ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ Jẹ́ Ká Wà Lára Àwọn Tó Ní Ìgbàgbọ́
    Ilé Ìṣọ́—1999 | December 15
    • 16, 17. (a) Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe rí ìgboyà fún iṣẹ́ òjíṣẹ́? (b) Kí la lè ṣe báa bá rí i pé apá kan iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni wa ń fò wá láyà?

      16 Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tó wà ní Tẹsalóníkà pé: “Lẹ́yìn tí a ti kọ́kọ́ jìyà, tí a sì hùwà sí wa lọ́nà àfojúdi (gẹ́gẹ́ bí ẹ ti mọ̀) ní ìlú Fílípì, [a] ti máyàle nípasẹ̀ Ọlọ́run wa láti sọ ìhìn rere Ọlọ́run fún yín pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìjàkadì.” (1 Tẹsalóníkà 2:2) Báwo ni ‘wọ́n ṣe ṣàfojúdi sí’ Pọ́ọ̀lù àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ ní Fílípì? Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan ti sọ, ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tí Pọ́ọ̀lù lò túmọ̀ sí líláálí ẹni, dídójú tini, tàbí kíkanni lábùkù tó pọ̀. Àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Fílípì ní kí àwọn èèyàn nà wọ́n, wọ́n sọ wọ́n sẹ́wọ̀n, wọ́n sì dè wọ́n mọ́ inú àbà. (Ìṣe 16:16-24) Ipa wo ni ìrírí burúkú yẹn ní lórí Pọ́ọ̀lù? Ǹjẹ́ àwọn tó wà ní ìlú kejì tí Pọ́ọ̀lù fẹ́ bẹ̀ wò nígbà ìrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kejì, ìyẹn ni Tẹsalóníkà, rí i kó máa gbọ̀n jìnnìjìnnì? Rárá o, ńṣe ló “máyàle.” Ó borí ìbẹ̀rù, ó sì ń wàásù lọ láìṣojo.

      17 Ibo ni Pọ́ọ̀lù ti rí ìgboyà rẹ̀? Ṣé láti inú ara rẹ̀ ni? Rárá o, ó wí pé, òun máyàle “nípasẹ̀ Ọlọ́run wa.” Ìwé ìṣèwádìí kan tí àwọn olùtumọ̀ Bíbélì ń lò sọ pé a lè túmọ̀ gbólóhùn náà báyìí, “Ọlọ́run yọ ìbẹ̀rù kúrò lọ́kàn wa.” Nítorí náà, bó bá jẹ́ pé ẹ̀rù n bà ọ́ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ, tàbí tó jẹ́ pé apá kan nínú rẹ̀ ló ń fò ọ́ láyà, kí ló dé tóò bẹ Jèhófà kó ṣe ohun tó ṣe fún Pọ́ọ̀lù fún ọ? Bẹ̀ ẹ́ pé kó dákun, kó yọ ìbẹ̀rù náà kúrò lọ́kàn rẹ. Ní kó jọ̀ọ́, kó fún ọ lágbára àtimáyàle nínú iṣẹ́ náà. Ní àfikún sí i, gbé àwọn ìgbésẹ̀ mìíràn tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́. Fún àpẹẹrẹ, ṣètò láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ẹnì kan tó jẹ́ ògbóṣáṣá nínú apá ìjẹ́rìí tó jẹ́ ìṣòro rẹ. Ó lè jẹ́ àgbègbè iṣẹ́ ajé, ìjẹ́rìí òpópónà, ìjẹ́rìí àìjẹ́ bí àṣà, tàbí jíjẹ́rìí lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀. Ó ṣeé ṣe kí alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ kọ́kọ́ fẹ́ wàásù ní ilé àkọ́kọ́. Bó bá ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, fara balẹ̀ wo bó ṣe ń ṣe é, kí o sì kẹ́kọ̀ọ́ lára rẹ̀. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìyẹn, máyàle láti gbìyànjú rẹ̀ wò.

      18. Àwọn ìbùkún wo la lè rí gbà báa bá máyàle nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?

      18 Bóo bá máyàle, wá máa wo ohun tó máa ṣẹlẹ̀. Bóo bá ń bá a lọ, tí o kò rẹ̀wẹ̀sì, o lè ní ìrírí tó fani mọ́ra nínú ṣíṣàjọpín òtítọ́, ìyẹn ni àwọn ìrírí tí ì bá má ṣeé ṣe fún ọ láti ní. (Wo ojú ìwé 25.) Ọkàn rẹ yóò balẹ̀ pé o ti mú inú Jèhófà dùn nípa ṣíṣe ohun tó ṣòro fún ọ. Wàá wá rí ìbùkún àti ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ tóo lè lò láti borí ìbẹ̀rù rẹ. Ìgbàgbọ́ rẹ yóò lágbára sí i. Lóòótọ́, o kò lè mú kí ìgbàgbọ́ àwọn ẹlòmíràn lágbára sí i láìjẹ́ pé ìwọ náà sọ ìgbàgbọ́ tìrẹ di alágbára.—Júúdà 20, 21.

  • Wọ́n Máyàle
    Ilé Ìṣọ́—1999 | December 15
    • Wọ́n Máyàle

      KÌÍ sábà rọrùn láti máyàle kí a lè wàásù. Lóòótọ́, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé òun ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà kan, àmọ́ “pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìjàkadì” ni òun fi ṣe é. (1 Tẹsalóníkà 2:2) Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ yẹ ká ‘jìjàkadì’ nítorí àtiwàásù? Kò sí ìdánilójú kankan pé ohun bàbàrà kan yóò ṣẹlẹ̀ báa bá ṣe bẹ́ẹ̀, àmọ́ inú àwọn ènìyàn Ọlọ́run máa ń dùn nígbà gbogbo pé àwọn máyàle. Gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.

