ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Kì Í Bá Wọn Sọ̀rọ̀ Láìsí Àpèjúwe”
    “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn”
    • 13 Jésù tún sọ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ míì nípa ọ̀nà tó gba “Jerúsálẹ́mù lọ sí Jẹ́ríkò” yìí. Gẹ́gẹ́ bí àpèjúwe yẹn ṣe lọ, àlùfáà ló kọ́kọ́ gba ọ̀nà yẹn kọjá, lẹ́yìn náà ni ọmọ Léfì kan tún kọjá níbẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ìkankan lára àwọn méjèèjì tó dúró ṣaájò ọ̀gbẹ́ni náà. (Lúùkù 10:31, 32) Inú tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù làwọn àlùfáà ti ń sìn, àwọn ọmọ Léfì sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ àwọn àlùfáà àtàwọn ọmọ Léfì ni wọ́n máa ń lọ sun Jẹ́ríkò bí wọ́n ò bá sí lẹ́nu iṣẹ́ ní tẹ́ńpìlì; ó ṣe tán, kìlómítà mẹ́tàlélógún [ìyẹn bí ibùsọ̀ mẹ́rìnlá] ni Jẹ́ríkò sí Jerúsálẹ́mù. Ìdí rèé tí wọ́n fi máa ń gba ọ̀nà yẹn kọjá. Tún kíyè sí i pé Jésù sọ pé ọ̀gbẹ́ni náà ń “sọ̀ kalẹ̀,” kò sọ pé ó ń gòkè “láti Jerúsálẹ́mù.” Ọ̀rọ̀ yìí yé àwọn olùgbọ́ rẹ̀ dáadáa. Gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ nísàlẹ̀ ni Jẹ́ríkò wà sí Jerúsálẹ́mù. Nítorí náà, béèyàn bá ń rìnrìn àjò “láti Jerúsálẹ́mù,” ẹni náà ní láti “sọ̀ kalẹ̀” ni.b Ó hàn gbangba pé Jésù fi àwọn olùgbọ́ rẹ̀ sọ́kàn.

  • “Kì Í Bá Wọn Sọ̀rọ̀ Láìsí Àpèjúwe”
    “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn”
    • b Jésù tún sọ pé àlùfáà àti ọmọ Léfì ń bọ̀ “láti Jerúsálẹ́mù,” èyí tó túmọ̀ sí pé wọ́n ti kúrò ní tẹ́ńpìlì. Nítorí náà, kò sí àwíjàre kankan fún bí wọn ò ṣe ran ẹni tó ń kú lọ yẹn lọ́wọ́. Wọn ò lè sọ pé torí bó ṣe dà bí ẹni pé ọkùnrin tó bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọlọ́ṣà náà ti kú ni ò jẹ́ káwọn ṣaájò rẹ̀, nítorí pé táwọn bá fọwọ́ kan òkú, kò ní jẹ́ káwọn lè ṣiṣẹ́ nínú tẹ́ńpìlì fún ìwọ̀n àkókò kan.—Léfítíkù 21:1; Númérì 19:16.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́