ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àwọn Alàgbà Jẹ́ ‘Alábàáṣiṣẹ́pọ̀ Fún Ìdùnnú Wa’
    Ilé Ìṣọ́—2013 | January 15
    • 6, 7. (a) Ọ̀nà wo ni àwọn alàgbà lè gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, Pọ́ọ̀lù àti àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run mìíràn? (b) Kí nìdí tí inú àwọn ará fi máa ń dùn tá a bá rántí orúkọ wọn?

      6 Ọ̀pọ̀ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin sọ pé inú àwọn máa ń dùn táwọn bá rí i pé ọ̀rọ̀ àwọn jẹ àwọn alàgbà lógún. Àwọn alàgbà lè fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn ará jẹ àwọn lógún bí wọ́n bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Dáfídì, Élíhù àti Jésù. (Ka 2 Sámúẹ́lì 9:6; Jóòbù 33:1; Lúùkù 19:5.) Ohun tí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà yìí ṣe ni pé wọ́n máa ń fi orúkọ táwọn èèyàn ń jẹ́ pè wọ́n. Pọ́ọ̀lù náà sì rí i pé ó ṣe pàtàkì pé kí òun rántí orúkọ àwọn arákùnrin àti arábìnrin òun, kí òun sì máa fi orúkọ wọn pè wọ́n. Ní ìparí ọ̀kan lára àwọn lẹ́tà tó kọ, ó dárúkọ àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó ju mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] lọ. Ọ̀kan lára àwọn arábìnrin náà ni Pésísì. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ kí . . . Pésísì olùfẹ́ wa ọ̀wọ́n.”—Róòmù 16:3-15.

  • Àwọn Alàgbà Jẹ́ ‘Alábàáṣiṣẹ́pọ̀ Fún Ìdùnnú Wa’
    Ilé Ìṣọ́—2013 | January 15
    • 8. Ọ̀nà pàtàkì wo ni Pọ́ọ̀lù gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà àti Jésù?

      8 Pọ́ọ̀lù tún fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn jẹ òun lógún lọ́nà mìíràn. Ó máa ń gbóríyìn fún wọn. Ìyẹn sì tún jẹ́ ọ̀nà pàtàkì kan táwọn alàgbà fi lè mú kí àwọn ará máa fayọ̀ sin Ọlọ́run. Nígbà tó kọ lẹ́tà sí àwọn ará ní Kọ́ríńtì, ó sọ fún wọn pé: “Mo ní ìṣògo ńláǹlà nípa yín.” (2 Kọ́r. 7:4) Ó dájú pé ìwúrí lọ̀rọ̀ yìí máa jẹ́ fún àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì! Pọ́ọ̀lù tún gbóríyìn fún àwọn ìjọ míì nítorí iṣẹ́ rere wọn. (Róòmù 1:8; Fílí. 1:3-5; 1 Tẹs. 1:8) Kódà, lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù ti dárúkọ Pésísì tán nínú lẹ́tà tó kọ sí ìjọ tó wà ní Róòmù, ó sọ nípa rẹ̀ pé: “Ó ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ òpò nínú Olúwa.” (Róòmù 16:12) Ohun ìwúrí ni ọ̀rọ̀ yìí ti ní láti jẹ́ fún arábìnrin olùṣòtítọ́ yẹn! Ó ṣe kedere pé àpẹẹrẹ Jèhófà àti Jésù ni Pọ́ọ̀lù ń tẹ̀ lé bó ṣe ń gbóríyìn fún àwọn míì.—Ka Máàkù 1:9-11; Jòhánù 1:47; Ìṣí. 2:2, 13, 19.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́