ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ohun Tó Túmọ̀ Sí Láti Má Ṣe Dá Sí Ogun àti Ọ̀rọ̀ Òṣèlú
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
    • Ẹ̀kọ́ 45. Ọ̀dọ́bìnrin Kristẹni kan ò bá wọn kí àsíá, kò sì fọwọ́ sí àyà bíi tàwọn ọmọléèwé tó kù, àmọ́ ó dìde dúró tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ nígbà tí wọ́n ń ka ẹ̀jẹ́ orílẹ̀-èdè.

      Ẹ̀KỌ́ 45

      Ohun Tó Túmọ̀ Sí Láti Má Ṣe Dá Sí Ogun àti Ọ̀rọ̀ Òṣèlú

      Jésù sọ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ò gbọ́dọ̀ jẹ́ “apá kan ayé.” (Jòhánù 15:19) Lára ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé wọn ò gbọ́dọ̀ dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú àti ogun. Ká sòótọ́, kò rọrùn láti má ṣe dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú. Àwọn èèyàn lè máa fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé a ò dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú. Kí la lè ṣe tá ò fi ní máa dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú ká sì jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà Ọlọ́run?

      1. Èrò wo làwa Kristẹni tòótọ́ ní nípa ìjọba èèyàn?

      Àwa Kristẹni máa ń bọ̀wọ̀ fún ìjọba. A máa ń ṣègbọràn sí ohun tí Jésù sọ pé: “Ẹ san àwọn ohun ti Késárì pa dà fún Késárì.” Ọ̀nà tá à ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé a máa ń ṣègbọràn sí òfin orílẹ̀-èdè, irú bí òfin tó sọ pé ká máa san owó orí. (Máàkù 12:17) Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ló gba àwọn ìjọba èèyàn láyè láti máa ṣàkóso. (Róòmù 13:1) Torí náà, a mọ̀ pé ó níbi tí agbára wọn mọ. Ó sì dá wa lójú pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè yanjú gbogbo ìṣòro tó wà láyé.

      2. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a ò dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú?

      Bíi ti Jésù, a kì í dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú. Nígbà táwọn kan rí ọ̀kan lára iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe, wọ́n fẹ́ fi jọba, àmọ́ kò gbà fún wọn. (Jòhánù 6:15) Kí nìdí tí Jésù ò fi gbà? Ó sọ pé, “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí.” (Jòhánù 18:36) Torí pé ọmọlẹ́yìn Jésù ni wá, àwọn nǹkan kan wà tá a gbọ́dọ̀ yẹra fún ká lè fi hàn pé a ò dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú. Bí àpẹẹrẹ, a kì í lọ́wọ́ sí ogun. (Ka Míkà 4:3.) A máa ń bọ̀wọ̀ fún àwọn àmì orílẹ̀-èdè bí àsíá, àmọ́ a kì í júbà wọn. (1 Jòhánù 5:21) A kì í dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú kankan, bẹ́ẹ̀ la kì í ta kò wọ́n. Bákan náà, a kì í dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú láwọn ọ̀nà èyíkéyìí míì. Ńṣe ni èyí ń fi hàn pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan la fara mọ́.

      KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀

      Jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan tó lè fẹ́ mú ká dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú àtàwọn nǹkan tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣèpinnu táá múnú Jèhófà dùn.

      Ọkùnrin kan tí kò dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú. Kò fọkàn sí ìlérí táwọn olóṣèlú ń ṣe bí wọ́n ṣe ń bá àwọn alátìlẹyìn wọn sọ̀rọ̀ lọ́tùn-ún lósì.

      3. Àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú

      Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ fàpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún wa. Ka Róòmù 13:1, 5-7 àti 1 Pétérù 2:13, 14. Lẹ́yìn náà, wo FÍDÍÒ yìí kó o sì dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

      FÍDÍÒ: Àwọn Kristẹni Tòótọ́ Kì Í Dá Sí Ọ̀rọ̀ Òṣèlú​—Apá 1 (4:28)

      • Kí nìdí tó fi yẹ ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ?

      • Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi hàn pé a tẹrí ba fún wọn?

