-
Ẹ̀sìn Kristẹni Gbilẹ̀ Láàárín Àwọn Júù Ọ̀rúndún KìíníIlé Ìṣọ́—2005 | October 15
-
-
Ẹ̀sìn Kristẹni Gbilẹ̀ Láàárín Àwọn Júù Ọ̀rúndún Kìíní
ÌPÀDÉ pàtàkì kan wáyé ní Jerúsálẹ́mù ní nǹkan bí ọdún 49 Sànmánì Kristẹni. “Àwọn tí wọ́n dà bí ọwọ̀n” nínú ìjọ Kristẹni ti ọ̀rúndún kìíní, ìyẹn Jòhánù, Pétérù àti Jákọ́bù iyèkan Jésù wà nípàdé yẹn. Àwọn méjì tí Bíbélì tún sọ pé ó wà níbẹ̀ ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ìkejì rẹ̀. Ohun tí wọ́n ṣèpàdé lé lórí ni bí wọ́n ṣe máa pín ìpínlẹ̀ ńlá tí wọ́n ti ń wàásù. Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “[Wọ́n] fún èmi àti Bánábà ní ọwọ́ ọ̀tún ìṣàjọpín, pé kí a lọ sọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè, ṣùgbọ́n kí àwọn lọ sọ́dọ̀ àwọn tí ó dádọ̀dọ́.”—Gálátíà 2:1, 9.a
Báwo ló ṣe yẹ ká lóye ohun tí wọ́n fẹnu kò lé lórí? Ṣé bí wọ́n ṣe pín ìpínlẹ̀ ìwàásù ìhìn rere yìí ni pé kí àwọn kan máa wàásù fáwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe Júù kí àwọn mìíràn sì lọ máa wàásù fáwọn Kèfèrí? Àbí wọ́n kàn pín ìpínlẹ̀ ìwàásù yìí ní ẹlẹ́kùnjẹkùn láìfi tàwọn tó wà níbẹ̀ pín in ni? Ká tó mọ èyí tó lè jẹ́, ó yẹ ká kọ́kọ́ mọ̀ díẹ̀ nípa àwọn Júù tó wà lájò, ìyẹn àwọn Júù tí kò gbé nílẹ̀ Palẹ́sìnì.
Àwọn Ibi Táwọn Júù Wà Ní Ọ̀rúndún Kìíní
Àwọn Júù mélòó ló ń gbé láwọn ibi tí kì í ṣe ilẹ̀ Palẹ́sìnì ní ọ̀rúndún kìíní? Ó jọ pé ọ̀pọ̀ ọ̀mọ̀wé fara mọ́ ohun tí ìwé Atlas of the Jewish World sọ lórí kókó yìí. Ìwé náà sọ pé: “Ó ṣòro láti mọ iye gbogbo wọn pátápátá, ṣùgbọ́n wọ́n fojú bù ú pé kété ṣáájú ọdún 70 Sànmánì Kristẹni àwọn Júù tó wà ní Jùdíà tó mílíọ̀nù méjì àtààbọ̀ nígbà táwọn tó ń gbé láwọn ibi yòókù ní ilẹ̀ ọba Róòmùlé ní mílíọ̀nù mẹ́rin dáadáa. . . . Ó dà bíi pé tá a bá rí èèyàn mẹ́wàá nínú gbogbo èèyàn orílẹ̀-èdè tó wà lábẹ́ ilẹ̀ ọba Róòmù, ọ̀kan lára wọn á jẹ́ Júù. Àní láwọn ìlú àwọn ará ìlà oòrùn táwọn Júù pọ̀ sí jù lọ, ó dà bíi pé tá a bá fi máa rí èèyàn mẹ́rin, ọ̀kan lára wọn á jẹ́ Júù.”
Àwọn ilẹ̀ bíi Síríà, Éṣíà Kékeré, Babilónì àti Íjíbítì tí wọ́n wà lápá ìlà oòrùn làwọn Júù pọ̀ sí jù. Àwọn Júù tó wà láwọn ilẹ̀ wọ̀nyí pọ̀ ju àwọn tó wà ní ilẹ̀ Yúróòpù lọ. Ara àwọn Júù tó wà lájò yìí làwọn kan tó jẹ́ Kristẹni tó gbajúmọ̀ ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn bíi Bánábà láti Kípírọ́sì, Pírísíkà àti Ákúílà tó jẹ́ ọmọ bíbí Pọ́ńtù tó lọ gbé ní Róòmù, Ápólò láti Alẹkisáńdíríà àti Pọ́ọ̀lù láti ìlú Tásù.—Ìṣe 4:36; 18:2, 24; 22:3.
