ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ‘Kí Ni Yóò Ṣe Àmì Wíwàníhìn-Ín Rẹ?’
    Ilé-Ìṣọ́nà—1994 | February 15
    • 16. Apá-ìhà wo ni Luku 21:24 fikún àsọtẹ́lẹ̀ Jesu, ìjẹ́pàtàkì wo sì ni èyí ní?

      16 Bí a bá ṣe ìfiwéra Matteu 24:​15-⁠28 àti Marku 13:​14-⁠23 pẹ̀lú Luku 21:​20-⁠24, a óò rí ohun kejì tí ó fihàn pé àsọtẹ́lẹ̀ Jesu gbòòrò rékọjá ìparun Jerusalemu. Rántí pé Luku nìkanṣoṣo ni ó mẹ́nukan àjàkálẹ̀-àrùn. Bákàn náà, òun nìkanṣoṣo ni ó mú ẹ̀ka-ìpín yìí wá sí ìparí pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ Jesu náà pé: “Àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì tẹ Jerusalemu mọ́lẹ̀, títí àwọn àkókò tí a yànkalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè [“àkókò àwọn Keferi,” King James Version] yóò fi pé.”e (Luku 21:24, NW) Àwọn ará Babiloni mú ọba àwọn Ju tí ó jẹ kẹ́yìn kúrò ní 607 B.C.E., lẹ́yìn èyíinì, Jerusalemu, tí ó dúró fún Ìjọba Ọlọrun, ni a tẹ̀ mọ́lẹ̀. (2 Awọn Ọba 25:1-⁠26; 1 Kronika 29:23; Esekieli 21:​25-⁠27) Ní Luku 21:24, Jesu fihàn pé ipò-ọ̀ràn náà yóò máa báa lọ wọnú ọjọ́-ọ̀la títí di ìgbà tí àkókò náà bá tó fún Ọlọrun láti tún Ìjọba kan gbé kalẹ̀.

  • ‘Kí Ni Yóò Ṣe Àmì Wíwàníhìn-Ín Rẹ?’
    Ilé-Ìṣọ́nà—1994 | February 15
    • e  Ọ̀pọ̀ rí ìyípadà nínú ìtẹnumọ́ nínú àkọsílẹ̀ Luku lẹ́yìn Luku 21:24. Dókítà Leon Morris sọ pé: “Jesu ń báa lọ láti sọ̀rọ̀ nípa àkókò àwọn Keferi. . . . Gẹ́gẹ́ bí èrò ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀, àfiyèsí ti yí sórí ìpadàbọ̀ Ọmọkùnrin ènìyàn báyìí.” Ọ̀jọ̀gbọ́n R. Ginns kọ̀wé pé: “Ìpadàbọ̀ Ọmọkùnrin Ènìyàn​—⁠(Mt 24:​29-⁠31; Mk 13:​24-⁠27). Mímẹ́nukan ‘àkókò àwọn Keferi’ pèsè ìnasẹ̀-ọ̀rọ̀ fún ẹṣin-ọ̀rọ̀ yìí; ojú-ìwòye [ti Luku] nísinsìnyí ni a mú ríran rékọjá ìparun Jerusalemu wọnú ọjọ́-ọ̀la.”

      f  Ọ̀jọ̀gbọ́n Walter L. Liefeld kọ̀wé pé: “Ó ṣeéṣe nítòótọ́ láti tànmọ́ọ̀ pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Jesu ní àwọn ìpele ìdàgbàsókè méjì nínú: (1) àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ A.D. 70 tí wọ́n wémọ́ tẹmpili náà àti (2) àwọn wọnnì tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú jíjìnnà-réré, tí a fi ọ̀rọ̀ tí ó túbọ̀ jẹ́ ti ìṣípayá ṣàpèjúwe.” Àlàyé-ọ̀rọ̀ tí J. R. Dummelow jẹ́ olùyẹ̀wòṣàtúnṣe fún sọ pé: “Ọ̀pọ̀ nínú àwọn ìṣòro lílekoko inú ọ̀rọ̀-àwíyé ńlá yìí pòórá nígbà tí ó di mímọ̀ pé Oluwa wa kò tọ́ka sí ìṣẹ̀lẹ̀ kanṣoṣo nínú rẹ̀ bíkòṣe méjì, àti pé èyí àkọ́kọ́ jẹ́ àpẹẹrẹ-òjìji fún èyí èkejì. . . . Ní pàtàkì [Luku] 21:24, tí ó sọ̀rọ̀ nípa ‘àkókò àwọn Keferi,’ . . . pààlà àkókò kan tí kò ṣe pàtó sáàárín ìṣubú Jerusalemu àti òpin ayé.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́