ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Jésù . . . Nífẹ̀ẹ́ Wọn Dé Òpin”
    “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn”
    • 9 Lọ́jọ́ tí Jésù máa kú, ó jẹ́ ká rí i lọ́nà tó ṣeni láàánú pé ipò tẹ̀mí àwọn tí òun fẹ́ràn jẹ òun lógún gan-an. Fojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀. Jésù wà lórí òpó igi níbi tó ti ń jẹ̀rora burúkú burúkú. Kó tó lè mí sínú, ó ti ní láti kọ́kọ́ fi ẹsẹ̀ ti ara rẹ̀ sókè. Kò sì síyè méjì pé ìrora ńlá gbáà nìyẹn á jẹ́ fún un bí ara rẹ̀ ṣe ń fà ya níbi ojú ìṣó tí wọ́n fi kàn án lẹ́sẹ̀ tí ẹ̀yìn rẹ̀ tí wọ́n ti fi ẹgba bà jẹ́ sì ń ha òpó náà. Kó tó lè sọ̀rọ̀, ó ní láti mí sínú, èyí sì ti ní láti fa ìnira àti ìrora fún un gan-an ni. Síbẹ̀ náà, pẹ̀lú bí àtisọ̀rọ̀ ṣe nira fún Jésù tó yìí, kó tó gbẹ́mìí mì, ó kúkú tiraka sọ̀rọ̀ kan tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ Màríà ìyá rẹ̀ púpọ̀. Nígbà tó rí Màríà ìyá rẹ̀ àti àpọ́sítélì Jòhánù tí wọ́n dúró sítòsí rẹ̀, ó gbóhùn sókè débi táwọn tó dúró nítòsí fi lè gbọ́, ó sọ fún ìyá rẹ̀ pé: “Obìnrin, wò ó! Ọmọkùnrin rẹ!” Ó sì sọ fún Jòhánù pé: “Wò ó! Ìyá rẹ!” (Jòhánù 19:26, 27) Jésù mọ̀ pé yàtọ̀ sí pé àpọ́sítélì náà tó jẹ́ olóòótọ́ á ṣe ohun tó máa dín ẹ̀dùn ọkàn Màríà kù, ó tún máa pèsè nípa tara àti nípa tẹ̀mí fún un.b

      Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 164, 165

      Àwọn òbí tí wọ́n bá mọṣẹ́ wọn níṣẹ́ á máa ní sùúrù, wọ́n á sì máa bójú tó àwọn ọmọ wọn

  • “Jésù . . . Nífẹ̀ẹ́ Wọn Dé Òpin”
    “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn”
    • b Ó hàn gbangba pé opó ni Màríà nígbà yẹn àti pé àwọn ọmọ rẹ̀ yòókù ò tíì di ọmọ ẹ̀yìn Jésù.—Jòhánù 7:5.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́