-
“Òun Ló Kọ́kọ́ Nífẹ̀ẹ́ Wa”Sún Mọ́ Jèhófà
-
-
Ìfẹ́ Tó Ga Jù Lọ Tí Jèhófà Fi Hàn
4. Báwo ni ọ̀gágun Róòmù kan ṣe rí i pé Jésù kì í ṣe èèyàn lásán, kí ló sì sọ lẹ́yìn náà?
4 Nígbà tí ọ̀gágun Róòmù tó bójú tó bí wọ́n ṣe pa Jésù rí i tí òkùnkùn ṣú, tí ilẹ̀ sì mì tìtì lọ́nà tó lágbára, ẹnu yà á gan-an. Ó wá sọ pé: “Ó dájú pé Ọmọ Ọlọ́run nìyí.” (Mátíù 27:54) Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn jẹ́ kí ọ̀gágun náà rí i pé Jésù kì í ṣe èèyàn lásán. Ó ṣeni láàánú pé ọkùnrin yìí ti bá wọn lọ́wọ́ sí bí wọ́n ṣe pa Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Ọlọ́run Gíga Jù Lọ! Àmọ́ o, báwo ni ìfẹ́ tó wà láàárín Ọmọ yẹn àti Bàbá ẹ̀ ṣe lágbára tó?
5. Báwo la ṣe lè ṣàpèjúwe iye ọdún tí Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ ti jọ wà?
5 Bíbélì pe Jésù ní “àkọ́bí nínú gbogbo ẹ̀dá.” (Kólósè 1:15) Èyí fi hàn pé Ọmọ Ọlọ́run ti wà kí ayé àtọ̀run tó wà. Báwo ni àkókò tí Ọmọ àti Bàbá ti jọ wà pa pọ̀ ṣe gùn tó? Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan fojú bù ú pé á ti tó bílíọ̀nù mẹ́tàlá ọdún tí ayé àtọ̀run ti wà. Ṣé o mọ bí ọdún yẹn ṣe gùn tó? Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe ohun kan káwọn èèyàn lè lóye iye ọdún tí wọ́n sọ pé ayé àtọ̀run ti wà. Wọ́n ṣe ilé ńlá kan tí wọ́n fi ṣàfihàn bí àgbáálá ayé yìí ṣe rí, wọ́n wá fa ìlà kan tó gùn tó àádọ́fà (110) mítà sínú ilé náà. Wọ́n sọ pé táwọn tó wá ṣèbẹ̀wò síbẹ̀ bá dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìlà náà, ẹsẹ̀ kan tí wọ́n bá gbé máa dúró fún nǹkan bíi mílíọ̀nù márùndínlọ́gọ́rin (75) ọdún. Lápá ìparí ìlà náà, wọ́n fa ìlà bíńtín kan tí kò gùn ju fọ́nrán irun kan ṣoṣo, wọ́n sì sọ pé ó dúró fún gbogbo iye ọdún téèyàn ti wà. Ìyẹn mà ga o! Àmọ́, ká tiẹ̀ sọ pé òótọ́ lohun táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ yìí, gbogbo ọdún yẹn ò tó nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ iye ọdún tí Ọmọ Ọlọ́run ti wà! Iṣẹ́ wo ló ń ṣe ní gbogbo àkókò yẹn?
6. (a) Iṣẹ́ wo ni Ọmọ Ọlọ́run ń ṣe lọ́run kó tó wá sí ayé? (b) Báwo ni ìfẹ́ tó wà láàárín Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ ṣe jinlẹ̀ tó?
