ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jèhófà Yóò ‘Ṣe Ìdájọ́ Òdodo’
    Ilé Ìṣọ́—2006 | December 15
    • 8 Lẹ́yìn tí Jésù sọ àpèjúwe yẹn, ó sọ ẹ̀kọ́ tó wà nínú rẹ̀, ó ní: “Ẹ gbọ́ ohun tí onídàájọ́ náà wí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ aláìṣòdodo! Dájúdájú, nígbà náà, Ọlọ́run kì yóò ha mú kí a ṣe ìdájọ́ òdodo fún àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ tí ń ké jáde sí i tọ̀sán-tòru, kódà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní ìpamọ́ra sí wọn? Mo sọ fún yín, Yóò mú kí a ṣe ìdájọ́ òdodo fún wọn pẹ̀lú ìyára kánkán. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí Ọmọ ènìyàn bá dé, yóò ha bá ìgbàgbọ́ ní ilẹ̀ ayé ní ti gidi bí?”—Lúùkù 18:1-8.

  • Jèhófà Yóò ‘Ṣe Ìdájọ́ Òdodo’
    Ilé Ìṣọ́—2006 | December 15
    • 9. Kí ni kókó pàtàkì tó wà nínú àpèjúwe tí Jésù sọ nípa opó àti onídàájọ́ náà?

      9 Kókó pàtàkì tó wà nínú àpèjúwe yìí ṣe kedere. Àwọn tí àpèjúwe náà dá lé lórí mẹ́nu kan kókó pàtàkì náà, Jésù pàápàá sọ ọ́. Opó náà bẹ̀bẹ̀ pé: “Rí i pé mo rí ìdájọ́ òdodo gbà.” Onídàájọ́ náà ní: “Èmi yóò rí i pé ó rí ìdájọ́ òdodo gbà.” Jésù béèrè pé: “Ọlọ́run kì yóò ha mú kí a ṣe ìdájọ́ òdodo?” Jésù sì sọ nípa Jèhófà pé: “Yóò mú kí a ṣe ìdájọ́ òdodo fún wọn pẹ̀lú ìyára kánkán.” (Lúùkù 18:3, 5, 7, 8) Ìgbà wo gan-an ni Ọlọ́run ‘yóò ṣe ìdájọ́ òdodo’?

      10. (a) Ìgbà wo ni Jèhófà ṣe ìdájọ́ òdodo ní ọ̀rúndún kìíní? (b) Ìgbà wo ni Ọlọ́run yóò ṣe ìdájọ́ òdodo fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lóde òní, báwo ni yóò sì ṣe ṣe é?

      10 Ní ọ̀rúndún kìíní, “àwọn ọjọ́ fún pípín ìdájọ́ òdodo jáde” (tàbí, “ọjọ ẹsan,” Bibeli Mimọ) dé lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni nígbà táwọn ará Róòmù pa Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ run. (Lúùkù 21:22) Lóde òní, Jèhófà yóò ṣe ìdájọ́ òdodo fáwọn èèyàn rẹ̀ ní “ọjọ́ ńlá Jèhófà.” (Sefanáyà 1:14; Mátíù 24:21) Tó bá dìgbà yẹn, Jèhófà yóò “san ìpọ́njú padà fún àwọn tí ń pọ́n” àwọn èèyàn rẹ̀ lójú “bí [Jésù Kristi] ti ń mú ẹ̀san wá sórí àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere nípa Jésù Olúwa wa.”—2 Tẹsalóníkà 1:6-8; Róòmù 12:19.

  • Jèhófà Yóò ‘Ṣe Ìdájọ́ Òdodo’
    Ilé Ìṣọ́—2006 | December 15
    • 12, 13. (a) Ẹ̀kọ́ wo ni àpèjúwe tí Jésù sọ nípa opó àti onídàájọ́ kọ́ wa? (b) Kí nìdí tó fi lè dá wa lójú pé Jèhófà yóò gbọ́ àdúrà wa àti pé yóò ṣe ìdájọ́ òdodo?

      12 Àpèjúwe tí Jésù sọ nípa opó àti onídàájọ́ yẹn tún jẹ́ ká rí àwọn kókó pàtàkì míì. Nígbà tí Jésù ń sọ ẹ̀kọ́ tó wà nínú àpèjúwe náà, ó ní: “Ẹ gbọ́ ohun tí onídàájọ́ náà wí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ aláìṣòdodo! Dájúdájú, nígbà náà, Ọlọ́run kì yóò ha mú kí a ṣe ìdájọ́ òdodo fún àwọn àyànfẹ́ rẹ?” Àmọ́ kì í ṣe pé Jésù ń fi Jèhófà wé onídàájọ́ yìí o, bí ẹni pé bí onídàájọ́ yẹn ṣe ṣe ni Ọlọ́run náà yóò ṣe. Dípò ìyẹn, ńṣe ni Jésù sọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín Ọlọ́run àti onídàájọ́ yẹn káwọn àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lè kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì kan nípa Jèhófà. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun táwọn méjèèjì fi yàtọ̀ síra?

      13 Onídàájọ́ tí Jésù mẹ́nu kàn nínú àpèjúwe rẹ̀ jẹ́ “aláìṣòdodo,” àmọ́ “Ọlọ́run jẹ́ Onídàájọ́ òdodo.” (Sáàmù 7:11; 33:5) Ọ̀rọ̀ opó yẹn kò jẹ onídàájọ́ náà lógún rárá àti rárá, àmọ́ ọ̀rọ̀ wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan jẹ Jèhófà lógún. (2 Kíróníkà 6:29, 30) Onídàájọ́ yìí ò ṣe tán láti ran opó yẹn lọ́wọ́, àmọ́ ní ti Jèhófà, kì í ṣe pé ó ṣe tán láti ran àwọn tó ń sìn ín lọ́wọ́ nìkan ni, ńṣe ló máa ń jẹ ẹ́ lọ́kàn láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Aísáyà 30:18, 19) Ẹ̀kọ́ wo nìyẹn kọ́ wa? Ó kọ́ wa pé tí onídàájọ́ tó jẹ́ aláìṣòdodo yìí bá lè fetí sílẹ̀ sí ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ opó yẹn tó sì ṣe ìdájọ́ òdodo, mélòómélòó ni Jèhófà! Yóò gbọ́ àdúrà àwọn èèyàn rẹ̀, ó sì dájú pé yóò ṣe ìdájọ́ òdodo fún wọn.—Òwe 15:29.

      14. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká dẹni tí kò nígbàgbọ́ mọ́ pé ọjọ́ ìdájọ́ Ọlọ́run ń bọ̀?

      14 Tó bá wá rí bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé àṣìṣe ńlá gbáà làwọn tí kò nígbàgbọ́ mọ́ pé ọjọ́ ìdájọ́ Ọlọ́run máa dé ṣe. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé bí wọn ò ṣe nígbàgbọ́ mọ́ pé “ọjọ́ ńlá Jèhófà” yóò dé fi hàn pé wọn ń ṣiyèméjì pé bóyá ni Jèhófà lè mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Àmọ́ tí ẹnikẹ́ni bá sọ pé Ọlọ́run ò lè mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ, onítọ̀hún ò tọ̀nà. (Jóòbù 9:12) Ìbéèrè pàtàkì tó yẹ ká béèrè ni pé, Ǹjẹ́ a óò jẹ́ olóòótọ́ títí dé òpin? Kókó yẹn gan-an sì ni Jésù fi parí àpèjúwe tó sọ nípa opó àti onídàájọ́ náà.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́