Àwọn Júù tó wà lájò ń lọ́wọ́ sí ohun tó ń lọ ní ìlú ìbílẹ̀ wọn ní Palẹ́sìnì dáadáa. Ọ̀nà kan tí wọ́n gbà ń ṣe èyí ni owó orí tí wọ́n fi ń ránṣẹ́ sí tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù lọ́dọọdún láti máa fi ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe ní tẹ́ńpìlì àti ìjọsìn tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀. Lórí kókó yìí, ọ̀mọ̀wé John Barclay sọ pé: “Ẹ̀rí fi hàn pé àwọn Júù tó wà lájò ò fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọ̀rọ̀ sísan owó orí yìí, kódà àwọn ọlọ́rọ̀ àárín wọn máa ń fi ọrẹ tó jọjú ránṣẹ́ pẹ̀lú.”
Ọ̀nà mìíràn táwọn Júù tún gbà ń lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ ìlú ìbílẹ̀ wọn ni ìrìn-àjò ẹ̀sìn tí wọ́n ń rìn wá sí Jerúsálẹ́mù lọ́dọọdún láti wá ṣe àjọyọ̀. A rí àpẹẹrẹ èyí látinú ìtàn tó wà nínú Ìṣe 2:9-11, ìyẹn ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. Nígbà yẹn, àwọn Júù rin ìrìn-àjò ẹ̀sìn wá láti ilẹ̀ Pátíà, Mídíà, Élámù, Mesopotámíà, Kapadókíà, Pọ́ńtù, Éṣíà, Fíríjíà, Panfílíà, Íjíbítì, Líbíà, Róòmù, Kírétè àti Arébíà.
Àwọn tó ń ṣe kòkárí ètò inú tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù máa ń kọ̀wé sáwọn Júù tó wà lájò. Ẹ̀rí sì fi hàn pé Gàmálíẹ́lì, olùkọ́ òfin tí ìwé Ìṣe 5:34 sọ̀rọ̀ rẹ̀, kọ lẹ́tà sí àwọn tó ń gbé ilẹ̀ Bábílónì àtàwọn ilẹ̀ mìíràn. Nígbà tí wọ́n mú Pọ́ọ̀lù lóǹdè dé Róòmù lọ́dún 59 Sànmánì Kristẹni, “àwọn tí wọ́n jẹ́ sàràkí-sàràkí . . . lára àwọn Júù” sọ fún un pé “àwa kò gba àwọn lẹ́tà nípa rẹ láti Jùdíà, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni lára àwọn ará tí ó ti dé kò ròyìn tàbí kí wọ́n sọ ohun burúkú kankan nípa rẹ.” Ohun tí èyí fi hàn ni pé wọ́n sábà máa ń fi lẹ́tà àti ìròyìn ránṣẹ́ láti Palẹ́sìnì sí Róòmù déédéé.—Ìṣe 28:17, 21.
Bíbélì Septuagint, ìyẹn Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí wọ́n túmọ̀ sí èdè Gíríìkì, làwọn Júù tó wà lájò ń lò. Ìwé kan sọ pé: “A ò jayò pa tá a bá sọ pé Bíbélì Septuagint làwọn Júù tó wà lájò ń kà, pé òun ni wọ́n gbà pé ó jẹ́ Bíbélì, tàbí ‘Ìwé Mímọ́,’ tiwọn.” Àwọn Kristẹni ìjímìjí lo Bíbélì yìí dáadáa nígbà tí wọ́n ń kọ́ni.
Gbogbo èyí làwọn Kristẹni tó wà nínú ìgbìmọ̀ olùdarí ní Jerúsálẹ́mù nígbà náà lọ́hùn-ún mọ̀. Ìhìn rere ṣáà ti dé ọ̀dọ̀ àwọn Júù tó wà lẹ́yìn odi nígbà náà, irú bíi Síríà àtàwọn ibi tó jìnnà jùyẹn lọ, títí kan Damásíkù àti Áńtíókù. (Ìṣe 9:19, 20; 11:19; 15:23, 41; Gálátíà 1:21) Láìsí àní-àní, ètò bí iṣẹ́ ìwàásù yóò ṣe máa lọ lọ́jọ́ iwájú làwọn tó wà nípàdé ọdún 49 Sànmánì Kristẹni yẹn ṣe. Ẹ jẹ́ ká wá wo ohun tí Bíbélì sọ nípa bí iṣẹ́ ìwàásù náà ṣe gbilẹ̀ láàárín àwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe Júù.