      Nígbà ogun, àwọn orílẹ̀-èdè kan máa ń sọ pé àwọn kì í dá sí ogun, àmọ́ wọ́n máa ń fi owó tàbí àwọn ohun ìjà ṣètìlẹyìn fáwọn tó ń jagun. Ṣé a lè sọ pé wọn ò dá sí ogun lóòótọ́? Kí ló túmọ̀ sí láti má ṣe dá sí ogun tàbí ọ̀rọ̀ òṣèlú? Ka Jòhánù 17:16. Lẹ́yìn náà, wo FÍDÍÒ yìí kó o sì dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

      FÍDÍÒ: Àwọn Kristẹni Tòótọ́ Kì Í Dá Sí Ọ̀rọ̀ Òṣèlú​—Apá 2 (3:11)

      • Kí ló túmọ̀ sí láti má ṣe dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú?

      Kí ló yẹ ká ṣe táwọn aláṣẹ bá sọ pé ká ṣe ohun tó ta ko òfin Ọlọ́run? Ka Ìṣe 5:28, 29. Lẹ́yìn náà, wo FÍDÍÒ yìí kó o sì dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

      FÍDÍÒ: Àwọn Kristẹni Tòótọ́ Kì Í Dá Sí Ọ̀rọ̀ Òṣèlú​—Apá 3 (1:18)

      • Tí ìjọba bá ní ká ṣe ohun tí Ọlọ́run ò fẹ́, ta ló yẹ ká ṣègbọràn sí?

      • Ṣé o lè sọ àwọn àpẹẹrẹ ohun tí ìjọba lè ní káwa Kristẹni ṣe àmọ́ tá ò ní ṣègbọràn sí wọn?

      4. Má ṣe dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú nínú èrò àti ìṣe rẹ

      Ka 1 Jòhánù 5:21. Lẹ́yìn náà, wo FÍDÍÒ yìí kó o sì dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

      FÍDÍÒ: Ìdí Tí Àwa Kristẹni Tòótọ́ Fi Nílò Ìgboyà​—Láti Má Ṣe Dá Sí Ọ̀rọ̀ Òṣèlú (2:49)

      • Kí nìdí tí Ayenge fi pinnu pé òun ò ní dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú, òun ò sì ní tẹrí ba fún àsíá orílẹ̀-èdè?

      • Ṣé o rò pé ìpinnu tó ṣe yẹn bọ́gbọ́n mu?

      Àwọn nǹkan míì wo ló lè ṣẹlẹ̀ tó lè fẹ́ mú ká dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú? Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

      FÍDÍÒ: Àwọn Ẹ̀kọ́ Látinú Ilé Ìṣọ́​—Má Ṣe Dá sí Ọ̀rọ̀ Òṣèlú Tàbí Ogun (5:16)

      • Tó bá dọ̀rọ̀ eré ìdárayá, kí la lè ṣe ká má bàa ṣohun tó fi hàn pé a ka orílẹ̀-èdè wa sí pàtàkì ju àwọn orílẹ̀-èdè míì lọ?

      • Kí la lè ṣe tá ò fi ní dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé ohun táwọn olóṣèlú fẹ́ ṣe máa pa wá lára tàbí ṣe wá láǹfààní?

      • Báwo ni ohun táwọn oníròyìn ń gbé jáde àtàwọn tá à ń bá kẹ́gbẹ́ ṣe lè mú ká dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú?

      Àwòrán: 1. Àwọn ará ìlú ń wọ́de, wọ́n gbé àwọn pátákó tí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ sí dání láti fi hàn pé inú ń bí wọn gan-an. 2. Ọkùnrin kan wà níbi tó ti ń wo eré ìdárayá, ó na àsíá orílẹ̀-èdè ẹ̀ sókè, ó sì ń ṣe kóríyá fáwọn olùkópa. 3. Ọmọléèwé kan ń ka ẹ̀jẹ́ orílẹ̀-èdè. 4. Ọmọ ogun kan gbé ìbọn dání. 5. Àwọn olóṣèlú méjì ń ṣe atótónu lórí ohun tí wọ́n máa ṣe fáwọn ará ìlú tí wọ́n bá dìbò fún wọn. 6. Obìnrin kan ń fi ìwé tó fi dìbò sínú àpótí ìdìbò.

