-
Ìrètí Tí Ó Dájú fún Àwọn ÒkúNígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ́ Fẹ́ràn Bá Kú
-
-
Ìdáhùnpadà Jesu sí ikú Lasaru fi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́nkẹ́ hàn ní ìhà ọ̀dọ̀ Ọmọkùnrin Ọlọrun. Àwọn ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ tí ó ní ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ yìí fi ìfẹ́-ọkàn mímúná rẹ̀ láti jí àwọn òkú dìde hàn ní kedere. A kà pé: “Nígbà tí Maria sì dé ibi tí Jesu gbé wà, tí ó sì rí i, ó wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó wí fún un pé, Oluwa, ìbáṣepé ìwọ ti wà níhìn-ín, arákùnrin mi kì bá kú. Ǹjẹ́ nígbà tí Jesu rí i, tí ó sọkún, àti àwọn Ju tí ó bá a wá ń sọkún pẹ̀lú rẹ̀, ó kérora ní ọkàn rẹ̀, inú rẹ̀ sì bàjẹ́, Ó sì wí pé, Níbo ni ẹ̀yin gbé tẹ́ ẹ sí? Wọ́n sì wi fún un pé, Oluwa, wá wò ó. Jesu sọkún. Nítorí náà àwọn Ju wí pé, sáà wò ó bí ó ti fẹ́ràn rẹ̀ tó!”—Johannu 11:32-36.
Ìyọ́nú àtọkànwá tí Jesu ní ni a fihàn níhìn-ín nípasẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ mẹ́ta: “kérora,” “inú rẹ̀ sì bàjẹ́,” àti “sọkún.” Àwọn ọ̀rọ̀ èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí a lò ní ṣíṣàkọsílẹ̀ ìran arùmọ̀lára sókè yìí fihàn pé ikú Lasaru ọ̀rẹ́ rẹ̀ ọ̀wọ́n àti rírí arábìnrin Lasaru tí ń sọkún ba Jesu nínú jẹ́ púpọ̀ tí omije fi ń dà ni ojú Rẹ̀.a
Ohun tí ó jọni lójú ni pé ṣáájú àkókò yìí Jesu ti mú àwọn ẹni méjì mìíràn wá sí ìyè. Òun ni lọ́kàn dáadáa láti ṣe ohun kan náà fún Lasaru. (Johannu 11:11, 23, 25) Síbẹ̀, ó “sọkún.” Nígbà náà mímú ènìyàn padà wá sí ìyè kìí wulẹ̀ ṣe ọ̀nà ìgbàṣe kan lásán fún Jesu. Ìyọ́nú àti ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti fihàn ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ní kedere fi ìfẹ́-ọkàn mímúná rẹ̀ hàn láti mú òfò ikú kúrò.
Ìmọ̀lára oníjẹ̀lẹ́nkẹ́ Jesu nígbà tí ó ń jí Lasaru dìde fi ìfẹ́-ọkàn mímúná rẹ̀ hàn láti mú àwọn òfò ikú kúrò
-
-
Ìrètí Tí Ó Dájú fún Àwọn ÒkúNígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ́ Fẹ́ràn Bá Kú
-
-
a Ọ̀rọ̀ Griki náà tí a túmọ̀sí “kérora” wá láti inú ọ̀rọ̀ ìṣe náà (em·bri·maʹo·mai) tí o dúró fún láti nírora, tàbí banújẹ́ gidigidi. Ọ̀mọ̀wé kan nípa Bibeli ṣàkíyèsí pé: “Ohun tí ó lè túmọ̀sí níhìn-ín ni pé irú èrò-ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ bẹ́ẹ̀ mú Jesu tí ó fi jẹ́ pé ìkérora wá fúnraarẹ̀ láti ọkàn-àyà Rẹ̀.” Ọ̀rọ̀ náà tí a túmọ̀sí “inú rẹ̀ sì bàjẹ́” wá láti inú ọ̀rọ̀ Griki náà (ta·rasʹso) tí ó tọ́kasí ìrugùdù. Gẹ́gẹ́ bí olùṣe ìwé atúmọ̀ ọ̀rọ̀ kan ṣe sọ, ó túmọ̀sí “láti fa ìdàrúdàpọ̀ inú lọ́hùn-ún fún ẹnìkan, . . . kí ìroragógó tàbí ìbànújẹ́ nípalórí ẹni.” Ọ̀rọ̀ náà “sọkún” wá láti inú ọ̀rọ̀ ìṣe Griki náà (da·kryʹo) tí ó túmọ̀sí “láti da omije, láti sọkún sínú.”
-