ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ‘Torí Náà, Ẹ Lọ, Kí Ẹ Máa Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn’
    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020 | January
    • 1-2. Kí ni áńgẹ́lì kan sọ fún àwọn obìnrin tó wá sí ibojì Jésù, ìtọ́ni wo ni Jésù alára sì fún wọn?

      OHUN kan ṣẹlẹ̀ láàárọ̀ kùtù Nísàn 16, 33 Sànmánì Kristẹni. Lẹ́yìn ohun tó ju wákàtí mẹ́rìndínlógójì (36) tí wọ́n ti sin Jésù, àwọn obìnrin mélòó kan tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run gbéra lọ síbi tí wọ́n tẹ́ òkú rẹ̀ sí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣì ń ṣọ̀fọ̀. Ohun tí wọ́n ní lọ́kàn ni pé táwọn bá débẹ̀, àwọn máa fi àwọn èròjà tó ń ta sánsán àti òróró onílọ́fínńdà pa ara rẹ̀, àmọ́ ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ pé wọn ò bá òkú náà nígbà tí wọ́n débẹ̀! Áńgẹ́lì kan yọ sí wọn, ó sì sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà pé Jésù ti jíǹde, ó wá fi kún un pé: “Ó ń lọ sí Gálílì ṣáájú yín. Ẹ máa rí i níbẹ̀.”​—Mát. 28:1-7; Lúùkù 23:56; 24:10.

  • ‘Torí Náà, Ẹ Lọ, Kí Ẹ Máa Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn’
    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020 | January
    • 4 Gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ni Jésù fẹ́ kó máa wàásù. Kì í ṣe àwọn àpọ́sítélì mọ́kànlá tó jẹ́ olóòótọ́ nìkan làṣẹ yẹn kàn. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká wò ó báyìí ná: Ṣé òun àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ nìkan ló wà níbi òkè kan ní Gálílì nígbà tó pàṣẹ pé kí wọ́n sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn? Ẹ rántí pé áńgẹ́lì tó yọ sáwọn obìnrin yẹn sọ fún wọn pé: “Ẹ máa rí i [ní Gálílì].” Èyí fi hàn pé àwọn obìnrin yẹn wà lára àwọn tó wà níbẹ̀ lọ́jọ́ náà. Àmọ́, àwọn míì náà tún wà níbẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù “fara han èyí tó ju ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) àwọn ará lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.” (1 Kọ́r. 15:6) Ibo ló ti ṣèpàdé pẹ̀lú ọgọ́rùn-ún márùn-ún èèyàn?

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́