ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ṣé Iná Ọ̀run Àpáàdì Ni Jésù Ní Lọ́kàn?
    Ilé Ìṣọ́—2008 | June 15
    • ÀWỌN kan tó gba ẹ̀kọ́ iná ọ̀run àpáàdì gbọ́ sábà máa ń fi ọ̀rọ̀ Jésù tó wà ní Máàkù 9:48 (tàbí ẹsẹ 44 àti 46) ti ẹ̀kọ́ yìí lẹ́yìn. Nínú ẹsẹ Bíbélì yẹn, Jésù sọ̀rọ̀ nípa kòkòrò mùkúlú (tàbí ìdin) tí kì í kú àti iná tí wọn kì í pa. Tẹ́nì kan bá bi ọ́ ní ohun kan nípa àwọn ọ̀rọ̀ yẹn, kí lo máa sọ?

      Irú ìtumọ̀ Bíbélì tí ẹni náà bá lò ló máa pinnu bóyá ó máa ka ẹsẹ 44 àti 46, tàbí ẹsẹ 48, torí pé ohun kan náà ló wà nínú àwọn ẹsẹ yẹn nínú àwọn Bíbélì kan.a Àmọ́ ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun rèé: “Bí ojú rẹ bá sì mú ọ kọsẹ̀, sọ ọ́ nù; ó sàn fún ọ láti wọ ìjọba Ọlọ́run ní olójú kan ju kí a gbé ọ pẹ̀lú ojú méjì sọ sínú Gẹ̀hẹ́nà, níbi tí ìdin wọn kì í kú, tí a kì í sì í pa iná náà.”—Máàkù 9:47, 48.

  • Ṣé Iná Ọ̀run Àpáàdì Ni Jésù Ní Lọ́kàn?
    Ilé Ìṣọ́—2008 | June 15
    • a Kò sí ẹsẹ 44 àti 46 nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ Bíbélì tó péye jù lọ. Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ gbà pé, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n fi àwọn ẹsẹ méjì yìí kún un nígbà tó yá. Ọ̀jọ̀gbọ́n kan tó ń jẹ́ Archibald T. Robertson sọ pé: “Kò sí ẹsẹ méjèèjì yìí nínú ìwé àfọwọ́kọ Bíbélì tó lọ́jọ́ lórí jù, tó sì péye jù lọ. Inú ìwé àfọwọ́kọ Bíbélì ti Ìwọ̀-Oòrùn àti ti Síríà (Bìsáńṣíọ̀mù) ló ti wá. Ohun tó wà ní ẹsẹ 48 ni wọ́n kàn tún sọ ní ẹsẹ 44 àti 46. Ìdí nìyí tá a fi [fo] ẹsẹ 44 àti 46 torí wọn kì í ṣe ojúlówó.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́