-
Àwọn Alábòójútó Tó Ń Ṣe Olùṣọ́ Àgùntàn AgboA Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
-
-
11 Àwọn ọkùnrin tó kúnjú ìwọ̀n láti di alábòójútó kì í ṣe àṣejù nínú ìwà àti nínú àjọṣe wọn pẹ̀lú àwọn èèyàn. Wọ́n máa ń wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Bí wọ́n ṣe ń gbé ìgbésí ayé wọn fi hàn pé wọn kì í kọjá ààyè wọn, wọ́n sì ń kó ara wọn níjàánu. Yálà wọ́n ń jẹ tàbí wọ́n ń mu, wọ́n ń ṣeré ìtura tàbí wọ́n ń ṣeré ìnàjú, wọ́n kì í ṣàṣejù. Wọn kì í ṣe àṣejù nídìí ọtí kí wọ́n má bàa di ẹni tá a fẹ̀sùn kàn pé ó jẹ́ ọ̀mùtí. Ẹni tí ọtí ti pa níyè kò ní lè kó ara rẹ̀ níjàánu, kò sì ní lè bójú tó àwọn nǹkan tó máa gbé ìgbàgbọ́ àwọn ará ìjọ ró.
-
-
Àwọn Alábòójútó Tó Ń Ṣe Olùṣọ́ Àgùntàn AgboA Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
-
-
13 Alábòójútó gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tó máa ń fòye báni lò. Ó gbọ́dọ̀ mọ béèyàn ṣe ń ṣiṣẹ́ níṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn alàgbà yòókù, kó sì máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn. Kò gbọ́dọ̀ jọ ara rẹ̀ lójú, kò sì gbọ́dọ̀ máa retí pé kí àwọn èèyàn ṣe kọjá agbára wọn. Torí pé alábòójútó jẹ́ afòyebánilò, kì í rin kinkin mọ́ èrò tara rẹ̀, kó máa rò pé èrò tòun ló dáa ju tàwọn alàgbà yòókù lọ. Àwọn míì lè ní àwọn ànímọ́ tí kò ní tàbí kí wọ́n lè ṣe àwọn nǹkan tí kò lè ṣe. Alàgbà kan máa fi hàn pé òun jẹ́ afòyebánilò tó bá ń ṣe àwọn ìpinnu tó bá Ìwé Mímọ́ mu tó sì ń sapá láti máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù Kristi. (Fílí. 2:2-8) Kò yẹ kí alàgbà jẹ́ oníjà tàbí oníwà ipá, ó gbọ́dọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún àwọn èèyàn, kó sì gbà pé àwọn míì sàn ju òun lọ. Kò gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tó ń ṣe tinú ara rẹ̀, tó ń fi dandan lé e pé káwọn èèyàn gba èrò òun tàbí kí wọ́n ṣe nǹkan lọ́nà tí òun ń gbà ṣe é. Kì í ṣe ẹni tó máa ń tètè bínú ṣùgbọ́n ó máa ń wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn.
-