ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Inú Rere Ṣe Pàtàkì Lójú Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́—2012 | September 1
    • Yàtọ̀ sí pé inú rere jẹ́ ara ìwà tí Ọlọ́run dá mọ́ àwa èèyàn ká máa hù, ó tún ṣe pàtàkì gan-an lójú Ọlọ́run. Ìdí nìyẹn tó fi bọ́gbọ́n mu bí Ọlọ́run ṣe sọ fún wa pé kí a jẹ́ ‘onínúrere sí ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.’ (Éfésù 4:32) Bíbélì sì tún rán wa létí pé: “Ẹ má gbàgbé aájò àlejò,” tàbí ṣíṣe inúure sí àwọn tí a kò mọ̀ rí.—Hébérù 13:2.

  • Inú Rere Ṣe Pàtàkì Lójú Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́—2012 | September 1
    • Ṣàkíyèsí pé lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa ṣíṣe inú rere sí àwọn tí a kò mọ̀ rí, ó sọ pé: “Nípasẹ̀ rẹ̀, àwọn kan ṣe àwọn áńgẹ́lì lálejò, láìjẹ́ pé àwọn fúnra wọn mọ̀.” Ìwọ rò ó wò ná, báwo ló ṣe máa rí lára rẹ ká ní o láǹfààní láti ṣe àwọn áńgẹ́lì lálejò? Ṣùgbọ́n rántí pé gbólóhùn tí Pọ́ọ̀lù fi parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni, “láìjẹ́ pé àwọn fúnra wọn mọ̀.” Lọ́nà míì, ohun tó ń sọ ni pé tó bá ti mọ́ wa lára láti máa ṣe àwọn èèyàn lóore, títí kan àwọn àjèjì tàbí àwọn tí a kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀, a lè jàǹfààní rẹ̀ láwọn ọ̀nà tí a kò ronú kàn.

      Ọ̀pọ̀ Bíbélì tó ní atọ́ka níbi tí Pọ́ọ̀lù ti sọ ọ̀rọ̀ yìí, ló tọ́ka sí ìtàn Ábúráhámù àti ti Lọ́ọ̀tì tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì orí kejìdínlógún àti ìkọkàndínlógún. A rí i kà nínú ìtàn àwọn méjèèjì yìí pé àwọn áńgẹ́lì wá sí ọ̀dọ̀ wọn bíi pé wọ́n jẹ́ àjèjì tó wá jíṣẹ́ pàtàkì fún wọn. Ní ti Ábúráhámù, ohun tí àwọn áńgẹ́lì wá sọ fún un dá lórí bí ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé ó máa bí ọmọkùnrin kan ṣe máa ní ìmúṣẹ, àmọ́ ní ti Lọ́ọ̀tì, ohun táwọn áńgẹ́lì wá sọ fún un ni bí ó ṣe máa yè bọ́ nínú ìparun tó fẹ́ dé bá ìlú Sódómù àti Gòmórà.—Jẹ́nẹ́sísì 18:1-10; 19:1-3, 15-17.

      Tí o bá ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí nínú ìpínrọ̀ tó ṣáájú èyí wàá rí i pé, àwọn tí Ábúráhámù àti Lọ́ọ̀tì kò mọ̀ rí, tó kàn ń gba ọ̀dọ̀ wọn kọjá lọ ni wọ́n ṣe inúure sí. Òótọ́ ni pé, láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ó jẹ́ àṣà àti ojúṣe àwọn èèyàn láti máa ṣe àwọn tó bá ń rìnrìn àjò tàbí tí wọ́n ń kọjá lọ lálejò, yálà wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́, ìbátan tàbí àjèjì. Kódà, Òfin Mósè sọ pé kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ṣèrànlọ́wọ́ fún àwọn tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì tó bá ń gbé ní orílẹ̀-èdè wọn. (Diutarónómì 10:17-19) Ṣùgbọ́n, ẹ̀rí fi hàn pé Ábúráhámù àti Lọ́ọ̀tì tiẹ̀ ṣe kọjá àṣà tó pa dà wá di òfin nígbà tó yá yìí. Wọ́n sa gbogbo ipá wọn láti ṣe inúure sí àwọn tí wọn kò mọ̀ rí rárá, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ rí ìbùkún gbà.

      Inú rere Ábúráhámù jẹ́ kó rí ìbùkún gbà ní ti pé ó bí ọmọkùnrin kan, àwa náà sì tún jàǹfààní inú rere rẹ̀. Lọ́nà wo? Ábúráhámù àti Ísákì ọmọ rẹ̀ kó ipa pàtàkì nínú bí ète Jèhófà ṣe ní ìmúṣẹ. Wọ́n di òpómúléró nínú ìlà ìdílé àwọn tí Jésù tó jẹ́ Mèsáyà ti wá. Nítorí pé wọ́n jẹ́ olóòótọ́, ohun tí wọ́n ṣe tún jẹ́ àpẹẹrẹ bí ìfẹ́ àti inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí ṣe mú kí Ọlọ́run pèsè ìgbàlà fún aráyé.—Jẹ́nẹ́sísì 22:1-18; Mátíù 1:1, 2; Jòhánù 3:16.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́