ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Máàkù ‘Wúlò fún Iṣẹ́ Ìránṣẹ́’
    Ilé Ìṣọ́—2010 | March 15
    • Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń ṣẹ̀wọ̀n ẹlẹ́ẹ̀kejì ní ìlú Róòmù ní nǹkan bí ọdún 65 Sànmánì Kristẹni, ó kọ̀wé sí Tímótì tó wà ní Éfésù pé kó wá, ó sì fi kún un pé: “Mú Máàkù, kí o sì mú un wá pẹ̀lú rẹ.” (2 Tím. 4:11) Èyí fi hàn pé Éfésù ni Máàkù wà nígbà yẹn. Kò sì sí iyè méjì pé Máàkù bá Tímótì lọ sí ìlú Róòmù gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ. Kò rọrùn láti rìnrìn àjò nígbà yẹn, àmọ́ Máàkù fínnú fíndọ̀ rin àwọn ìrìn àjò náà.

  • Máàkù ‘Wúlò fún Iṣẹ́ Ìránṣẹ́’
    Ilé Ìṣọ́—2010 | March 15
    • “Ó Wúlò fún Mi fún Iṣẹ́ Ìránṣẹ́”

      Máàkù ṣe ohun mìíràn ní ìlú Róòmù yàtọ̀ sí ìwé Ìhìn Rere tó kọ níbẹ̀. Má ṣe gbàgbé pé Pọ́ọ̀lù ní kí Tímótì, “mú Máàkù, kí o sì mú un wá pẹ̀lú [rẹ̀].” Kí nìdí? Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nítorí ó wúlò fún mi fún iṣẹ́ ìránṣẹ́.”—2 Tím. 4:11.

      Bá a bá fojú ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa Máàkù wò ó, ibí yìí ló ti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ kẹ́yìn, ohun tó sì sọ jẹ́ ká mọ púpọ̀ sí i nípa Máàkù. Kò sígbà kankan nínú ìtàn iṣẹ́ òjíṣẹ́ Máàkù tí wọ́n ti tọ́ka sí i gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì, aṣáájú tàbí wòlíì. Òjíṣẹ́ ni, ìyẹn ẹni tó máa ń jíṣẹ́ tó sì máa ń sin àwọn míì. Níbi tọ́rọ̀ sì dé yìí, gẹ́rẹ́ ṣáájú kí Pọ́ọ̀lù tó kú, ó jàǹfààní látinú ìrànlọ́wọ́ tí Máàkù ṣe fún un.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́