      Tara, ọmọbìnrin tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ nígbà tí olùkọ́ rẹ̀ ń sọ fún wọn nínú kíláàsì pé nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó wà nínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tí wọ́n kó àwọn Júù sí ní láti lẹ Ìràwọ̀ Dáfídì tó ní àwọ̀ ìyeyè mọ́ ẹ̀wù wọn, káwọn èèyàn lè dá wọn mọ̀. Ẹ̀rù àtisọ̀rọ̀ ń ba Tara. Ó rántí pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ń kò dijú, mò ń fọkàn gbàdúrà lọ.” Lẹ́yìn náà, ó nawọ́ sókè, ó sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà wà nínú àwọn àgọ́ yẹn, àmì onígun mẹ́ta aláwọ̀ àlùkò wà lára ẹ̀wù tiwọn pẹ̀lú. Inú tíṣà náà dùn, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ ọmọbìnrin yìí. Ohun tí Tara sọ yìí ló jẹ́ kí àǹfààní ṣí sílẹ̀ fún un láti tú kẹ̀kẹ́ ọ̀rọ̀ sílẹ̀ fún tíṣà wọn, débi pé ó ní láti fi fídíò Jehovah’s Witnesses Stand Firm Against Nazi Assault, han gbogbo kíláàsì wọn.

      Ní Guinea, ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà, ọmọbìnrin kan tí kò tíì ṣèrìbọmi tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Irène fẹ́ tẹ̀ síwájú nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Míṣọ́nnárì tó kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rọ̀ ọ́ pé kó gbìyànjú fi ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọ àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ nílé ìwé. Àmọ́ Irène ń lọ́ tìkọ̀ nítorí pé àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kì í fẹ́ gbọ́. Ṣùgbọ́n, nítorí pé ìṣírí tí míṣọ́nnárì yẹn fún un wọ̀ ọ́ lọ́kàn, Irène pinnu láti kọ́kọ́ kàn sí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tó dà bí ẹni pé òun ló máa ń ta kò ó jù lọ. Ó ya Irène lẹ́nu pé, ọmọbìnrin náà fara balẹ̀, ó sì gba ìwé ìròyìn náà. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mìíràn bíi tirẹ̀ tún ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. Táa bá ṣírò iye ìwé ìròyìn tí Irene fi síta ní oṣù márùn-⁠ún tó ṣáájú papọ̀, kò tó èyí tó fi síta ní oṣù yẹn nìkan ṣoṣo.

      Ní Trinidad, alàgbà kan ń lọ́ra láti bá ọ̀gá àgbà ilé ẹ̀kọ́ sọ̀rọ̀ kí ó bàa lè mọyì ẹ̀kọ́ tó wà nínú ìwé ìròyìn Jí! Síbẹ̀síbẹ̀, ó máyàle. Ó wí pé: “Bí mo ṣe ń wọnú ọgbà ilé ìwé náà lọ ni mo gbàdúrà. Ó yà mí lẹ́nu nígbà tí ọ̀gá àgbà náà fọ̀yàyà tẹ́wọ́ gbà mí.” Obìnrin yìí gba ìwé ìròyìn Jí! tó sọ̀rọ̀ lórí “Ìrètí Tó Wà fún Àwọn Ọ̀dọ́ Òde Òní?” ó tilẹ̀ gbà láti máa fi kọ́ àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀. Lẹ́nu ìgbà náà síhìn-⁠ín, ó ti gba ogójì ìwé ìròyìn tó sọ̀rọ̀ lórí onírúurú kókó.

      Gẹ́gẹ́ bí èwe, ìwàásù máa ń nira fún Vaughn nígbà gbogbo. “Ńṣe ni gbogbo ara mi a máa gbọ̀n, ti màá máa làágùn ní àtẹ́lẹwọ́, tí màá sì máa yára sọ̀rọ̀—n kò ní lè rọra sọ̀rọ̀.” Síbẹ̀, ó di òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Àmọ́, kò tíì rọrùn fún un síbẹ̀ láti fìgboyà sọ̀rọ̀. Lọ́jọ́ kan, lẹ́yìn tó ti wáṣẹ́-wáṣẹ́, tí kò rí, ó fẹ́ jẹ́rìí fún ẹnì kan nínú ọkọ̀ rélùwéè, “kó ṣáà lè rí i pé òun ṣe ohun kan tó ní láárí lọ́jọ́ burúkú yẹn.” Àmọ́ ẹ̀mí rẹ̀ ò gbé e láti bá àwọn ọkùnrin oníṣòwò tí ìmúra wọn fi hàn pé èèyàn pàtàkì ni wọ́n, tí wọ́n wà nínú ọkọ̀ rélùwéè abẹ́lẹ̀ náà, sọ̀rọ̀. Níkẹyìn, ó máyàle láti bá baba àgbàlagbà kan tó jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀. Ni wọ́n bá sọ̀rọ̀. Oníṣòwò náà dáhùn pé: “Bóo ṣe kéré tó yìí, àwọn ìbéèrè tó dáa mà wà nínú ọpọlọ rẹ o, ṣé ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ni ẹ́ ni?” Vaughn fèsì pé: “Rárá o, Ẹlẹ́rìí Jèhófà lèmi.” Ọkùnrin náà rẹ́rìn-⁠ín músẹ́, ó ní: “Mo sọ bẹ́ẹ̀ náà, ó ṣẹ̀ẹ̀ wá yé mi ni wàyí.”

      Gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí wọ̀nyí—àti àìmọye àwọn mìíràn—ni inú wọn ń dùn bí wọ́n ti ń máyàle láti wàásù. Ṣé wàá ṣe bíi tiwọn?

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́