-
“New World Translation”—O Fi Ijinlẹ Ẹ̀kọ́ Hàn Kò Sì Fi Otitọ PamọIlé-Ìṣọ́nà—1991 | March 1
-
-
Ni Luuku 4:18, gẹgẹ bi New World Translation ti wi, Jesu fi asọtẹlẹ ti o wa ninu Aisaya silo fun ara rẹ̀, ni wiwipe: “Ẹmi Jehofa nbẹ lara mi.” (Aisaya 61:1) Ọpọlọpọ tako lilo orukọ naa Jehofa nihin-in. Bi o ti wu ki o ri, o wulẹ jẹ ọkan lara ibi ti o ju 200 lọ nibi ti orukọ yẹn ti farahan ninu New World Translation ti Iwe Mimọ Kristian lede Giriiki, eyi ti a npe ni Majẹmu Titun. Nitootọ, ko si iwe afọwọkọ Giriiki ijimiji ti “Majẹmu Titun” ti o ṣì wà ti o ni orukọ ara-ẹni ti Ọlọrun ninu. Ṣugbọn orukọ naa ni a fikun un ninu New World Translation fun awọn ìdí ti o yekooro, kii wulẹ ṣe lori èrò aibọgbọnmu. Awọn miiran sì ti tẹle ipa-ọna kannaa. Ninu èdè German nikan, o keretan awọn ẹda itumọ 11 lo “Jehofa” (tabi itumọ iyilẹta pada ti Heberu naa, “Yahweh”) ninu ọrọ ẹsẹ iwe “Majẹmu Titun” naa, nigba ti awọn olutumọ mẹrin fi orukọ naa kun un ninu àkámọ́ lẹhin “Oluwa.”c Ohun ti o ju aadọrin itumọ èdè German lo o ninu awọn akiyesi ẹsẹ iwe tabi awọn alaye.
-
-
“New World Translation”—O Fi Ijinlẹ Ẹ̀kọ́ Hàn Kò Sì Fi Otitọ PamọIlé-Ìṣọ́nà—1991 | March 1
-
-
c Johann Babor, Karl F. Bahrdt, Petrus Dausch, Wilhelm M. L. De Wette, Georg F. Griesinger, Heinrich A. W. Meyer, Friedrich Muenter, Sebastian Mutschelle, Johann C. F. Schulz, Johann J. Stolz, ati Dominikus von Brentano. August Dächsel, Friedrich Hauck, Johann P. Lange, ati Ludwig Reinhardt ni orukọ naa ninu awọn àkámọ́.
-