-
“New World Translation”—O Fi Ijinlẹ Ẹ̀kọ́ Hàn Kò Sì Fi Otitọ PamọIlé-Ìṣọ́nà—1991 | March 1
-
-
Ni Johanu 1:1 New World Translation kà pe: “Ọ̀rọ̀ naa jẹ ọlọrun kan.” Ninu ọpọlọpọ itumọ ọ̀rọ̀ yii wulẹ kà pe: “Ọ̀rọ̀ naa jẹ Ọlọrun” a sì ńlò ó lati ti ẹkọ igbagbọ Mẹtalọkan lẹhin. Ko jẹ iyalẹnu pe, awọn onigbagbọ Mẹtalọkan kò nifẹẹ si bi a ṣe tumọ rẹ̀ ninu New World Translation. Ṣugbọn Johanu 1:1 ni a kò fi èké yipada ki a baa lè fi ẹ̀rí han pe Jesu kii ṣe Ọlọrun Olodumare. Awọn Ẹlẹrii Jehofa, papọ pẹlu ọpọlọpọ awọn miiran, ti gbe ibeere dide si fifi lẹta gadagba bẹrẹ “ọlọrun” tipẹ ṣaaju ki New World Translation to jade, eyi ti o sapa lati tumọ èdè ipilẹṣẹ lọna pipeye. Awọn olutumọ Bibeli lede German marun-un bakan naa lo èdè ìsọ̀rọ̀ naa “ọlọrun kan” ninu ẹsẹ-iwe yii.b O keretan awọn mẹtala miiran ti lo awọn ọ̀rọ̀ bii “jẹ iru ti ọrun” tabi “iru ẹni bi Ọlọrun.” Awọn itumọ wọnyi baramu pẹlu awọn apa Bibeli miiran ti o fihan pe, bẹẹni, Jesu ni ọrun jẹ́ ọlọrun kan ni ero itumọ ti jijẹ ẹni ti ọrun. Ṣugbọn Jehofa ati Jesu kii ṣe olùwà kannaa, Ọlọrun kannaa.—Johanu 14:28; 20:17.
-
-
“New World Translation”—O Fi Ijinlẹ Ẹ̀kọ́ Hàn Kò Sì Fi Otitọ PamọIlé-Ìṣọ́nà—1991 | March 1
-
-
b Jürgen Becker, Jeremias Felbinger, Oskar Holtzmann, Friedrich Rittelmeyer, ati Siegfried Schulz. Emil Bock wipe, “olùwà bi Ọlọrun kan.” Tun wo itumọ Gẹẹsi naa: Today’s English Version, The New English Bible, Moffatt, Goodspeed pẹlu.
-