6 Ńṣe ni Ọmọ Ọlọ́run ń ṣiṣẹ́ tayọ̀tayọ̀ pẹ̀lú Bàbá rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “àgbà òṣìṣẹ́.” (Òwe 8:30) Bíbélì sọ pé: “Láìsí [Ọmọ], kò sí nǹkan kan tó wà.” (Jòhánù 1:3) Ìyẹn fi hàn pé Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ ni wọ́n jọ ṣẹ̀dá gbogbo nǹkan tó kù. Ó dájú pé inú wọn máa dùn gan-an bí wọ́n ṣe ṣiṣẹ́ pa pọ̀! Gbogbo wa la mọ̀ pé ìfẹ́ tó máa ń wà láàárín òbí àtọmọ máa ń jinlẹ̀ gan-an. Ìfẹ́ sì jẹ́ “ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.” (Kólósè 3:14) Torí náà, ìfẹ́ tó wà láàárín Jèhófà àti Jésù jinlẹ̀ gan-an torí àìmọye ọdún ni wọ́n ti jọ wà pa pọ̀. Ká sòótọ́, kò sí ìfẹ́ tó lágbára tó ìfẹ́ àárín Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀.
7. Nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi, kí ni Jèhófà sọ tó fi hàn pé inú ẹ̀ dùn sí i?
7 Síbẹ̀, Jèhófà rán Ọmọ rẹ̀ wá sáyé, kí wọ́n lè bí i bí ọmọ ọwọ́ tó jẹ́ èèyàn. Ohun tíyẹn túmọ̀ sí ni pé ọ̀pọ̀ ọdún ni Jésù ò fi sí lọ́dọ̀ Jèhófà lọ́run, ó sì dájú pé àárò ọmọ ẹ̀ ọ̀wọ́n yìí máa sọ ọ́ gan-an. Gbogbo ìgbà ni Jèhófà ń wo Jésù látọ̀run, tó sì ń kíyè sí i bó ṣe ń dàgbà di ọkùnrin pípé. Nǹkan bí ẹni ọgbọ̀n ọdún ni Jésù nígbà tó ṣèrìbọmi. Ó dájú pé inú Jèhófà dùn sí Ọmọ rẹ̀ yìí gan-an. Kódà, Jèhófà fúnra rẹ̀ sọ̀rọ̀ látọ̀run pé: “Èyí ni Ọmọ mi, àyànfẹ́, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.” (Mátíù 3:17) Gbogbo nǹkan tí Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ pé Jésù máa ṣe ló ṣe, ohunkóhun tí Jèhófà bá sọ pé kó ṣe ló sì máa ń ṣe. Ó dájú pé Jésù múnú Jèhófà dùn gan-an!—Jòhánù 5:36; 17:4.
8, 9. (a) Àwọn nǹkan wo ni Jésù fara dà lọ́jọ́ kẹrìnlá, oṣù Nísàn, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, báwo ló sì ṣe rí lára Baba rẹ̀? (b) Kí nìdí tí Jèhófà fi jẹ́ kí Ọmọ rẹ̀ jìyà, kó sì kú?
8 Àmọ́, báwo lohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ kẹrìnlá, oṣù Nísàn, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ṣe rí lára Jèhófà? Báwo ló ṣe rí lára ẹ̀ nígbà tí wọ́n da Jésù, táwọn jàǹdùkú sì wá mú un lóru ọjọ́ yẹn? Ṣé o rò pé inú Jèhófà máa dùn nígbà táwọn ọ̀rẹ́ Jésù sá lọ, táwọn èèyàn sì mú un lọ síbi tí wọ́n ti gbọ́ ẹjọ́ ẹ̀ lọ́nà tí kò bófin mu? Báwo ló ṣe rí lára Jèhófà nígbà tí wọ́n ń fi Ọmọ ẹ̀ ṣẹ̀sín, tí wọ́n ń tutọ́ sí i lára, tí wọ́n sì ń gbá a lẹ́ṣẹ̀ẹ́? Báwo ló ṣe rí lára ẹ̀ nígbà tí wọ́n ń na Ọmọ ẹ̀ lẹ́gba, tí ẹgba náà sì dá egbò sí i lẹ́yìn yánnayànna? Báwo ló ṣe rí lára ẹ̀ nígbà tí wọ́n ń fi ìṣó kan ọwọ́ àtẹsẹ̀ Ọmọ rẹ̀ mọ́ òpó igi, táwọn èèyàn sì ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ bó ṣe wà lórí igi oró? Báwo ló ṣe rí lára Jèhófà nígbà tí Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n ń jẹ̀rora, tó sì ké jáde pé kí Bàbá òun ran òun lọ́wọ́? Báwo ló ṣe rí lára Jèhófà nígbà tí Jésù mí èémí ìkẹyìn, tó wá di pé fúngbà àkọ́kọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá, Ọmọ Rẹ̀ ọ̀wọ́n ṣaláìsí?—Mátíù 26:14-16, 46, 47, 56, 59, 67; 27:38-44, 46; Jòhánù 19:1.