      Kí làwọn nǹkan tí Kristẹni kan ò ní ṣe kó lè fi hàn pé òun ò dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú nínú èrò àti ìṣe rẹ̀?

      ẸNÌ KAN LÈ BÉÈRÈ PÉ: “Kí ló dé tẹ́ ò kì í tẹrí ba fún àsíá tàbí kẹ́ ẹ kọ orin orílẹ̀-èdè?”

      • Kí lo máa sọ?

      KÓKÓ PÀTÀKÌ

      Àwọn Kristẹni máa ń sapá gan-an kí wọ́n má bàa dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú nínú èrò, ọ̀rọ̀ àti ìṣe wọn.

      Kí lo rí kọ́?

      • Báwo ló ṣe yẹ ká máa ṣe sáwọn ìjọba èèyàn?

      • Kí nìdí táwa Kristẹni ò fi ń dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú?

      • Àwọn nǹkan wo ló lè ṣẹlẹ̀ tó lè fẹ́ mú ká dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú?

      Ohun tó yẹ kó o ṣe

      ṢÈWÁDÌÍ

      Àwọn nǹkan tí ò rọrùn wo ló lè gba pé ká ṣe tá ò bá fẹ́ dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú?

      Jèhófà Ò Fi Wá Sílẹ̀ Rárá (3:14)

      Kí ni ìdílé lè ṣe láti múra sílẹ̀ ṣáájú fún àwọn nǹkan tó lè mú kí wọ́n dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú?

      Jẹ́ Adúróṣinṣin sí Jèhófà Tó O Bá Wà Níbi Tí Wọ́n Ti Ń Kí Àsíá (4:25)

      Kí nìdí tó fi jẹ́ pé kéèyàn máa ṣe ohun táá gbé orílẹ̀-èdè ẹ̀ ga kọ́ lohun tó ṣe pàtàkì jù téèyàn lè ṣe?

      “Ohun Gbogbo Ṣeé Ṣe fún Ọlọ́run” (5:19)

      Ka ìwé yìí kó o lè mọ bí o ò ṣe ní jẹ́ “apá kan ayé” tó o bá fẹ́ pinnu irú iṣẹ́ tí wàá ṣe.

      “Olúkúlùkù Ni Yóò Ru Ẹrù Ti Ara Rẹ̀” (Ilé Ìṣọ́, March 15, 2006)

  • O Lè Jẹ́ Adúróṣinṣin sí Jèhófà Táwọn Èèyàn Bá Tiẹ̀ Ń Ta Kò Ẹ́
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
    • Bó pẹ́ bó yá, gbogbo àwa Kristẹni la máa kojú inúnibíni. Ṣé ó yẹ kíyẹn dẹ́rù bà wá?

      1. Kí nìdí táwọn èèyàn fi ń ṣenúnibíni sí wa?

      Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé: “Gbogbo àwọn tó bá fẹ́ fi ayé wọn sin Ọlọ́run tọkàntọkàn ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi Jésù ni wọ́n máa ṣe inúnibíni sí.” (2 Tímótì 3:12) Àwọn èèyàn ṣenúnibíni sí Jésù torí pé kì í ṣe apá kan ayé. Àwa náà ò kì í ṣe apá kan ayé, torí náà kò yà wá lẹ́nu pé àwọn ìjọba ayé yìí àtàwọn ẹlẹ́sìn ń ṣenúnibíni sí wa.​—Jòhánù 15:18, 19.

      2. Àwọn nǹkan wo la lè ṣe láti múra sílẹ̀ de inúnibíni?

      Àsìkò tá a wà yìí ló yẹ ká túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Rí i pé ò ń wáyè láti máa gbàdúrà sí Jèhófà déédéé, kó o sì máa ka Bíbélì lójoojúmọ́. Máa lọ sí ìpàdé ìjọ déédéé. Àwọn nǹkan yìí á fún ẹ lókun, á sì jẹ́ kó o nígboyà láti kojú inúnibíni tàbí àtakò èyíkéyìí, kódà tó bá jẹ́ pé ìdílé rẹ ló ń ta kò ẹ́. Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn èèyàn ṣenúnibíni sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ó sọ pé: “Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi; mi ò ní bẹ̀rù.”​—Hébérù 13:6.

