-
Irú Ẹ̀mí Wo Lò Ń fi Hàn?Ilé Ìṣọ́—2012 | October 15
-
-
“Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jésù Kristi Olúwa wà pẹ̀lú ẹ̀mí tí ẹ fi hàn.”—FÍLÉM. 25.
-
-
Irú Ẹ̀mí Wo Lò Ń fi Hàn?Ilé Ìṣọ́—2012 | October 15
-
-
1. Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ léraléra nígbà tó ń kọ̀wé sí àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́?
NÍGBÀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń kọ lẹ́tà sí àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́, ó sọ léraléra pé òun ní ìrètí pé Ọlọ́run àti Kristi máa bù kún ẹ̀mí táwọn ìjọ náà fi hàn. Bí àpẹẹrẹ, ó kọ̀wé sáwọn ará ní ìlú Gálátíà pé: “Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Olúwa wa Jésù Kristi wà pẹ̀lú ẹ̀mí tí ẹ ń fi hàn, ẹ̀yin ará. Àmín.” (Gál. 6:18) Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn pẹ̀lú gbólóhùn náà, “ẹ̀mí tí ẹ ń fi hàn”?
2, 3. (a) Kí ni Pọ́ọ̀lù máa ń ní lọ́kàn nígbà míì tó bá lo ọ̀rọ̀ náà “ẹ̀mí”? (b) Àwọn ìbéèrè wo la lè bi ara wa nípa irú ẹ̀mí tí à ń fi hàn?
2 Nínú ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù yìí, ohun tí “ẹ̀mí” túmọ̀ sí ni ohun tó ń mú ká máa sọ̀rọ̀ tàbí ṣe nǹkan lọ́nà pàtó kan. Èèyàn kan lè jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́, agbatẹnirò, onínú tútù, ọ̀làwọ́, tàbí ẹni tó lẹ́mìí ìdáríjì. Bíbélì sọ̀rọ̀ dáadáa nípa ẹni tó ní “ẹ̀mí ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ àti ti ìwà tútù” àti ẹni tó “tutù ní ẹ̀mí.” (1 Pét. 3:4; Òwe 17:27) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ẹlòmíì lè jẹ́ apẹ̀gàn, olùfẹ́ ọrọ̀, onínúfùfù tàbí aṣetinú-ẹni. Àwọn míì sì wà tí wọ́n ní ẹ̀mí tó ń mú kí wọ́n máa ro èròkérò, kí wọ́n máa ṣàìgbọràn, tàbí kí wọ́n tiẹ̀ máa ṣọ̀tẹ̀.
3 Nípa bẹ́ẹ̀, láwọn ìgbà tí Pọ́ọ̀lù bá lo àwọn gbólóhùn bíi “kí Olúwa wà pẹ̀lú ẹ̀mí tí o fi hàn,” ńṣe ló ń fún àwọn arákùnrin rẹ̀ níṣìírí láti fi ẹ̀mí tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run àti ìwà Kristi mu hàn. (2 Tím. 4:22; ka Kólósè 3:9-12.) Lóde òní, ó dára ká bi ara wa pé: ‘Irú ẹ̀mí wo ni mò ń fi hàn? Báwo ni ẹ̀mí tí mò ń fi hàn ṣe lè túbọ̀ máa múnú Ọlọ́run dùn? Kí ni mo lè ṣe láti mú kí ẹ̀mí tó dára máa gbilẹ̀ nínú ìjọ?’ Bí àpẹẹrẹ, nínú ọgbà tí wọ́n gbin àwọn òdòdó rírẹwà sí, àwọ̀ tó wà lára òdòdó kọ̀ọ̀kan ló para pọ̀ di àwọ̀ mèremère tó wà níbẹ̀. Ṣé bíi ti òdòdó kọ̀ọ̀kan yẹn làwa náà rí? Ṣé à ń ṣe ipa tiwa láti mú kí ìjọ lẹ́wà? Ohun tó yẹ ká máa sapá láti ṣe gan-an nìyẹn. Wàyí o, ẹ jẹ́ ká wo ohun tá a lè ṣe kí ẹ̀mí tí à ń fi hàn lè máa múnú Ọlọ́run dùn.
-