ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa—Báwo Ni A Ṣe Níláti Ṣe É Lemọ́lemọ́ Tó?
    Ilé-Ìṣọ́nà—1994 | March 15
    • Ayẹyẹ Kanṣoṣo Náà

      Ayẹyẹ yìí ni Jesu fi lélẹ̀ ní ọjọ́ náà tí ó kú. Ó ti ṣèrántí àsè Ìrékọjá ti àwọn Ju pẹ̀lú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Lẹ́yìn náà ó fi díẹ̀ nínú àkàrà aláìwú ti Ìrékọjá náà fún wọn, ní wíwí pé: “Èyí ni ara mi tí a fifún yín.” Tẹ̀lé ìyẹn, Jesu fi ago wáìní kan fún wọn, ní wíwí pé: “Ago yìí ni májẹ̀mú titun [nínú] ẹ̀jẹ̀ mi, tí a ta sílẹ̀ fún yín.” Ó tún sọ pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” (Luku 22:19, 20; 1 Korinti 11:​24-⁠26) Ayẹyẹ yìí ni a pè ní Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa, tàbí Ìṣe-Ìrántí. Òun ni ayẹyẹ kanṣoṣo tí Jesu pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti ṣe é.

      Àwọn ṣọ́ọ̀ṣì púpọ̀ sọ pé àwọn ń pa ayẹyẹ yìí mọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ayẹyẹ-ìsìn wọn yòókù, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ jùlọ ń ṣayẹyẹ rẹ̀ lọ́nà tí ó yàtọ̀ sí bí Jesu ti pa á láṣẹ. Bóyá ìyàtọ̀ tí ó gbàfiyèsí jùlọ ni ìṣelemọ́lemọ́ ayẹyẹ náà. Àwọn ṣọ́ọ̀ṣì kan ń ṣe é lóṣooṣù, lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, àní lójoojúmọ́ pàápàá. Èyí ha ni ohun tí Jesu ní lọ́kàn nígbà tí ó sọ́ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi” bí? The New English Bible sọ pé: “Ẹ ṣe èyí gẹ́gẹ́ bí ìrántí mi.” (1 Korinti 11:​24, 25) Báwo ni a ti ń ṣe ìrántí tàbí àyájọ́ kan lemọ́lemọ́ tó? Ó sábà máa ń jẹ́ ẹ̀ẹ̀kanṣoṣo lọ́dún.

      Rántí, pẹ̀lú, pé Jesu bẹ̀rẹ̀ ayẹyẹ yìí ó sì kú lẹ́yìn náà ní oṣù Nisan 14 lórí kàlẹ́ndà àwọn Ju.a Ìyẹn jẹ́ ọjọ́ Ìrékọjá, àjọyọ̀ kan tí ń rán àwọn Ju létí ìdáǹdè títóbilọ́lá tí wọ́n ní ìrírí rẹ̀ ní Egipti ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún B.C.E. Ní àkókò náà ẹbọ ọ̀dọ́-àgùtàn kan yọrísí ìgbàlà fún àkọ́bí àwọn Ju, nígbà tí ó jẹ́ pé angẹli Jehofa pa gbogbo àkọ́bí àwọn ará Egipti.​—⁠Eksodu 12:​21, 24-⁠27.

      Báwo ni èyí ṣe ṣèrànwọ́ fún òye wa? Ó dára, Kristian aposteli Paulu kọ̀wé pé: “A ti fi ìrékọjá wa, àní Kristi, rúbọ fún wa.” (1 Korinti 5:⁠7) Ikú Jesu jẹ́ ẹbọ Ìrékọjá títóbi jù, ní fífún aráyé ní àǹfààní fún ìgbàlà kan tí ó tóbilọ́lá púpọ̀. Nítorí náà, fún àwọn Kristian, Ìṣe-Ìrántí ikú Kristi ti rọ́pò Ìrékọjá àwọn Ju.​—⁠Johannu 3:⁠16.

      Ìrékọjá jẹ́ ayẹyẹ ẹlẹ́ẹ̀kan lọ́dún. Nígbà náà, lọ́nà tí ó bá ọgbọ́n ìrònú mu, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ní Ìṣe-Ìrántí jẹ́. Ìrékọjá​—⁠ní ọjọ́ náà tí Jesu kú​—⁠sábà máa ń bọ́ sí ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Nisan ti àwọn Ju. Fún ìdí yìí, ikú Kristi ni a níláti ṣèrántí rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan lọ́dún ni ọjọ́ tí ó dọ́gba pẹ̀lú Nisan 14 lórí kàlẹ́ńdà. Ní 1994 ọjọ́ yẹn jẹ́ Saturday, March 26, lẹ́yìn tí oòrùn bá ti wọ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, èéṣe tí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹndọm kò fi tíì sọ èyí di ọjọ́ ayẹyẹ àkànṣe kan? Wíwo ọ̀rọ̀-ìtàn ní ṣókí yóò dáhùn ìbéèrè yẹn.

  • Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa—Báwo Ni A Ṣe Níláti Ṣe É Lemọ́lemọ́ Tó?
    Ilé-Ìṣọ́nà—1994 | March 15
    • a Nisan, oṣù àkọ́kọ́ nínú ọdún àwọn Ju, bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìfarahàn òṣùpá titun. Nípa báyìí, Nisan 14 máa ń sábàá jẹ́ nígbà òṣùpá àrànmọ́jú.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́