-
“Ẹ Wò Ó! Ọkunrin Naa!”Ilé-Ìṣọ́nà—1991 | January 1
-
-
Nitori naa, ní ìbámu pẹlu ohun ti wọn fi dandangbọ̀n béèrè—ati fífẹ́ lati tẹ́ ogunlọgọ naa lọ́rùn ju lati ṣe ohun tí ó tọ̀nà lọ—Pilatu tú Barabba silẹ fun wọn. Oun mú Jesu ó sì jẹ́ kí wọn bọ́ ọ ní aṣọ ki wọn sì nà án lọ́rẹ́ lẹhin naa. Eyi kii ṣe nínà ní pàṣán ṣákálá. The Journal of the American Medical Association ṣàpèjúwe àṣà ìnanilọ́rẹ́ awọn ará Romu:
“Ohun-èèlò ti a saba maa nlo ni pàṣán tẹ́ẹ́rẹ́ (flagrum tabi flagellum) kòbókò awọ ẹlẹ́yọkọọkan melookan tabi alahunpọ tí gígùn wọn kò báradọ́gba, ti a wa so awọn irin ródóródó kéékèèké tabi awọn eegun àgùtàn wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ mímú mọ́ kaakiri. . . . Bí awọn ọmọ-ogun Romu ti ńlu ẹ̀hìn òjìyà naa léraléra pẹlu ipá, awọn irin ródóródó naa yoo dá awọn ìdáranjẹ̀ jíjìn, kòbókò aláwọ naa ati awọn egun àgùtàn yoo sì bẹ́ awọ ara naa ati awọn ẹran isalẹ awọ. Nigbanaa, bí ìnàlọ́rẹ́ naa ti nbaalọ, ara ti nbẹ naa yoo fayakan awọn iṣu-ẹran ti wọn wà lara eegun yoo sì sọ ẹran-ara di ẹlẹ́jẹ̀ jálajàla.”
-
-
“Ẹ Wò Ó! Ọkunrin Naa!”Ilé-Ìṣọ́nà—1991 | January 1
-
-
Bí ó tilẹ jẹ́ pe a dọgbẹ sii lara ti a si ti han an leemọ ika, níhìn-ín ni sàràkí ẹ̀dá títayọ julọ ninu gbogbo ìtàn dúró, ọkunrin títóbi jùlọ nitootọ tí ó tíì gbé láyé rí! Bẹẹni, Jesu fi iyì-ọlá dídákẹ́rọ́rọ́ ati ìparọ́rọ́ han eyi tí ó tọka si ìtóbilọ́lá kan tí Pilatu pàápàá gbọdọ jẹ́wọ́, nitori awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọna tí ó hàn gbangba jẹ́ ìdàpọ̀mọ́ra ọ̀wọ̀ ati ìkáàánú. Johanu 18:39–19:5; Matiu 27:15-17, 20-30, NW; Maaku 15:6-19; Luku 23:18-25.
-