ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Bá A Ṣe Lè Máa Láyọ̀ Tá A Bá Ń Fara Da Ìṣòro
    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021 | February
    • 2 Ọ̀pọ̀ ò gbà pé èèyàn lè láyọ̀ tó bá ń kojú inúnibíni. Àmọ́ ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé ká ṣe gan-an nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, Jémíìsì sọ pé dípò ká máa kọ́kàn sókè nítorí àwọn ìṣòro wa, ṣe ló yẹ ká máa láyọ̀. (Jém. 1:​2, 12) Bákan náà, Jésù sọ pé ká máa láyọ̀ tí wọ́n bá ń ṣenúnibíni sí wa. (Ka Mátíù 5:11.) Kí lá jẹ́ ká máa láyọ̀ bá a tiẹ̀ ń kojú àdánwò? Ọ̀pọ̀ nǹkan la lè kọ́ látinú lẹ́tà tí Jémíìsì kọ sáwọn Kristẹni ìgbàanì. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro táwọn Kristẹni yẹn kojú.

      ÌṢÒRO WO LÀWỌN KRISTẸNI ÌGBÀANÌ KOJÚ?

      3. Kí ló ṣẹlẹ̀ kété lẹ́yìn tí Jémíìsì di ọmọ ẹ̀yìn Jésù?

      3 Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Jémíìsì àbúrò Jésù di ọmọ ẹ̀yìn ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe inúnibíni sí àwọn Kristẹni ní Jerúsálẹ́mù. (Ìṣe 1:14; 5:​17, 18) Lẹ́yìn tí wọ́n pa Sítéfánù, ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni ló sá kúrò ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì “tú ká lọ sí gbogbo agbègbè Jùdíà àti Samáríà,” kódà àwọn kan sá lọ sí Sápírọ́sì àti Áńtíókù. (Ìṣe 7:58–8:1; 11:19) Ó dájú pé ọ̀pọ̀ ìṣòro làwọn ọmọlẹ́yìn yẹn kojú, síbẹ̀ wọ́n ń fìtara wàásù ní gbogbo ibi tí wọ́n lọ, wọ́n sì ń dá ìjọ sílẹ̀ láwọn ilẹ̀ tí Róòmù ń ṣàkóso. (1 Pét. 1:1) Àmọ́ kékeré làwọn ìṣòro yẹn lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ìṣòro tí wọ́n ṣì máa kojú.

      4. Àwọn ìṣòro míì wo làwọn Kristẹni yẹn kojú?

      4 Onírúurú ìṣòro làwọn Kristẹni yẹn kojú. Bí àpẹẹrẹ, ní nǹkan bíi 50 S.K., Olú Ọba Kíláúdíù pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn Júù fi ìlú Róòmù sílẹ̀. Torí náà, ó di dandan pé kí àwọn Júù tó ti di Kristẹni fi ilé wọn sílẹ̀, kí wọ́n sì kó lọ síbòmíì. (Ìṣe 18:​1-3) Nígbà tó di nǹkan bíi 61 S.K., àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé àwọn èèyàn pẹ̀gàn àwọn Kristẹni ní gbangba, wọ́n jù wọ́n sẹ́wọ̀n, wọ́n sì kó wọn lẹ́rù. (Héb. 10:​32-34) Yàtọ̀ síyẹn, bíi tàwọn èèyàn yòókù, àwọn Kristẹni náà fara da ipò òṣì àti àìsàn.​—Róòmù 15:26; Fílí. 2:​25-27.

  • Bá A Ṣe Lè Máa Láyọ̀ Tá A Bá Ń Fara Da Ìṣòro
    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021 | February
    • Fọ́tò: 1. Iná ń jó nínú láńtánì kan bó tiẹ̀ jẹ́ pé òjò ń rọ̀, atẹ́gùn sì ń fẹ́. 2. Arákùnrin àgbàlagbà kan ṣí Bíbélì sọ́wọ́.

      Bíi ti iná tó ń jó nínú láńtánì kan, bẹ́ẹ̀ ni ayọ̀ tí Kristẹni kan ní ṣe kún inú ọkàn ẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 6)

      6. Kí ni Lúùkù 6:​22, 23 sọ pé á jẹ́ kí Kristẹni kan máa láyọ̀ tó bá tiẹ̀ ń kojú ìṣòro?

      6 Àwọn kan ronú pé ó dìgbà tí ìlera àwọn bá jí pépé, táwọn lówó rẹpẹtẹ, tí ilé àwọn sì dùn káwọn tó lè láyọ̀. Àmọ́, ẹ̀mí mímọ́ ló ń mú kéèyàn ní irú ayọ̀ tí Jémíìsì ń sọ yìí, èèyàn sì lè láyọ̀ yìí láìka ìṣòro tó ní sí. (Gál. 5:22) Ohun tó mú káwọn Kristẹni máa láyọ̀ ni pé wọ́n ń múnú Jèhófà dùn, wọ́n sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. (Ka Lúùkù 6:​22, 23; Kól. 1:​10, 11) A lè fi ayọ̀ wé iná tó ń jó nínú láńtánì kan. Ẹyin láńtánì náà ni ò ní jẹ́ kí atẹ́gùn tàbí òjò pa iná tó wà nínú ẹ̀. Lọ́nà kan náà, àwa náà lè máa láyọ̀ bá a tiẹ̀ ń kojú ìṣòro nígbèésí ayé wa. Ayọ̀ wa ò ní pẹ̀dín tá a bá ń ṣàìsàn tàbí tá ò lówó lọ́wọ́. Kódà, kò ní dín kù táwọn èèyàn bá ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí tí ìdílé wa tàbí àwọn míì ń ta kò wá. Dípò káyọ̀ wa máa dín kù, ṣe lá máa pọ̀ sí i. Àwọn àtakò tá à ń kojú torí ohun tá a gbà gbọ́ jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé ọmọ ẹ̀yìn Kristi ni wá. (Mát. 10:22; 24:9; Jòh. 15:20) Ìdí nìyẹn tí Jémíìsì fi sọ pé: “Ẹ̀yin ará mi, tí oríṣiríṣi àdánwò bá dé bá yín, ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ayọ̀.”​—Jém. 1:2.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́