ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Bójú Tó Àjàrà Yìí”!
    Ilé Ìṣọ́—2006 | June 15
    • Bí Jèhófà ṣe fi orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì wé àjàrà ni Jésù náà lo àjàrà láti fi ṣe àfiwé kan. Nígbà tí Jésù ń fi ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa lọ́lẹ̀, ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Èmi ni àjàrà tòótọ́, Baba mi sì ni aroko.” (Jòhánù 15:1) Jésù fi àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wé ẹ̀ka àjàrà yìí. Bí àwọn ẹ̀ka àjàrà gidi ṣe gbára lé igi àjàrà náà làwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣe gbọ́dọ̀ wà níṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀. Jésù ní: “Láìsí mi, ẹ kò lè ṣe nǹkan kan rárá.” (Jòhánù 15:5) Bí àwọn àgbẹ̀ ṣe máa ń gbin àjàrà tìtorí èso rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà ṣe ń retí pé káwọn èèyàn òun so èso nípa tẹ̀mí. Ìyẹn ni yóò múnú Ọlọ́run tó loko dùn, tí yóò sì gbé e ga.—Jòhánù 15:8.

  • “Bójú Tó Àjàrà Yìí”!
    Ilé Ìṣọ́—2006 | June 15
    • ‘Ẹ Máa Bá A Nìṣó Ní Síso Èso Púpọ̀’

      Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ló dúró fún àwọn ẹ̀ka ìṣàpẹẹrẹ tí “àjàrà tòótọ” ní. Síbẹ̀ “àwọn àgùntàn mìíràn” náà gbọ́dọ̀ rí i dájú pé àwọn náà jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Kristi tó ń mésò jáde. (Jòhánù 10:16) Ó ṣeé ṣe fáwọn náà láti “so èso púpọ̀” kí wọ́n sì máa gbé ògo Baba wọn ọ̀run ga. (Jòhánù 15:5, 8) Àpèjúwe àjàrà tóòtọ́ tí Jésù lò ń mú ká rántí pé ẹni tí yóò bá rí ìgbàlà ní láti wà níṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi kó sì máa so èso dáadáa nípa tẹ̀mí. Jésù sọ pé: “Bí ẹ bá pa àwọn àṣẹ mi mọ́, ẹ óò dúró nínú ìfẹ́ mi, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti pa àwọn àṣẹ Baba mọ́, tí mo sì dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀.”—Jòhánù 15:10.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́