-
Àwọn Alábòójútó Tó Ń Ṣe Olùṣọ́ Àgùntàn AgboA Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
-
-
11 Àwọn ọkùnrin tó kúnjú ìwọ̀n láti di alábòójútó kì í ṣe àṣejù nínú ìwà àti nínú àjọṣe wọn pẹ̀lú àwọn èèyàn. Wọ́n máa ń wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Bí wọ́n ṣe ń gbé ìgbésí ayé wọn fi hàn pé wọn kì í kọjá ààyè wọn, wọ́n sì ń kó ara wọn níjàánu. Yálà wọ́n ń jẹ tàbí wọ́n ń mu, wọ́n ń ṣeré ìtura tàbí wọ́n ń ṣeré ìnàjú, wọ́n kì í ṣàṣejù. Wọn kì í ṣe àṣejù nídìí ọtí kí wọ́n má bàa di ẹni tá a fẹ̀sùn kàn pé ó jẹ́ ọ̀mùtí. Ẹni tí ọtí ti pa níyè kò ní lè kó ara rẹ̀ níjàánu, kò sì ní lè bójú tó àwọn nǹkan tó máa gbé ìgbàgbọ́ àwọn ará ìjọ ró.
-
-
Àwọn Alábòójútó Tó Ń Ṣe Olùṣọ́ Àgùntàn AgboA Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
-
-
14 Bákan náà, ẹni tó kúnjú ìwọ̀n láti di alábòójútó nínú ìjọ gbọ́dọ̀ ní àròjinlẹ̀. Èyí túmọ̀ sí pé ó jẹ́ onílàákàyè, tí kì í kánjú ṣe ìpinnu. Ó lóye àwọn ìlànà Jèhófà dáadáa ó sì mọ bó ṣe lè lò wọ́n. Ẹni tó bá ń ronú jinlẹ̀ máa ń gba ìmọ̀ràn àti ìtọ́sọ́nà. Kì í ṣe alágàbàgebè.
-
-
Àwọn Alábòójútó Tó Ń Ṣe Olùṣọ́ Àgùntàn AgboA Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
-
-
15 Pọ́ọ̀lù rán Títù létí pé alábòójútó ní láti jẹ́ ẹni tó nífẹ̀ẹ́ ohun rere. Ó gbọ́dọ̀ jẹ́ olódodo àti olóòótọ́. Àwọn ànímọ́ yìí máa hàn tí nǹkan bá da òun àtàwọn ẹlòmíì pọ̀ àti nínú ọwọ́ tó fi ń mú ohun tó tọ́ àti ohun rere. Ó ń sin Jèhófà láìyẹsẹ̀, ó sì ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà òdodo nínú gbogbo ohun tó bá ń ṣe. Ó máa ń pa ọ̀rọ̀ àṣírí mọ́. Ó tún máa ń ṣe aájò àlejò tinútinú, ó máa ń yọ̀ǹda ara rẹ̀ àtàwọn nǹkan ìní rẹ̀ fún àwọn èèyàn.—Ìṣe 20:33-35.
-