ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Nikodémù
    Ilé Ìṣọ́—2002 | February 1
    • Nǹkan bí oṣù mẹ́fà péré lẹ́yìn tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ni Nikodémù ti rí Jésù ‘gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.’ Iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ní Jerúsálẹ́mù nígbà Ìrékọjá ọdún 30 Sànmánì Tiwa wú Nikodémù lórí gan-an débi pé ó wá ní òru láti wá sọ fún Jésù pé òun gbà á gbọ́ àti láti wá túbọ̀ mọ̀ nípa olùkọ́ yìí. Nípa bẹ́ẹ̀, Jésù sọ ìjìnlẹ̀ òtítọ́ fún Nikodémù nípa ìdí tó fi pọn dandan láti ‘di àtúnbí’ kí a tó lè wọ Ìjọba Ọlọ́run. Àkókò yìí kan náà ni Jésù sọ ọ̀rọ̀ náà pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 3:1-16.

      Ẹ ò rí i pé ìrètí ńlá ló wà fún Nikodémù yìí! Ó láǹfààní láti bá Jésù kẹ́gbẹ́, kó sì fojú ara rẹ̀ rí onírúurú apá ìgbésí ayé Jésù lórí ilẹ̀ ayé. Gẹ́gẹ́ bí alákòóso àwọn Júù àti olùkọ́ kan ní Ísírẹ́lì, òye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yé Nikodémù dáadáa. Ó sì tún ní ìjìnlẹ̀ òye, bí a ṣe rí i nínú bó ṣe mọ̀ pé Jésù ni olùkọ́ tí ó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Nikodémù nífẹ̀ẹ́ sí àwọn nǹkan tẹ̀mí, ó sì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. Ẹ wo bó ṣe ní láti ṣòro tó fún mẹ́ńbà ilé ẹjọ́ gíga jù lọ ti àwọn Júù láti gbà pé ọmọ káfíńtà lásán-làsàn yìí wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run! Gbogbo irú àwọn ànímọ́ bẹ́ẹ̀ ló ṣe pàtàkì gan-an kéèyàn tó lè di ọmọ ẹ̀yìn Jésù.

  • Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Nikodémù
    Ilé Ìṣọ́—2002 | February 1
    • Lákọ̀ọ́kọ́ ná, Jòhánù sọ pé olùṣàkóso àwọn Júù yìí “wá sí ọ̀dọ̀ [Jésù] ní òru.” (Jòhánù 3:2) Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ kan sọ pé: “Wíwá tí Nikodémù wá lóru, kì í ṣe nítorí ìbẹ̀rù, bí kò ṣe láti yẹra fún ọ̀pọ̀ èèyàn tó lè máa ṣèdíwọ́ nígbà tó bá ń fọ̀rọ̀ wá Jésù lẹ́nu wò.” Àmọ́, Jòhánù tọ́ka sí Nikodémù gẹ́gẹ́ bí “ọkùnrin tí ó wá sọ́dọ̀ [Jésù] ní òru ní ìgbà àkọ́kọ́,” nínú àyíká ọ̀rọ̀ kan náà tó ti tọ́ka sí Jósẹ́fù ará Arimatíà gẹ́gẹ́ bí “ẹni tí ó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù, ṣùgbọ́n ọ̀kan tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀ nítorí ìbẹ̀rù rẹ̀ fún àwọn Júù.” (Jòhánù 19:38, 39) Nítorí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Nikodémù wá sọ́dọ̀ Jésù ní òru nítorí “ìbẹ̀rù àwọn Júù,” bí àwọn mìíràn nígbà ayé rẹ̀ ṣe máa ń bẹ̀rù níní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú Jésù.—Jòhánù 7:13.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́