-
Jèhófà Ni Olùrànlọ́wọ́ WaIlé Ìṣọ́—2004 | December 15
-
-
20, 21. Ipò wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wà nígbà táwọn ará tó wá láti Róòmù fún un lókun?
20 Èyí tó wúni lórí jù lọ ni àwọn àkọsílẹ̀ nípa bí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe sa gbogbo ipá wọn láti fún àwọn onígbàgbọ́ bíi tiwọn ní okun àti ìṣírí. Gbé àpẹẹrẹ kan tó kan àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù yẹ̀ wò. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń lọ sí Róòmù gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́wọ̀n, ó gba òpópónà àwọn ará Róòmù kan tí wọ́n ń pè ní Ọ̀nà Ápíà kọjá. Ibi tí wọ́n máa dé kẹ́yìn nínú ìrìn àjò náà ò dáa rárá, nítorí pé àwọn arìnrìn-àjò ní láti gba inú ẹrọ̀fọ̀ kọjá, ìyẹn ní àgbègbè kan tó jẹ́ pẹ̀tẹ́lẹ̀.a Àwọn ará ìjọ tó wà ní Róòmù mọ̀ pé Pọ́ọ̀lù ń bọ̀. Kí ni kí wọ́n ṣe? Ṣé kí wọ́n jókòó gẹlẹtẹ sínú ilé wọn títí dìgbà tí Pọ́ọ̀lù fi máa dé kí wọ́n sì lọ kí i nígbà tó bá dé ni?
21 Ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì, ìyẹn Lúùkù tó wà lára àwọn tó tẹ̀ lé Pọ́ọ̀lù nígbà ìrìn àjò náà sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún wa, ó ní: “Nígbà tí àwọn ará sì gbọ́ ìròyìn nípa wa, wọ́n wá láti ibẹ̀ [ìyẹn Róòmù] láti wá pàdé wa ní ibi tí ó jìnnà dé Ibi Ọjà Ápíọ́sì àti Ilé Èrò Mẹ́ta.” Ǹjẹ́ o lè fojú inú wo ohun tí wọ́n ṣe yìí? Bí wọ́n ṣe mọ̀ pé Pọ́ọ̀lù ń bọ̀, àwọn arákùnrin tí wọ́n yàn gbéra láti Róòmù lọ pàdé rẹ̀. Lára àwọn aṣojú náà dúró sí Ibi Ọjà Ápíọ́sì, tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí ibi táwọn arìnrìn-àjò ti máa ń dúró sinmi, ó sì wà ní nǹkan bí kìlómítà mẹ́rìnléláàádọ́rin sí Róòmù. Àwọn arákùnrin tó kù dúró sí Ilé Èrò Mẹ́ta, ìyẹn ibi tí wọ́n ti máa ń dúró sinmi, ó sì wà ní nǹkan bíi kìlómítà méjìdínlọ́gọ́ta sí ìlú. Kí ni Pọ́ọ̀lù ṣe nígbà tó rí wọn? Lúùkù ròyìn pé: “Bí Pọ́ọ̀lù sì ti tajú kán rí wọn, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì mọ́kànle.” (Ìṣe 28:15) Àbí ẹ ò rí nǹkan, rírí tí Pọ́ọ̀lù rí àwọn arákùnrin tí wọ́n ti sa gbogbo ipá wọn láti rin ìrìn tó jìn tó yẹn jẹ́ orísun okun àti ìtùnú fún un! Tá ni Pọ́ọ̀lù sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ nítorí gbogbo ìrànlọ́wọ́ táwọn ará ṣe yìí? Ó dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹni tó mú kó ṣeé ṣe, ìyẹn Jèhófà Ọlọ́run.
-
-
Jèhófà Ni Olùrànlọ́wọ́ WaIlé Ìṣọ́—2004 | December 15
-
-
a Akéwì ọmọ ilẹ̀ Róòmù nì tórúkọ rẹ̀ ń Horace (tó gbé ayé ní ọdún 65 sí 68 ṣáájú Sànmánì Tiwa), to sì rin ìrìn àjò kan náà yìí sọ̀rọ̀ nípa bí kò ṣe rọrùn tó láti gba apá ibi tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ yẹn. Horace ṣàpèjúwe ibi ọjà Ápíọ́sì gẹ́gẹ́ bí “ibi tí àwọn tó ń wakọ̀ ojú omi àtàwọn olùtọ́jú ilé èrò tí wọ́n láròró pọ̀ sí gan-an.” Ó tún ráhùn nípa “àwọn kòkòrò kantíkantí àtàwọn ọ̀pọ̀lọ́” tó wà níbẹ̀ àti omi ibẹ̀ “tí kò dára lẹ́nu rárá.”
-