ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìrètí Ló Mú Wa Dúró, Ìfẹ́ Ló ń sún Wa Ṣiṣẹ́
    Ilé Ìṣọ́—1999 | July 15
    • Ìrètí Tí A Fi Wé Ìdákọ̀ró

      10, 11. Kí ni Pọ́ọ̀lù fi ìrètí wa wé, èé sì ti ṣe tí ìfiwéra yìí fi bá a mu wẹ́kú?

      10 Pọ́ọ̀lù là á mọ́lẹ̀ pé Jèhófà ṣèlérí láti mú ìbùkún wá nípasẹ̀ Ábúráhámù. Lẹ́yìn náà, àpọ́sítélì náà ṣàlàyé pé: “Ọlọ́run mú ìbúra kan wọ̀ ọ́, pé, nípasẹ̀ ohun àìlèyípadà méjì [ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ìbúra rẹ̀], nínú èyí tí kò ṣeé ṣe fún Ọlọ́run láti purọ́, kí àwa tí a ti sá sí ibi ìsádi lè ní ìṣírí tí ó lágbára láti gbá ìrètí tí a gbé ka iwájú wa mú. Ìrètí yìí ni àwa ní gẹ́gẹ́ bí ìdákọ̀ró fún ọkàn, ó dájú, ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in.” (Hébérù 6:17-19; Jẹ́nẹ́sísì 22:16-18) Ìrètí tí a gbé ka iwájú àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ni ìyè àìleèkú lókè ọ̀run. Lónìí, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ló ní ìrètí kíkọyọyọ ti ìyè àìnípẹ̀kun nínú párádísè kan lórí ilẹ̀ ayé. (Lúùkù 23:43) Láìsí irú ìrètí bẹ́ẹ̀, a kò lè ní ìgbàgbọ́.

      11 Ìdákọ̀ró jẹ́ ohun kan táa ṣe nítorí ààbò ọkọ̀, bí kò bá sí ìdákọ̀ró, ọkọ̀ òkun kò ṣeé so mọ́lẹ̀, òun ni kì í sì í jẹ́ kí ọkọ̀ sú lọ. Kò sí atukọ̀ kan tí yóò dábàá kíkúrò ní èbúté láìsí ìdákọ̀ró. Níwọ̀n bí ọkọ̀ ti ri Pọ́ọ̀lù lọ́pọ̀ ìgbà, ìrírí tí jẹ́ kó mọ̀ pé bí kò bá sí ìdákọ̀ró inú ewu ńlá làwọn atukọ̀ wà. (Ìṣe 27:29, 39, 40; 2 Kọ́ríńtì 11:25) Ní ọ̀rúndún kìíní, ọkọ̀ òkun kì í ní ẹ́ńjìnnì tó lè mú kí ọ̀gákọ̀ fọgbọ́n darí rẹ̀ bó ṣe wù ú. Yàtọ̀ sí àwọn ọkọ̀ ogun tí wọ́n ń fi àjẹ̀ wà, afẹ́fẹ́ gan-an ló ń darí ọkọ̀ òkun. Bó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkọ̀ rẹ̀ fẹ́ forí sọ àpáta, ohun kan ṣoṣo tí ọ̀gákọ̀ kan lè ṣe ni kí ó sọ ìdákọ̀ró rẹ̀ sínú òkun, kó sì wá ní sùúrú títí ìjì náà yóò fi rọlẹ̀, pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé pé ìdákọ̀ró náà kò ní yẹ̀ ní ibi tó fi sọlẹ̀ sí nísàlẹ̀ òkun. Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi fi ìrètí Kristẹni kan wé ‘ìdákọ̀ró fún ọkàn, tó dájú, tó sì fìdí múlẹ̀ gbọn-in.’ (Hébérù 6:19) Nígbà tí a bá dojú kọ àtakò táa lè fi wé ìjì líle tàbí tí a bá dojú kọ àdánwò mìíràn, ìrètí àgbàyanu wa dà bí ìdákọ̀ró tó jẹ́ ká dúró gbọn-in gẹ́gẹ́ bí alààyè ọkàn, kí ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wa má bàa sú lọ sí àgbègbè tí kò jìn, níbi tí ọkọ̀ ti lè fàyà gbálẹ̀, ìyẹn ni àárín àwọn oníyèméjì, tàbí ibi tí àwọn àpáta tó lè fọ́ ọkọ̀ yángá wà, ìyẹn ni àwùjọ àwọn apẹ̀yìndà.—Hébérù 2:1; Júúdà 8-13.

      12. Báwo la ṣe lè yẹra fún fífà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà?

      12 Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fún àwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni pé: “Ẹ kíyè sára, ẹ̀yin ará, kí ọkàn-àyà burúkú tí ó ṣaláìní ìgbàgbọ́ má bàa dìde nínú ẹnikẹ́ni nínú yín láé nípa lílọ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè.” (Hébérù 3:12) Nínú ọ̀rọ̀ Gíríìkì, “lílọ kúrò” ní ṣangiliti túmọ̀ sí “láti ta kété” ìyẹn ni láti di apẹ̀yìndà. Àmọ́, a lè yẹra fún irú ọkọ̀ rírì pátápátá bẹ́ẹ̀. Ìgbàgbọ́ àti ìrètí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti rọ̀ mọ́ Jèhófà, kódà nígbà tí a bá dojú kọ àdánwò táa lè fi wé ìjì tó le jù lọ. (Diutarónómì 4:4; 30:19, 20) Ìgbàgbọ́ wa kò ní dà bí ọkọ̀ òkun tí ẹ̀fúùfù, ìyẹn ni ẹ̀kọ́ àwọn apẹ̀yìndà, ń gbé síhìn-ín sọ́hùn-ún. (Éfésù 4:13, 14) Níwọ̀n bí a sì ti ní ìrètí gẹ́gẹ́ bí ìdákọ̀ró wa, yóò ṣeé ṣe fún wa láti la ìjì ayé yìí já gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà.

  • Ìrètí Ló Mú Wa Dúró, Ìfẹ́ Ló ń sún Wa Ṣiṣẹ́
    Ilé Ìṣọ́—1999 | July 15
    • Ẹ Jẹ́ Kí Á Forí Lé Ibi Tí A Ń Lọ!

      18. Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti fara da ìdánwò èyíkéyìí tó bá dé bá ìgbàgbọ́ wa lọ́jọ́ iwájú?

      18 A ṣì lè dán ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ wa wò dé góńgó kí a tó dé inú ètò tuntun àwọn nǹkan. Àmọ́, Jèhófà ti pèsè ìdákọ̀ró kan fún wa ‘tó dájú tó sì dúró gbọn-in’—ìyẹn ni àgbàyanu ìrètí wa. (Hébérù 6:19; Róòmù 15:4, 13) Nígbà tí a bá dojú kọ onírúurú àtakò tàbí àdánwò mìíràn, a lè fara dà á bó bá jẹ́ pé ìrètí táa ní ti mú wa dúró gbọn-in. Lẹ́yìn tí ìjì kan bá lọọlẹ̀, tí òmíràn kò sì tí ì dé, ẹ jẹ́ kí a pinnu láti mú kí ìrètí wa lágbára, kí a sí fún ìgbàgbọ́ wa lókun.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́