ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ǹjẹ́ o Lè Fúnra Rẹ Pinnu Ọjọ́ Ọ̀la rẹ?
    Ilé Ìṣọ́—2005 | January 15
    • Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “[Ọlọ́run] ti fi gbogbo ìbùkún ti ẹ̀mí ní àwọn ibi ọ̀run bù kún wa ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti yàn wá ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ ṣáájú ìgbà pípilẹ̀ ayé. . . . Nítorí ó yàn wá ṣáájú sí ìsọdọmọ fún ara rẹ̀ nípasẹ̀ Jésù Kristi.” (Éfésù 1:3-5) Kí ni Ọlọ́run ti yàn ṣáájú, kí sì ni pé a ti yàn wọ́n “ṣáájú ìgbà pípilẹ̀ ayé” túmọ̀ sí?

  • Ǹjẹ́ o Lè Fúnra Rẹ Pinnu Ọjọ́ Ọ̀la rẹ?
    Ilé Ìṣọ́—2005 | January 15
    • Ayé wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “[Ọlọ́run] ti yàn wá ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ ṣáájú ìgbà pípilẹ̀ ayé?” Kì í ṣe ayé tó bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Ọlọ́run dá Ádámù àti Éfà ni Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ bá o. Ayé ìgbà yẹn “dára gan-an ni,” kò sí ẹ̀ṣẹ̀ níbẹ̀, kò sì sí ìyà rárá. (Jẹ́nẹ́sísì 1:31) Ayé ìgbà yẹn kò nílò “ìtúsílẹ̀” kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.—Éfésù 1:7.

      Ayé tí Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn ni ayé tó bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn nínú ọgbà Édẹ́nì. Ayé tó ní lọ́kàn yìí yàtọ̀ sí èyí tí Ọlọ́run ṣètò níbẹ̀rẹ̀. Ó jẹ́ ayé tó bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Ádámù àti Éfà bẹ̀rẹ̀ sí í bímọ, ìyẹn ayé àwọn èèyàn tó ti di àjèjì sí Ọlọ́run, tí wọ́n ti di ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ àti ìdíbàjẹ́. Ayé tá à ń wí yìí ni ayé àwọn èèyàn tó ṣeé rà padà nítorí pé wọn ò mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ bíi ti Ádámù àti Éfà tí kò ṣeé rà padà.—Róòmù 5:12; 8:18-21.

      Jèhófà Ọlọ́run lágbára láti ṣètò lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ bí yóò ṣe wá ojútùú sóhun tó máa jẹ́ àbájáde ọ̀tẹ̀ tó wáyé ní ọgbà Édẹ́nì. Nítorí náà, gbàrà tí ọ̀tẹ̀ yẹn ti wáyé ni Ọlọ́run ti ṣètò ìjọba kan, ìyẹn Ìjọba Mèsáyà tí Jésù Kristi yóò ṣàkóso rẹ̀. Ìjọba yẹn ni Ọlọ́run yóò lò láti mú kí aráyé bọ́ lọ́wọ́ àwọn àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù. (Mátíù 6:10) Ọlọ́run ti ṣètò ìjọba yìí “ṣáájú ìgbà pípilẹ̀ ayé” tó jẹ́ ti àwọn èèyàn tó ṣeé rà padà, ìyẹn ṣáájú kí Ádámù àti Éfà tó bẹ̀rẹ̀ sí í bímọ.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́