ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àwọn Kristian Ẹlẹ́rìí Tí Wọ́n Ní Ẹ̀tọ́ Gẹ́gẹ́ Bí Aráàlú Ní Ọ̀run
    Ilé-Ìṣọ́nà—1995 | July 1
    • 2. Ohun titun wo ni Johannu Oníbatisí kéde pé Jesu yóò ṣe, kí sì ni ohun titun yìí tan mọ́?

      2 Nígbà tí Johannu Oníbatisí ń palẹ̀ ọ̀nà mọ́ fún Jesu, ó kéde pé Jesu yóò ṣe ohun titun. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “[Johannu] . . . a máa wàásù, wí pé: ‘Lẹ́yìn mi ẹni kan tí ó lókunlágbára jù mí lọ ń bọ̀; emi kò yẹ lati bẹ̀rẹ̀ tú awọn okùn sálúbàtà rẹ̀. Emi fi omi batisí yín, ṣugbọn oun yoo fi ẹ̀mí mímọ́ batisí yín.’” (Marku 1:7, 8) Ṣáájú àkókò yẹn, a kò tíì fi ẹ̀mí mímọ́ batisí ẹnikẹ́ni. Èyí jẹ́ ìṣètò titun kan tí ó ní ẹ̀mí mímọ́ nínú, ó sì ní ín ṣe pẹ̀lú ète tí Jehofa ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ ṣípayá láti múra àwọn ẹ̀dá ènìyàn sílẹ̀ fún ìṣàkóso ti ọ̀run.

  • Àwọn Kristian Ẹlẹ́rìí Tí Wọ́n Ní Ẹ̀tọ́ Gẹ́gẹ́ Bí Aráàlú Ní Ọ̀run
    Ilé-Ìṣọ́nà—1995 | July 1
    • 5. Nígbà wo ni a kọ́kọ́ fi ẹ̀mí mímọ́ batisí àwọn olùṣòtítọ́ ọmọ-ẹ̀yìn, ìṣiṣẹ́ ẹ̀mí mímọ́ tí ó fara jọ èyí wo ni ó sì ṣẹlẹ̀ ní àkókò kan náà?

      5 Nígbà tí Jesu bá Nikodemu sọ̀rọ̀, a ti fi ẹ̀mí mímọ́ yan Jesu, a yàn án fún ipò ọba rẹ̀ ní ọjọ́-iwájú nínú Ìjọba Ọlọrun, Ọlọrun sì ti jẹ́wọ́ Jesu ní gbangba gẹ́gẹ́ bí Ọmọkùnrin Rẹ̀. (Matteu 3:16, 17) Jehofa bí àwọn ọmọ ẹ̀mí púpọ̀ síi ní Pentekosti 33 C.E. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn olùṣòtítọ́ tí wọ́n kórajọpọ̀ sí yàrá òkè ní Jerusalemu ni a fi ẹ̀mí mímọ́ batisí. Ní àkókò kan náà, a tún wọn bí láti inú ẹ̀mí mímọ́ láti di àwọn ọmọkùnrin ẹ̀mí Ọlọrun. (Ìṣe 2:2-4, 38; Romu 8:15) Síwájú síi, a fi ẹ̀mí mímọ́ yàn wọ́n pẹ̀lú ète ọjọ́-iwájú ti àjògún ní ọ̀rún, a sì fi èdídí dí wọn ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ìtọ́wò ìjótìítọ́ ìrètí náà ní ọ̀run.—2 Korinti 1:21, 22.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́