-
“Ọgbọ́n Wà Pẹ̀lú Àwọn Amẹ̀tọ́mọ̀wà”Ilé Ìṣọ́—2000 | August 1
-
-
Pọ́ọ̀lù—“Òṣìṣẹ́ Ọmọ Abẹ́” àti “Ìríjú”
4. Kí ni àwọn àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ tí Pọ́ọ̀lù ní?
4 Ẹnì kan tó gbajúmọ̀ gan-an ni Pọ́ọ̀lù jẹ́ láàárín àwọn Kristẹni ìjímìjí, a sì mọ ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀. Nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó rin ẹgbẹẹgbẹ̀rún kìlómítà lójú òkun àti lórí ilẹ̀, ó sì dá ọ̀pọ̀ ìjọ sílẹ̀. Láfikún sí i, Jèhófà fi rírí àwọn ìran àti ẹ̀bùn fífi ahọ́n àjèjì sọ̀rọ̀ jíǹkí Pọ́ọ̀lù. (1 Kọ́ríńtì 14:18; 2 Kọ́ríńtì 12:1-5) Ó tún mí sí Pọ́ọ̀lù láti kọ mẹ́rìnlá lára àwọn ìwé tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì báyìí. Ní kedere, a lè sọ pé òpò tí Pọ́ọ̀lù ṣe pọ̀ ju ti gbogbo àwọn àpọ́sítélì yòókù lọ.—1 Kọ́ríńtì 15:10.
5. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé òun jẹ́ ẹni tó mẹ̀tọ́mọ̀wà?
5 Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù ló ń mú ipò iwájú nínú ìgbòkègbodò Kristẹni, àwọn kan lè máa retí àtirí i kó máa yan fanda kiri, kódà kó tiẹ̀ máa fi ọlá àṣẹ tó ní ṣe fọ́rífọ́rí pàápàá. Àmọ́, Pọ́ọ̀lù ò ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí pé ó mẹ̀tọ́mọ̀wà. Ó pe ara rẹ̀ ní ẹni tí ó “kéré jù lọ nínú àwọn àpọ́sítélì,” ó fi kún un pé: “Èmi kò sì yẹ ní ẹni tí a ń pè ní àpọ́sítélì, nítorí mo ṣe inúnibíni sí ìjọ Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 15:9) Gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ń ṣe inúnibíni sí àwọn Kristẹni tẹ́lẹ̀, Pọ́ọ̀lù ò lè gbàgbé láé pé tí kì í bá ṣe inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí ni, òun ì bá máà ní ìbátan kankan pẹ̀lú Ọlọ́run, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti bó ṣe gbádùn àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. (Jòhánù 6:44; Éfésù 2:8) Pẹ̀lú gbogbo ìyẹn, Pọ́ọ̀lù ò ronú pé àwọn ohun àrà ọ̀tọ̀ tí òun gbé ṣe nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà ti mú kí òun sàn ju àwọn yòókù lọ.—1 Kọ́ríńtì 9:16.
6. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi ìmẹ̀tọ́mọ̀wà hàn nínú bó ṣe bá àwọn ará Kọ́ríńtì lò?
6 Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà Pọ́ọ̀lù fara hàn kedere nínú bó ṣe bá àwọn ará Kọ́ríńtì lò. Ó hàn gbangba pé àwọn kan lára wọn ń kan sáárá sí àwọn alábòójútó tí wọ́n kà sí gbajúmọ̀ láàárín wọn, títí kan Àpólò, Kéfà, àti Pọ́ọ̀lù fúnra rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 1:11-15) Àmọ́ Pọ́ọ̀lù ò bẹ àwọn ará Kọ́ríńtì rí pé kí wọ́n gbóríyìn fún òun bẹ́ẹ̀ ni kò sí ohun tó fẹ́ fi ìkansáárá wọn ṣe. Nígbà tó bá ń bẹ̀ wọ́n wò, kì í wá “pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àsọrégèé tàbí ọgbọ́n.” Dípò ìyẹn, ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa ara rẹ̀ àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ni pé: “Kí ènìyàn díwọ̀n wa bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ ọmọ abẹ́ Kristi àti ìríjú àwọn àṣírí ọlọ́wọ̀ ti Ọlọ́run.”a—1 Kọ́ríńtì 2:1-5; 4:1.
7. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi ìmẹ̀tọ́mọ̀wà hàn, kódà nígbà tí ó ń fúnni ní ìmọ̀ràn?
7 Pọ́ọ̀lù tiẹ̀ fi ìmẹ̀tọ́mọ̀wà hàn nígbà tó yẹ kó fúnni ní ìbáwí líle koko àti ìtọ́ni. Ó “fi ìyọ́nú Ọlọ́run” pàrọwà sí àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, ó tún ṣe bẹ́ẹ̀ “nítorí ìfẹ́” kì í ṣe lọ́lá àṣẹ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì. (Róòmù 12:1, 2; Fílémónì 8, 9) Èé ṣe tí Pọ́ọ̀lù fi ṣe èyí? Nítorí pé ó ka ara rẹ̀ sí “alábàáṣiṣẹ́pọ̀” àwọn arákùnrin rẹ̀, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ‘ọ̀gá lórí ìgbàgbọ́ wọn.’ (2 Kọ́ríńtì 1:24) Láìsí àní-àní, ìmẹ̀tọ́mọ̀wà Pọ́ọ̀lù ló fà á tó fi jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n fún àwọn ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní.—Ìṣe 20:36-38.
-
-
“Ọgbọ́n Wà Pẹ̀lú Àwọn Amẹ̀tọ́mọ̀wà”Ilé Ìṣọ́—2000 | August 1
-
-
a Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tí a tú sí “òṣìṣẹ́ ọmọ abẹ” lè túmọ̀ sí ẹrú kan tí ó ń fi àjẹ̀ tukọ̀ lórí ìjókòó ìsàlẹ̀ nínú ọkọ̀ òkun ńlá kan. Ní ìyàtọ̀ sí ìyẹn, “ìríjú” lè jẹ́ ẹni tí a fi ọ̀pọ̀ ẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́, bíi pé kó máa bójú tó dúkìá kan. Síbẹ̀síbẹ̀, lójú ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọ̀gá, ìríjú ò yàtọ̀ sí ẹrú nínú ọkọ̀ òkun alájẹ̀.
-