      Bákan náà, a máa túbọ̀ jẹ́ onígboyà tá a bá ń wàásù déédéé. Torí ṣe ni iṣẹ́ ìwàásù máa ń jẹ́ ká túbọ̀ gbára lé Jèhófà, ìyẹn ò sì ní jẹ́ ká bẹ̀rù ẹnikẹ́ni. (Òwe 29:25) Tó o bá ti jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa fìgboyà wàásù báyìí, ó máa rọrùn fún ẹ láti máa wàásù táwọn ìjọba bá tiẹ̀ pàṣẹ pé a ò gbọ́dọ̀ wàásù.​—1 Tẹsalóníkà 2:2.

      3. Àwọn àǹfààní wo la máa rí tá a bá fara da inúnibíni?

      Ó dájú pé ara kì í tù wá tí wọ́n bá ń ṣenúnibíni sí wa, àmọ́ tá a bá fara da inúnibíni ìyẹn á jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára sí i. Ó máa ń jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, torí àá rí bó ṣe ń fún wa lókun láti máa fara dà á nígbà tó bá ṣe wá bíi pé a ò lókun mọ́. (Ka Jémíìsì 1:2-4.) Ó máa ń dun Jèhófà gan-an tá a bá ń jìyà, àmọ́ inú ẹ̀ máa ń dùn tó bá rí i pé a ò juwọ́ sílẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Tí ẹ bá fara da ìyà torí pé ẹ̀ ń ṣe rere, èyí dáa lójú Ọlọ́run.” (1 Pétérù 2:20) Tá a bá fara dà á dé òpin, Jèhófà máa fún wa láǹfààní láti wà ní ayé tuntun, níbi tí ẹnikẹ́ni ò ti ní máa ta ko ìjọsìn tòótọ́ mọ́, àá sì máa gbébẹ̀ títí láé.​—Mátíù 24:13.

      KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀

      Jẹ́ ká wo ohun tó jẹ́ ká mọ̀ pé a lè jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà táwọn èèyàn bá tiẹ̀ ń ṣenúnibíni sí wa, ká sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Jèhófà ṣe máa bù kún wa tá ò bá juwọ́ sílẹ̀.

      Bàbá àti ìyá obìnrin kan ń ta kò ó, síbẹ̀ obìnrin náà ń lọ síbi tó ti fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

      4. Fara dà á táwọn mọ̀lẹ́bí ẹ bá ń ta kò ẹ́

      Jésù mọ̀ pé inú àwọn kan nínú ìdílé wa lè má dùn sí wa tá a bá pinnu pé a máa sin Jèhófà. Ka Mátíù 10:34-​36, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

      • Kí ló ṣeé ṣe káwọn tó wà nínú ìdílé kan ṣe tẹ́nì kan nínú ìdílé náà bá pinnu láti sin Jèhófà?

      Kó o lè rí àpẹẹrẹ kan, wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

      FÍDÍÒ: Jèhófà Ò Fi Wá Sílẹ̀ (5:13)

      • Kí ni wàá ṣe tí mọ̀lẹ́bí tàbí ọ̀rẹ́ ẹ kan bá ní kó o má sin Jèhófà mọ́?

      Ka Sáàmù 27:10 àti Máàkù 10:29, 30. Lẹ́yìn tó o bá ka ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹsẹ Bíbélì náà, dáhùn ìbéèrè yìí:

      • Báwo làwọn ìlérí tó wà nínú ẹsẹ yìí ṣe lè fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀ táwọn mọ̀lẹ́bí tàbí ọ̀rẹ́ rẹ bá ń ta kò ẹ́?

      5. Má fi Jèhófà sílẹ̀ táwọn èèyàn bá tiẹ̀ ń ṣenúnibíni sí ẹ

      A nílò ìgboyà tá a bá fẹ́ máa sin Jèhófà nígbà táwọn èèyàn bá ń ta kò wá. Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

      FÍDÍÒ: Wọ́n Jẹ́ Onígboyà Báwọn Èèyàn Tiẹ̀ Ń Ṣenúnibíni Sí Wọn (6:27)

      • Kí lo rí nínú fídíò yẹn tó jẹ́ kó o mọ̀ pé ìwọ náà lè jẹ́ onígboyà?

