ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́—2004 | December 1
    • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

      Kí nìdí tí Jésù fi ní kí Tọ́másì fọwọ́ kan òun àmọ́ tí kò gba Màríà Magidalénì tó ti kọ́kọ́ fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ láyè?

      Ọ̀nà táwọn Bíbélì kan tọ́jọ́ wọn ti pẹ́ díẹ̀ gbà tú gbólóhùn yìí ló jẹ́ kò dà bíi pé ńṣe ni Jésù ń sọ fún Màríà Magidalénì pé kó má fọwọ́ kan òun rárá. Bí àpẹẹrẹ, bí Bibeli Mimọ ṣe tú ọ̀rọ̀ Jésù yìí rèé: “Máṣe fi ọwọ́ kàn mi; nitoriti emi kò ti igòke lọ sọdọ Baba mi.” (Jòhánù 20:17) Àmọ́ ohun tí ọ̀rọ̀ Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀ táwọn atúmọ̀ èdè máa ń tú sí “fọwọ́ kàn” lọ́pọ̀ ìgbà túmọ̀ sí ni “dì mọ́, rọ̀ mọ́, gbá mú, dì mú.” Èyí lè mú wa gbà pé kì í ṣe òun tí Jésù ń sọ fún Màríà Magidalénì ni pé kó má fọwọ́ kan òun, nítorí pé ó gba àwọn obìnrin míì tí wọ́n wà níbi ibojì rẹ̀ láyè láti “di ẹsẹ̀ rẹ̀ mú.”—Mát. 28:9.

      Ọ̀pọ̀ Bíbélì tí wọ́n fi èdè tó bóde mu túmọ̀, irú bí Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, The New Jerusalem Bible àti The New English Bible jẹ́ ká lóye ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Jésù yìí dáadáa. Ọ̀nà tí wọ́n gbà tú u nìyí: “Dẹ́kun dídìrọ̀ mọ́ mi.” Kí ló lè fà á tí Jésù fi sọ bẹ́ẹ̀ fún Màríà Magidalénì tó mọ̀ dáadáa?—Lúùkù 8:1-3.

      Láìsí àní-àní, ńṣe ni Màríà ń bẹ̀rù pé Jésù ti fẹ́ kúrò láyé tó sì fẹ́ gòkè re ọ̀run. Nítorí pé ó wu Màríà láti wà pẹ̀lú Olúwa rẹ̀ ló mú kó di Jésù mú, tí kò jẹ́ kó lọ. Kí Jésù lè fi dá Màríà lójú pé òun ò tíì lọ, Jésù sọ fún un pé kó má di òun mú, àmọ́ kó lọ sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn òun pé òun ti jíǹde.—Jòhánù 20:17.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́—2004 | December 1
    • Nítorí náà, ní ti Màríà Magidalénì, ohun tó mú kí Jésù sọ gbólóhùn yẹn fún un ni pé kò fẹ́ kí Jésù lọ, èrò yẹn ò sì tọ̀nà, àmọ́ ni ti Tọ́másì, ńṣe ni Jésù ń ràn án lọ́wọ́ nítorí pé ó ń ṣiyèméjì. Nínú ọ̀ràn méjèèjì, ohun tó yẹ kí Jésù ṣe gẹ́lẹ́ ló ṣe.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́