9 A ò lè sọ bó ṣe rí lára Jèhófà nígbà tó ń wo ọmọ ẹ̀ báwọn èèyàn ṣe ń fìyà jẹ ẹ́, tí wọ́n sì pa á. Àmọ́, a mọ̀ pé ó ní láti ní ìdí pàtàkì kan tí Jèhófà fi gbà kí gbogbo nǹkan yẹn ṣẹlẹ̀ sí ọmọ ẹ̀. Kí nìdí tí Jèhófà fi ní láti fara da gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn? Jèhófà jẹ́ ká mọ ohun tó mú kóun fara dà á nínú Jòhánù 3:16. Ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe pàtàkì gan-an débi táwọn kan fi sọ pé òun ló ṣàkópọ̀ Ìwé Ìhìn Rere. Ẹsẹ náà sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé gan-an débi pé ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí gbogbo ẹni tó bá ń ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” Èyí fi hàn pé ìfẹ́ ló mú kí Jèhófà ṣe ohun tó ṣe yẹn. Ẹ̀bùn tó ṣeyebíye ni Jèhófà fún wa bó ṣe rán Ọmọ ẹ̀ wá sáyé, kó lè jìyà, kó sì kú nítorí wa. Èyí ni ìfẹ́ tó ga jù lọ!
“Ọlọ́run . . . fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni”
-
-
“Òun Ló Kọ́kọ́ Nífẹ̀ẹ́ Wa”Sún Mọ́ Jèhófà
-
-
12 Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà a·gaʹpe sábà máa ń túmọ̀ sí ìfẹ́ tá a gbé karí ìlànà. Torí náà, kì í ṣe ìfẹ́ tá a ní sẹ́nì kan torí bí ọ̀rọ̀ ẹni yẹn ṣe rí lára wa. Ńṣe la máa ń dìídì fi irú ìfẹ́ yìí hàn sí gbogbo èèyàn, torí a mọ̀ pé ohun tó tọ́ nìyẹn. Ohun tó mú kí ìfẹ́ yìí wúni lórí jù ni pé, ẹni tó bá ń fi irú ìfẹ́ yìí hàn kì í ro tara ẹ̀ nìkan. Bí àpẹẹrẹ, tún wo Jòhánù 3:16 lẹ́ẹ̀kan sí i. “Ayé” wo ni Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ débi pé ó fún un ní Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo? Ọ̀rọ̀ náà “ayé” ń tọ́ka sí gbogbo àwọn tó bá fẹ́ jàǹfààní ìràpadà Jésù. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn èèyàn yìí ló jẹ́ pé ìgbé ayé wọn ò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Ṣé ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ni ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn jẹ́ sí Jèhófà bíi ti Ábúráhámù olóòótọ́? (Jémíìsì 2:23) Rárá o, àmọ́ Jèhófà ń fìfẹ́ ṣoore fún gbogbo èèyàn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun ńlá ló ná an. Ó fẹ́ kí gbogbo èèyàn ronú pìwà dà, kí wọ́n sì yí pa dà. (2 Pétérù 3:9) Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti ṣe bẹ́ẹ̀. Ó sì ń fayọ̀ sọ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ di ọ̀rẹ́ rẹ̀.
-