Bí Pọ́ọ̀lù Ṣe Rìnrìn Àjò Láti Wàásù Ìhìn Rere Fáwọn Júù Tó Wà Lájò
Iṣẹ́ tí Jésù gbé lé Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ níbẹ̀rẹ̀ ni pé kí ó “gbé orúkọ [Jésù Kristi] lọ sọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ọba àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”b (Ìṣe 9:15) Lẹ́yìn ìpàdé tí wọ́n ṣe ní Jerúsálẹ́mù, Pọ́ọ̀lù ń bá a lọ láti wá àwọn Júù tó wà lájò kàn ní gbogbo ibi tó bá dé láti lè wàásù fún wọn. (Wo àpótí tó wà lójú ìwé 14.) Èyí fi hàn pé ńṣe ni wọ́n pín ìpínlẹ̀ wọn ní ẹlẹ́kùnjẹkùn yálà àwọn Júù ló wà níbẹ̀ tàbí àwọn tí kì í ṣe Júù. Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ń bá iṣẹ́ míṣọ́nnárì wọn lọ lápá ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ ọba Róòmù, àwọn yòókù sì ń bójú tó àwọn Júù tó wà ní Palẹ́sìnì àti ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn Júù tó ń gbé ní ìlà oòrùn ayé.
-
-
Ẹ̀sìn Kristẹni Gbilẹ̀ Láàárín Àwọn Júù Ọ̀rúndún KìíníIlé Ìṣọ́—2005 | October 15
-
-
Ibòmíì táwọn Júù tún pọ̀ sí ni ilẹ̀ Bábílónì, títí lọ dé ilẹ̀ Pátíà, Mídíà àti Élámù. Òpìtàn kan sọ pé: “Kò síbi tá a máa dé ní gbogbo àgbègbè odò Tígírísì àti ti Yúfírétì, láti ilẹ̀ Àméníà títí dé ibi tí òkun ti ya wọ ilẹ̀ Páṣíà, àti láti apá àríwá Òkun Kásípíà títí lọ sí àgbègbè Mídíà lápá ìlà oòrùn, tá ò ní rí àwọn Júù.” Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Judaica sọ pé iye àwọn Júù tó wà níbẹ̀ tó ogójì ọ̀kẹ́ [800, 000] tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Òpìtàn kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Josephus tó gbé ayé ní ọ̀rúndún kìíní sọ pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Júù ló máa ń ti Bábílónì lọ sí Jerúsálẹ́mù láti lọ ṣe àwọn àjọyọ̀ ọdọọdún.
Ǹjẹ́ àwọn arìnrìn-àjò ẹ̀sìn kankan láti Bábílónì ṣèrìbọmi ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni? A ò mọ̀, àmọ́ àwọn ará Mesopotámíà wà lára àwọn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pétérù lọ́jọ́ náà. (Ìṣe 2:9) A mọ̀ dájú pé àpọ́sítélì Pétérù wà ní Bábílónì ní nǹkan bí ọdún 62 sí 64 Sànmánì Kristẹni. Ibẹ̀ ló wà nígbà tó kọ lẹ́tà rẹ̀ kìíní, ó sì lè jẹ́ pé ibẹ̀ ló ti kọ lẹ́tà rẹ̀ kejì pẹ̀lú. (1 Pétérù 5:13) Ó dájú pé Bábílónì táwọn Júù pọ̀ sí yìí wà lára ìpínlẹ̀ tí wọ́n pín fún Pétérù, Jòhánù àti Jákọ́bù nígbà ìpàdé tí Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn ará Gálátíà.
-
-
Ẹ̀sìn Kristẹni Gbilẹ̀ Láàárín Àwọn Júù Ọ̀rúndún KìíníIlé Ìṣọ́—2005 | October 15
-
-
a Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbà àpérò tí ìgbìmọ̀ olùdarí ti ọ̀rúndún kìíní ṣe lórí ọ̀ràn ìdádọ̀dọ́ ni wọ́n ṣèpàdé yìí tàbí kó jẹ́ pé àbájáde àpérò náà ló fa ìpàdé yìí.—Ìṣe 15:6-29.
-