-
“Ẹ Máa Ṣe Èyí Ní Ìrántí Mi”Ilé Ìṣọ́—2013 | December 15
-
-
9. Èrò tí kò tọ̀nà wo làwọn kan ní nípa búrẹ́dì tí Jésù lò?
9 Àwọn kan tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ṣàlàyé pé ohun tí Jésù sọ ní tààràtà ni pé: ‘Èyí ni ara mi,’ torí náà wọ́n gbà gbọ́ pé búrẹ́dì yẹn yí pa dà lọ́nà ìyanu, ó sì di ẹran ara Jésù gangan. Àmọ́, ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀.a Ara Jésù wà níbẹ̀ níwájú àwọn àpọ́sítélì olóòótọ́ náà, bẹ́ẹ̀ náà sì ni búrẹ́dì aláìwú tí wọ́n máa jẹ. Ó ṣe kedere nígbà náà pé èdè ìṣàpẹẹrẹ ni Jésù lò, bó ti ṣe láwọn ìgbà míì.—Jòh. 2:19-21; 4:13, 14; 10:7; 15:1.
10. Kí ni búrẹ́dì tá a máa ń lò nígbà Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa dúró fún?
10 Búrẹ́dì tó wà níwájú àwọn àpọ́sítélì tí wọ́n sì máa tó jẹ nínú rẹ̀ túmọ̀ sí ara Jésù. Ara wo? Ní ìgbà kan, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run rò pé níwọ̀n bí Jésù ti bu búrẹ́dì náà tó sì jẹ́ pé wọ́n kò ṣẹ́ èyíkéyìí nínú egungun rẹ̀, a jẹ́ pé búrẹ́dì náà túmọ̀ sí àwọn ẹni àmì òróró lápapọ̀, èyí tí Bíbélì pè ní “ara Kristi.” (Éfé. 4:12; Róòmù 12:4, 5; 1 Kọ́r. 10:16, 17; 12:27) Àmọ́, nígbà tó yá, a wá rí i pé téèyàn bá rò ó dáadáa, tó sì wo ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ, á rí i pé ńṣe ni búrẹ́dì náà ṣàpẹẹrẹ ara ẹ̀dá èèyàn tí Jésù ní, èyí ti a ti pèsè sílẹ̀ fún un. Jésù “jìyà nínú ẹran ara,” kódà wọ́n kàn án mọ́gi. Torí náà, nígbà Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, búrẹ́dì náà ṣàpẹẹrẹ ara ẹ̀dá èèyàn tí Jésù fi “ru àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.”—1 Pét. 2:21-24; 4:1; Jòh. 19:33-36; Héb. 10:5-7.
-
-
“Ẹ Máa Ṣe Èyí Ní Ìrántí Mi”Ilé Ìṣọ́—2013 | December 15
-
-
15, 16. Kí la máa ṣe sí búrẹ́dì náà nígbà Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa?
15 Bí ìjíròrò náà bá ń parí lọ, olùbánisọ̀rọ̀ á jẹ́ ká mọ̀ pé àkókò ti tó wàyí láti ṣe ohun tí Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé kí wọ́n ṣe. Bí a ṣe sọ lókè, ohun ìṣàpẹẹrẹ méjì ni a máa lò, búrẹ́dì aláìwú àti wáìnì pupa. Àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ náà lè wà lórí tábìlì lẹ́gbẹ̀ẹ́ olùbánisọ̀rọ̀. Ó máa pe àfiyèsí sí ẹsẹ Bíbélì kan tó ṣàlàyé ohun tí Jésù sọ àti ohun tó ṣe nígbà tó dá ìṣẹ̀lẹ̀ àkànṣe náà sílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, a rí i kà nínú ìwé Mátíù pé: “Jésù mú ìṣù búrẹ́dì kan, lẹ́yìn sísúre, ó bù ú, ní fífi í fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ó sì wí pé: ‘Ẹ gbà, ẹ jẹ. Èyí túmọ̀ sí ara mi.’” (Mát. 26:26) Jésù bu búrẹ́dì aláìwú náà kó lè fún àwọn àpọ́sítélì tó jókòó sí apá ọ̀tún àti apá òsì rẹ̀. Tó o bá dé ìpàdé yẹn ní April 14, wàá rí búrẹ́dì aláìwú mélòó kan tí wọ́n ti kán sí wẹ́wẹ́ tí wọ́n sì kó sínú àwo tí wọ́n á fi gbé e káàkiri.
-