-
Báwo La Ṣe Lè Mọ Ìjọsìn Tí Ọlọ́run Tẹ́wọ́ Gbà?Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
-
-
1. Báwo la ṣe lè mọ ọ̀nà tí Ọlọ́run fẹ́ ká máa gbà jọ́sìn òun?
Inú Bíbélì la ti lè mọ ọ̀nà tí Ọlọ́run fẹ́ ká máa gbà jọ́sìn òun. Jésù sọ fún Ọlọ́run pé: “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” (Jòhánù 17:17) Àwọn ẹ̀sìn kan kì í kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ẹ̀kọ́ èèyàn àti àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ni wọ́n fi ń kọ́ni. Ó sì yẹ ká mọ̀ pé inú Jèhófà ò dùn sí àwọn tó “kọ àṣẹ Ọlọ́run sílẹ̀.” (Ka Máàkù 7:9.) Àmọ́, tá a bá ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì nínú ìjọsìn wa, tá a sì ń fi ìmọ̀ràn inú rẹ̀ sílò, inú Ọlọ́run á máa dùn sí wa.
-
-
Ṣé Kristẹni Tòótọ́ Làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
-
-
1. Orí kí ni ẹ̀kọ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà dá lé?
Jésù sọ pé: “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ [Ọlọ́run].” (Jòhánù 17:17) Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà gbà pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé bíi ti Jésù orí Bíbélì ni ẹ̀kọ́ wa dá lé. Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan nínú ìtàn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ní nǹkan bí ọdún 1870, àwùjọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan bẹ̀rẹ̀ sí í fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ohun tí Bíbélì sọ ni wọ́n gbà gbọ́, kódà tó bá tiẹ̀ yàtọ̀ sí ẹ̀kọ́ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì. Wọ́n sì máa ń kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí wọ́n kọ́ látinú Bíbélì.a
-