-
‘Ẹ Ronú Jinlẹ̀ Nípa Ẹni Tó Lo Ìfaradà’“Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn”
-
-
“Ẹ Tẹ̀ Lé Àwọn Ìṣísẹ̀ Rẹ̀ Pẹ́kípẹ́kí”
20, 21. Bó bá dọ̀rọ̀ ìfaradà, kí ni Jèhófà ń retí lọ́dọ̀ wa, kí ló sì yẹ kó jẹ́ ìpinnu wa?
20 Jésù mọ̀ pé ẹni tó bá fẹ́ máa tọ òun lẹ́yìn ò ní ṣàìní ìwọ̀n ìnira tó máa béèrè pé kéèyàn ní ìfaradà. (Jòhánù 15:20) Ó múra tán láti ṣíwájú, torí ó mọ̀ pé àpẹẹrẹ òun á fún àwọn ẹlòmíì lókun. (Jòhánù 16:33) Òótọ́ ni pé Jésù fi àpẹẹrẹ pípé lélẹ̀ lórí ọ̀ràn ìfaradà, ṣùgbọ́n àwa kì í ṣe ẹni pípe. Kí ni Jèhófà ń retí lọ́dọ̀ wa? Pétérù ṣàlàyé pé: “Kristi pàápàá jìyà fún yín, ó fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún yín kí ẹ lè tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.” (1 Pétérù 2:21) Nínú ọ̀nà tí Jésù gbà kojú àdánwò, ó fi “àwòkọ́ṣe” tá a ní láti máa tẹ̀ lé lélẹ̀.a Àpẹẹrẹ ìfaradà tó fi lélẹ̀ dà bí “ìṣísẹ̀” tàbí ipa ẹsẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò lè tọ àwọn ìṣísẹ̀ yẹn lọ́nà tó pé pérépéré, ṣùgbọ́n a lè tẹ̀ lé e “pẹ́kípẹ́kí.”
-
-
‘Ẹ Ronú Jinlẹ̀ Nípa Ẹni Tó Lo Ìfaradà’“Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn”
-
-
a Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “àwòkọ́ṣe” túmọ̀ sí “ṣíṣe àdàkọ.” Àpọ́sítélì Pétérù nìkan ni òǹkọ̀wé Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tó lo ọ̀rọ̀ yìí, èyí tí wọ́n sọ pé ó túmọ̀ sí “àwòrán tí ọmọdé kan ń wò yà sínú ìwé rẹ̀, àwòkọ tí ọmọdé kan ní láti wò kọ gẹ́lẹ́ bó bá ṣe lè ṣe é tó.”
-