jẹ́ ìyè pàtó; òdìkejì rẹ̀ ni ìjìyà pàtó. Ọ̀rọ̀ àpọ́nlé èdè Griki náà aionios ní ìpìlẹ̀ kò tọ́ka ní pàtó sí àkókò, ṣùgbọ́n ìjójúlówó. Ìjìyà pàtó náà jẹ́ ikú ayérayé.”—Ọ̀jọ̀gbọ́n Juan Mateos tí ó ti fẹ̀yìn tì (Pontifical Biblical Institute, Romu) àti Ọ̀jọ̀gbọ́n Fernando Camacho (Theological Center, Seville), Madrid, Spania, 1981.
-