      Ka Ìṣe 5:27-29 àti Hébérù 10:24, 25. Lẹ́yìn tó o bá ka ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹsẹ Bíbélì náà, dáhùn ìbéèrè yìí:

      • Kí nìdí tí kò fi yẹ ká pa ìjọsìn Jèhófà tì táwọn ìjọba bá tiẹ̀ sọ pé a ò gbọ́dọ̀ wàásù tàbí lọ sí ìpàdé mọ́?

      6. Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́

      Kárí ayé, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́mọdé àti lágbà jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà láìka ti pé àwọn èèyàn ń ṣenúnibíni sí wọn. Kó o lè rí ohun tó ràn wọ́n lọ́wọ́, wo FÍDÍÒ yìí. Lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

      FÍDÍÒ: Jèhófà Máa Fún Mi Lókun (3:40)

      • Nínú fídíò yẹn, kí ló ran àwọn arákùnrin àti arábìnrin yẹn lọ́wọ́ láti fara dà á?

      Ka Róòmù 8:35, 37-39 àti Fílípì 4:13. Lẹ́yìn tó o bá ka ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹsẹ Bíbélì náà, dáhùn ìbéèrè yìí:

      • Báwo ni ẹsẹ yìí ṣe jẹ́ kó dá ẹ lójú pé o lè fara da àdánwò èyíkéyìí?

      Ka Mátíù 5:10-12, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

      • Kí ló lè mú kó o máa láyọ̀ tó o bá tiẹ̀ ń kojú inúnibíni tàbí àtakò?

      Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin táwọn èèyàn ṣenúnibíni sí lóde òní, tí wọ́n sì fi sẹ́wọ̀n nítorí ìgbàgbọ́ wọn.

      Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ló ti fara da inúnibíni àti àtakò. Ìwọ náà lè fara dà á!

      ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Mi ò rò pé màá lè fara da inúnibíni.”

      • Ẹsẹ Bíbélì wo lo lè kà fún ẹni náà táá mú kó dá a lójú pé Jèhófà máa ràn án lọ́wọ́ kó lè fara da inúnibíni?

      KÓKÓ PÀTÀKÌ

      Jèhófà mọyì gbogbo ohun tá a bá ṣe ká lè máa sìn ín láìka ti pé àwọn èèyàn ń ta kò wá tàbí ṣenúnibíni sí wa. Ó máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè fara dà á dé òpin.

      Kí lo rí kọ́?

      • Kí nìdí táwọn èèyàn fi ń ṣenúnibíni sáwa Kristẹni?

      • Àwọn nǹkan wo lo lè máa ṣe láti múra sílẹ̀ de inúnibíni?

      • Kí ló lè mú kó dá ẹ lójú pé o ò ní pa ìjọsìn Jèhófà tì táwọn èèyàn bá tiẹ̀ ń ṣenúnibíni sí ẹ?

      Ohun tó yẹ kó o ṣe

      ṢÈWÁDÌÍ

      Wo fídíò yìí kó o lè mọ bí Jèhófà ṣe ran ọ̀dọ́kùnrin kan lọ́wọ́ kó lè fara dà á nígbà tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n torí pé ó kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun.

      Jèhófà Ràn Án Lọ́wọ́ Láti Fara Da Inúnibíni (2:34)

      Wo ohun tó ran tọkọtaya kan lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa fi tọkàntọkàn sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún láìka pé àwọn èèyàn ṣenúnibíni sí wọn.

      Bá A Ṣe Sin Jèhófà Láwọn Àkókò Tí Nǹkan Ò Dẹrùn (7:11)

      Ka ìwé yìí kó o lè mọ àwọn nǹkan tó o lè ṣe láti jẹ́ onígboyà tí wọ́n bá ń ṣenúnibíni sí ẹ.

      “Ìsinsìnyí Gan-An Ni Kó O Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Múra Sílẹ̀ fún Inúnibíni” (Ilé Ìṣọ́, July 2019)

      Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn tí ìdílé wa bá ń ṣenúnibíni sí wa, àwọn nǹkan wo la sì lè ṣe ká lè fara dà á láìfi Jèhófà sílẹ̀?

      “Idà Ni Òtítọ́ Ń Mú Wá, Kì Í Ṣe Àlàáfíà” (Ilé Ìṣọ́, October 2017)

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́